Queen Naomi Silekunola Ogunwusi: Ẹ̀yin obìnrin, ẹ má ṣe fi ara da ìyà torí nǹkan tí àwọn èèyàn yóò sọ

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Olori Ooni Ile-Ife, Naomi Silekunola ti gba awọn obinrin ni imọran pe ki wọn o ma sa kuro ninu igbeyawo to ba kun fun iwa ipa.

O sọ eyi ninu ọrọ to kọ si oju opo ayélujára Instagram rẹ ni ọjọ Aje, lati fi kẹdun iku akọrin ẹmi, Osinachi Nwachukwu to di oloogbe ni opin ọsẹ to kọja.

Iroyin sọ pe ọkọ obinrin naa lo ṣe okunfa iku rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Olori Naomi kọ pe ominira wa fun obinrin, pẹlu akàwé lati inu iwe Luku ori kẹtala, ẹsẹ kejila.

O ni gẹgẹ bi obinrin, o ni ẹtọ lati sọ pe bẹẹ kọ, lai ṣẹṣẹ ma a reti pe iru ọkunrun bẹẹ yoo dẹkun iwa buruku to n hu si ọ.

Bakan naa lo sọ pe ko si nkan to buru fun obinrin lati sọ pe awọn ko ṣe mọ.

"O le beere fun iranlọwọ to o ba fẹ. Kọ nkan ti o ko fẹ, koda ti gbogbo aye ko ba faramọ igbesẹ rẹ.

"To o ba ku sinu igbeyawo, iyẹn ko sọ pe ki awọn eniyan gba ti ẹ ninu iboji."

"Ma duro di igba ti o ba kú ko to o kuro."

Ta ni Naomi Silekunola Ogunwusi?

Olori Naomi Silekunola Moronke Ogunwusi ni ayaba fun Ooni tilu Ile Ife, Ọba Adeyeye Enitan Ogunwusi, Ọjaja keji.

Olodumare si fi ọmọ kan soso saarin wọn, eyiun Ọmọọba Tadenikawo Ogunwusi lẹyin ọdun mẹta ti wọn se igbeyawo.

Amọ tẹ o ba gbagbe, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kejila, ọdun 2021, ni olori naa kede pe opin ti de ba igbeyawo oun pẹlu Ooni, Ọba Adeyeye Ogunwusi.

Ninu ọrọ to kọ soju opo Instagram rẹ nipa ituka igbeyawo naa, Naomi sọ pe oriṣiriṣi idojukọ ni oun ri ninu igbeyawo naa, ṣugbọn oun ma n fi ẹ̀rín bo ibanujẹ mọlẹ.

Nigba to tẹsiwaju ninu imọran rẹ fun awọn obinrin to ba n la igbeyawo to ni ipenija kọja, o sọ pe ki wọn o dẹkun lati ma a fi ara jiya nitori ibẹru nkan ti awọn eniyan yoo sọ.

O ni ko si ẹnikan ti ko ni aleebu, nitori naa lo ṣe ṣe pataki ki awọn obinrin dẹkun lati ma fi ara da nkan ti ko tọ ọ, nitori ohun ti aráyé yoo sọ.