Kemi Afolabi Battles Lupus: Wo àwọn gbajúmọ̀ òṣèré tíátà tó ní yóò fọ́ eegun ẹran láyé di ọgọ́rùn-ún ọdún

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Yorùbá bọ̀ wọ́n ní kò ní burú burú, kó má ku ẹnìkan mọ́ ni, ẹni tí yóó kù la ò mọ̀.

Àwọn ọ̀rẹ́ àti ará, tó fi mọ́ àwọn tí kìí bá Kemi Afolabi sọ̀rọ̀ tẹlẹ lágbolé tíátà ló ti ń kẹ́dùn, tí wọn sì ń ki òṣèrébìnrin náà láyà.

Bákan náà ni wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ àtìlẹyin fún un lẹ́yìn tó kéde pé ọdún márùn-ún ni dókítà ní ó kù fún òun láti lò láyé, tí òun sì ti lo ọdún kan níbẹ̀.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bẹẹ ba gbagbe, lọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ kọkànlá, oṣù kẹta, ọdún 2022 ni fọ́nrán ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí Kemi Afolabi ṣe pẹ̀lú gbajúmọ̀ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ kan, Chude Jideonwo gba orí ayélujára.

Ninu ifọrọwerọ naa si lo ti ṣíṣọ lójú eégún pé àìsàn Lupus, to maa n ro ẹda de inu egungun, ló ń bá òun fínra, ti oun si ni ọdun diẹ lati lo si laye.

Pẹ̀lú omijé lójú ni Kemi Afolabi fi kẹnu bọ ìròyìn lórí ohun tí ó ń là kọjá láti ìgbà tó ti gbọ́ ọjọ́ ikú rẹ̀ lẹ́nu àwọn dókìtà.

Kemi Afolabi ní àìsàn tó ń bá òun jà kògbóògùn, òògùn lásán sì ni òun yóò máa lò títí ni gbogbo ọjọ́ tí òun yóò lò lókè eèpẹ̀.

Àwọn òṣèré tíátà tó ń ki Kemi Afolabi láyà:

Lola Magaret ní Kemi Afolabi yoo fọ eegun ẹran laye di ọdun 2092:

Láti ìgbà tí Kemi Afolabi ti fi ìkéde àìsàn tó ń bá fínra léde, àwọn òṣèré tíátà lọ́kan ò jọ̀kan ló ti ń sọ̀rọ̀ àtìlẹyìn àti ọ̀rọ̀ ìwúrí fún un lórí àìsàn tó ń bá a jà.

Nínú fọ́nrán kan tí òṣèré náà fi sí orí Instagram rẹ̀ tó ti ń ṣe àdúrà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ fáwọn akẹgbẹ́ rẹ́, ti wọn bẹ̀rẹ̀ sí ní rọ òjò àdúrà àti ọ̀rọ́ ìwúrí fún un.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Lola Magret ní àwọn dókítà kàn wí ti wọn ni, àti pé Ọlọ́run ló ń ṣe ìwòsàn. Ó ni èsì tí àwọn dókítà fun kò ní jẹ́ tirẹ̀.

Lola Magaret ní títí di ọdún 2092, Kemi Afolabi yóò ṣì máa fọ egungun adìyẹ nínú àláfíà àti ara pípé ni.

Muyiwa Ademola n ki Kemi Afolabi ki ayẹyẹ ọgọrun ọdun:

Muyiwa Ademola ntiẹ wa n kí Kemi Afolabi kú ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọgọ́run ọdún lókè eèpẹ̀.

O ní èyí tó túmọ̀ sí pé òun ń sọ fún pé kò ní kú ìkú kankan, àti pé ọgọ́ta ọdún síi lónìí, gbọingbọin ni tòkè fún Kemi Afolabi.

Bimbo Afolayan ni Kemi Afolabi yoo dagba, yoo dogbo:

Bimbo Afolayan kọ sí ojú òpó ayélujára rẹ̀ pé, òun kò ní fojú sunkún Kemi Afolabi, pé yóò dàgbà dògbó lọ́lá Ọlọ́run.

Yewande Adekoya ni oun nifẹ rẹ pupọ, ti oun si n gbadura fun nitori pe Ọlọrun n ti lẹyin.

Opeyemi Aiyeola ni oun ni igbagbọ pupọ ninu Ọlọrun ati eto rẹ fun ẹda, ti oun si mọ pe o n ti Kemi Afolabi lẹyin.

Lati ile iwosan kan si omiran la n gbe Kemi Afolabi kiri - Yomi Fabiyi

Yomi Fabiyi, nígbà tó ń kọ ọ̀rọ̀ tirẹ̀ ránti alẹ́ ọjọ́ tí àwọn ń wá ilé ìwòsàn kiri nígbà tí àìsàn burúkú yìí bẹ̀rẹ̀ sí ní bá Kemi Afolabi fínra.

