You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ahmed Musa: Musa dèrò Saudi Arabia láti Leicester City
Ẹlẹsẹ ayo ọmọ Naijiria Ahmed Musa ti darapọ mọ ikọ agbabọọlu Al-Nassr ni orilẹede Saudi Arabia.
Ẹgbẹ agbabọọlu Al-Nassr ra Musa lati ikọ agbabọọlu ilẹ Gẹẹsi Leicester City fun £17.5M.
Ẹ o ranti pe Leicester City ra Musa lati ẹgbẹ agbabọọlu CSKA Moscow lọdun 2016 fun £16m.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:
Ṣugbọn wọn da a pada si CSKA Moscow ni saa bọọlu to kọja lẹyin to gbayo meji pere sawọn ninu ifẹsẹwọnsẹ mọkanlelogun.
Musa ṣoju orilẹede Naijiria ninu ife ẹyẹ agbaye lorilẹede Russia nibi to ti gba ayo meji sawọn ninu ifẹsẹwọnsẹ Naijiria pẹlu Iceland.