Unai Emery di akọnimọọgba Arsenal

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Unai Emery ni akọni moogba tuntun fun ẹgbẹ́ agbaboolu Arsenal.

Ẹgbẹ náà fi ìkéde iyansipo rẹ ati ìkínni káàbọ̀ sójú òpó Twitter wọn.

Emery n darapo mọ ẹgbẹ Arsenal láti PSG níbi tí ọ ti gbà ìfé ẹyẹ liigi pẹlú wọn.

Bákannáà ni o tí gbà ife ẹyẹ Europa league pẹlú Sevilla ni ẹẹmẹta otooto.

Emery ni inú oun dun lati dárapo mọ ẹgbẹ Arsenal.

O sọ pe oun sí ní ìrètí pé ''àwọn yóò jo ṣé gudugudu meje ati yaya mẹfa pọ''

Àwọn ololufe ẹgbẹ Arsenal ni orílè-èdè Nàìjíríà, si ti n fi iṣẹ ìkínni káàbọ̀ ranṣẹ sí akoni-moogba tuntun wọn