O ṣàlàyé pé láti ilé ìwòsàn kan sí òmíràn ni àwọn ń lọ káàkiri ṣùgbọ́n òun ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run pé kò ní já àwọn kulẹ̀.

Ti Debbie Shokoya si n kin Yomi Fabiyi lẹyin pe ki Kemi Afolabi mase ni igbagbọ ninu ohun ti awọn dokita ba sọ.

O ni niwọn igba ti esi ayẹwo Ọlọrun ko ba ti fontẹ lu ayẹwo dokita, ọrọ buse, ti ajaga esu si ti bọ.

Debbie wa gbadura fun Kemi Afolabi pe ẹmi gigun ati alaafia pipe ni ipin rẹ, ti aisan si ti jinna si.

Aisan Kemi Afolabi ba mi lọkan jẹ gidi:

Iyabo Ojo ni tirẹ̀ tọrọ àforíjì lọ́wọ́ Kemi Afolabi fún pé òun kò kàn sí i fún ìgbà pípẹ́, ó ní ìròyìn náà ba òun lọ́kàn jẹ́ tó sì tún da omi tútù sí òun lọ́kàn.

Bẹ́ẹ̀ náà ló rọ àwọn ènìyàn láti ṣàdúrà fún Kemi Afolabi, tó sì rọ̀ láti ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run wí pé kò sí ohuntí kò lè ṣe.

Bákan náà ni gbajúgbajà òṣèré tíátà lédè Gẹ̀ẹ́sì, Ngozi Nwozu gbàdúrà pé Ọlọ́run tó wo òun sàn lọ́wọ́ àìsàn kídìnrín ṣì wà lórí ìtẹ́, tí yóò sì wo Kemi náà sàn.

Wo awọn gbajumọ osere tiata to ti fun Kemi Afolabi ni ẹbun?

Kemi Afolabi ti kọ́kọ́ kéde ní ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n, oṣù kejìlá, ọdún 2021 pé àìsàn kògbóògùn kan ń bá òun fínra ṣùgbọ́n kò fi orúkọ àìsàn náà síta.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yìí, lẹ́yìn tí Kemi Afolabi ti kọ́kọ́ fi fọ́nrán kan síta péc, àìsàn kògbóògùn kan ń bá òun fínra.

Eyi lo mu ki àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lágbolé tíátà ti kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí ní fi ẹ̀bùn ráńṣẹ́ sí i.

Lára àwọn tí Kemi Afolabi fi àwòrán wọn sórí Instagram rẹ̀ nígbà náà ni Toyin Abrahan àti ọkọ rẹ̀, Kolawole Ajeyemi.

O si dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn fún àwọn ẹbun tí wọ́n fi ráńṣẹ́ sí òun.

Bákan náà ló tún dúpẹ́ lọ́wọ́ Funke Akindele fún gbogbo ohun tó kó ráńṣẹ́ sí òun nígbà náà.

Kemi Afolabi ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìfaǹfà wà láàárín àwọn, Funke Akindele kò kùnà láti fi ìfẹ́ hàn sí òun.

O salaye pe òun náà kò fi ìgbà kankan ma ní ìfẹ́ Funke Akindele mọ̀, bó ṣe jẹ́ pé láti ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì ni àwọn ti ń bá ara àwọn bọ̀.

Yàtọ̀ sí àwọn wọ̀nyìí, Kemi Afolabi kò ṣàì tún dúpẹ́ lọ́wọ́ Tunde Owokoniran àti ìyàwó rẹ̀, Yomi Fabiyi àti àwọn mìíràn fún ipa tí wọ́n kó nínú ọ̀rọ̀ òun.

Àwọn olólùfẹ́Kemi Afolabi lori ayelujara fi ìfẹ́ hàn si:

Yàtọ́ sí àwọn akẹgbẹ́ Kemi Afolabi, àwọn olólùfẹ́ gbajúgbajà òṣèré náà lórí Ìnstagram ti kọ onírúurú ọ̀rọ̀ ìwúrí fún un láti dùn ún nínú lórí ipò tó wà.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló ní àwọn yóò fi òṣèré náà sínú àdúrà àti pé, kò yẹ kí ẹnikẹ́ni máa la irú ìṣòro bẹ́ẹ̀ kọjá nítorí kò sí ẹni tí yóò gbọ́ ọjọ́ ikú rẹ̀ tí inú rẹ̀ yóó dùn.

Àwọn mìíràn tilẹ̀ sọ pé dókítà kò lè sọ pé iye ọjọ́ báyìí ni ènìyàn le lò láyé nítorí wọn kìí ṣe Ọlọ́run.