You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Seyi Makinde: Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo fún àjọ aláàbò Amotekun ní ọgọ́rùn ọkọ̀ fún ètò ààbò
Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde, ti laago ikilọ si eti awọn ọdaran, lati rin jina si ipinlẹ naa, bibẹẹkọ, wọn o fi imu ko ata ofin.
Ọjọ Ẹti ni gomina fi ikilọ naa sita lasiko to fa ọgọrun ọkọ le ajọ alaabo Amotekun lọwọ, fun iṣẹ wọn.
Ṣaaju asiko yii ni oriṣiriṣi iroyin ti n jade lori bi awọn ọdaran ṣe n ṣoro ni awọn ibi kan nipinlẹ Oyo, paapaa ilu Ibadan.
Ọsẹ to kọja ni eeyan mẹrin ku ni adugbo Omi Adio, lasiko ti awọn adigunjale kan lọ ọ ja awọn oni PoS ni ole. Ti wọn si yinbọn mọ ara adugbo lasiko ti wọn n salọ lẹyin idigunjale wọn.
Gomina Makinde sọ nibi eto naa to waye nile ijọba nilu Ibadan pe yatọ si ẹgbẹrun kan aabọ oṣiṣẹ Amotekun to wa nilẹ tẹlẹ, o ni ijọba oun yoo tun gba ẹẹdẹgbẹta kun wọn, ki eto aabo tun le fidimulẹ daadaa.
Bakan naa lo kilọ fun awọn ọdaran ati awọn to le ni erongba lati ṣe iṣẹ ibi nipinlẹ Oyo pe, ko si ibi ti wọn le fi ara pamọ si, ti ọwọ ko ni tẹ wọn.
O ni aṣemọ ni yoo jẹ fun ẹnikẹni to ba tun hu iwa ọdaran nipinlẹ Oyo lati asiko yii lọ.
Makinde ni ijọba ra awọn ọkọ naa pẹlu ajọṣepọ awọn ijọba ibilẹ to wa nipinlẹ Oyo.
O tun ke si awọn araalu, lati ma jẹ ki eti awọn oṣiṣẹ ajọ Amotekun di si awọn ihuwasi awọn ọdaran ti wọn ba n ri.