You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Alex Iwobi: Iwobi fọwọ́ sí àdéhùn tuntun pẹ̀lú Arsenal
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1
Agbabọọlu Naijiria Alex Iwobi ti fi idunnu rẹ han lẹyin to bọwọ luwe adehun tuntun pẹlu ẹgbẹ agbọọlu ilẹ Gẹẹsi Arsenal.
Iwobi tọwọ bọ iwe adehun ti yoo pari ni ọdun 2023 pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu naa.
Iwobi to jẹ ọmọ ọdun mejilelogun ti gbayo mẹsan wọle fun Arsenal ninu ifẹsẹwọnsẹ 98 to ko pa ninu rẹ lati ọdun 2015 to ti bẹrẹ si ṣoju ikọ naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Lati ọmọ ọdun mẹsan ni Iwobi ti darapọ mọ Arsenal, o ṣoju ikọ naa fun igba akọkọ nigba ti o pe ọmọ ọdun mọkandinlogun.
Iwobi dupẹ lọwọ akọnimọọgba tuntun ikọ naa Unai Emery fun igbagbọ rẹ ninu oun, bẹẹni ko gbagbe awọn ololufẹ Arsenal fun atilẹyin wọn.