You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Usain Bolt: Bọọlu gbigba lo kan fun mi
Ikọ agbabọọlu Mamelodi sundowns nilẹ South Africa ti gba alejo nla bayii pẹlu bi etu obeje ẹlẹsẹ ere, to jẹ ọmọ ilẹ Jamaica nni, Usain Bolt, se ti gunlẹ si agbo ikọ naa fun igbaradi ere bọọlu lọjọ aje.
Gbajugba elere ori papa ọmọ ilẹ Jamaica naa, se igbaradi pẹlu awọn agbabọọlu Mamelodi to si tun la wọn lọyẹ lori awọn ọna abuja si ere sisa.
Onigbọwọ kan naa lo nse agbatẹru asaregbayi Bolt ati ikọ agbabọọlu Mamelodi Sundowns, to si jẹ wipe, laifọtape, awọn mejeeji yii lo ti tayọ ninu ohun ti wọn yan laayo.
Ami ẹyẹ goolu mẹjọ ni Usain bolt ti gba bọ wa sile lati idije ere idaraya Olympic, eyi to fẹẹ se kongẹ afojusun awọn ikọ Mamelodi, tawọn naa nlepa ami ẹyẹ liigi kẹjọ nilẹ South Africa.
"Odu ni ikọ agbabọọlu Mamelodi, inu mi si dun pupọ lati bawọn dowo pọ. Lootọ, mi o lee sọ bi mo ti se yara si pẹlu bọọlu sugbọn bo pẹ, bo ya, emi naa maa de oju iwọn lẹnu rẹ."
Usain Bolt ni, sise igbaradi pẹlu ikọ Mamelodi sundowns ti si oun loju lati rii pe ere ori igi nikan ni ẹdun oun lee saa, ati pe omi nbẹ laamu fun oun lori ọrọ ati gba bọọlu jẹun.
"Maa sa gbogbo ipa lati rii daju pe ara mi tete bọ sipo ki n lee dara pọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu Borrusia Dortmund ni osu kẹta ọdun.
Ninu ọrọ rẹ, agbabọọlu ikọ Mamelodi Sundowns kan, Percy Tau ni, iriri nlanla lo jẹ fun asaregbayi ọmọ ilẹ Jamaica naa lati darapọ mọ awọn.