2022 ASUU Strike: Ìpàdé ìjọba àti ẹgbẹ́ olùkọ́ fásitì forí ṣánpọ́n, ọ̀sẹ̀ mẹ́jọ míì gun ìyanṣẹ́lódì

Ẹgbẹ awọn olukọ ni fasiti Naijiria, ASUU, ti kede pe oun ti fi ọsẹ mẹjọ kun iyanṣẹlodi to n lọ lọwọ, nitori pe awọn ko ti i fẹnuko lori ọna abayọ pẹlu ijọba.

Nibi ipade kan ti wọn ṣe nilu Abuja lọjọ Aiku ni ikede naa ti waye.

ASUU bẹrẹ iyanṣẹlodi lọjọ kẹrinla, oṣu Keji, lati fi kilọ fun ijọba.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ẹsun ti wọn fi kan iṣejọba Aarẹ Muhammadu Buhari ni pe o kuna lati sọ adehun kan ti wọn fẹnuko pẹlu ijọba lori ẹka eto ẹkọ fasiti ni Naijiria.

Wọn ni awọn n fẹ ki ijọba sọ igbe aye idẹrun fun awọn olukọ ati idagbasoke awọn fasiti, gẹgẹ bi wọn adehun ti wọn jọ fi ọwọ si lọdun 2009, di ootọ.

Ọkan pataki ninu ẹgbẹ ASUU, Ọjọgbọn Muhammad Danbazau sọ fun BBC Hausa pe awọn fikun iyanṣẹlodi ọhun, lati le mu ki awọn ati ijọba fẹnuko lori igbesẹ kan, eyi ti ko ni le jẹ ki ASUU tun lọ fun iyanṣẹlodi lọjọ iwaju.

O ni ọsẹ mẹjọ ti to lati mu ki ijọba gbe igbesẹ to yẹ.

Ẹẹmeji si ni igun mejeeji ti sẹ ipade lati igba ti iyanṣẹlodi yii ti bẹrẹ.

Kii ṣe igba akọkọ niyii ti awọn olukọ fasiti yan iṣẹ lodi nitori "pe ijọba ko nawo si eto ẹkọ fasiti daadaa".

Awọn iwadii kan ti ẹ sọ pe igba mẹẹdogun ni ASUU ti yanṣẹlodi lati ọdun 1999 ti ijọba alagbada ti pada si Naijiria, eyi to fi eto ẹkọ sinu ewu.

Ipa kekere kọ ni iyanṣẹlodi ẹgbẹ ASUU n ni lara awọn akẹkọọ nitori bi awọn iyanṣẹlodi ASUU ṣe ma n wa fun ọpọlọpọ oṣu.

Ọpọ eeyan lo si ma n rọ wọn pe ki wọn o wa ọna miran to yatọ si iyanṣẹlodi lati ma a yanju ede aiyede wọn pẹlu ijọba.