You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Iwobi: agbábọ́ọ̀lù Nàìjírìa fakọyọ fún ikọ̀ Arsenal
Agbabọọlu ikọ Arsenal to jẹ ọmọbibi orilẹede Naijiria Alex Iwobi ti sọ pe oun ko le ṣalaye bi oun se gba pẹnariti to mu Arsenal fiya jẹ Chelsea ninu idije International Champions Cup sawọn.
Adilemu fun Chelsea lo kọkọ gba bọọlu wọle Arsenal nipele akọkọ, ṣugbọn Alexandre Lacazette dayo naa pada nigba to ku diẹ ki ifẹsẹwọnsẹ naa pari.
Lẹyin eleyin ni wọn bẹrẹ womi ki n gba si ọ nibi ẹgbẹ agbabọọlu mejeeji ti gba ayo marun un, marun un wọle ara ara wọn.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Aṣọle fun ikọ Arsenal Petr Cech mu pẹnata kẹfa ti Chelsea ti Ruben Loftus-Cheek gba.
Ṣugbọn Iwobi gba pẹnariti ẹlẹẹkẹfa Arsenal sawọn eleyi to mu ẹgbẹ agbabọọlu jawe olubori.
Ẹwẹ, akọnimọọgba Arsenal Unai Emery ti dunnu si bi awọn agbabọọlu ikọ naa ti fakọyọ ninu ifẹsẹwọnsẹ ọhun.