Bolt tọwọbọwe adehun pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu kan

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Gbajugbaja elere ori papa, Usain Bolt sọ pe oun ti tọwọbọwe adehun lati darapọmọ ẹgbẹ agbabọọlu kan.

Lori oju opo facebook rẹ lo ti kede ọrọ naa.

Ṣugbon o kọ lati darukọ ẹgbẹ agbabọọlu naa.

O ni ki ẹnikẹni to ba fẹ ẹ mọ orukọ ẹgbẹ agbabọọlu naa pade oun lọjọ iṣẹgun.

Awọn ololufẹ rẹ ti bẹrẹ si nii daba orukọ ẹgbẹ ti wọn lero wi pe o le jẹ

Laipe yi ni aworan Usain Bolt gba ori ẹrọ ayelujara nibi ti o ti'n ṣe igbaradi pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Mamelodi Sundowns ni orilẹẹde South Africa.

Ọdun 2017 ni Bolt fẹyin ti nibi ere ori papa.

Awọn iroyin ti ẹ le nifẹ si: