You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọ̀kan lára àwọn alátẹ̀lé Sunday Igboho tó bọ́ ní ahámọ́ DSS sọ bí ìkọlú sílé Igboho ṣe wáyé
Ọkan lara awọn alatẹ́le Sunday Igboho ti ikọ DSS ko nile rẹ lasiko ti wọn kọlu ile naa ni ọjọ Kinni osu Keje ọdun 2021, ti sọrọ soke nipa isẹlẹ naa.
Onaolapo Ademola, tii se ọkan lara awọn eeyan mejila ti wọn ko nile Igboho, to sẹsẹ gba idande, lasiko to ba akọroyin Punch sọrọ, salaye ohun ti oju rẹ ri.
Ademola, tii se ẹni ọdun mejilelọgbọn ni oun maa n ta ẹrọ amunawa Solar inverter, ti oun si tun maa n se katakara ilẹ ati ile.
Ninu ifọrọwerọ naa, o ni o ti to ọdun meji si mẹta ti oun ti n tẹle Sunday Igboho, awọn si dijọ bẹrẹ ijijagbara Yoruba Nation ni.
O salaye pe ọjọ manigbagbe ni ọjọ tawọn DSS wa sile Igboho nitori o dabi pe awọn wa loju ogun ni.
Ohun to gbe mi dele Sunday Igboho ree:
Ajijagbara naa ni ile toun n gbe ko jinna sile Sunday Igboho, to si jẹ baba si oun amọ aago mejila oru ni oun lọ sile rẹ lọjọ naa lati lọ jisẹ kan fun.
O ni awọn dijọ sọrọ titi di aago kan aabọ oru ti onikaluku fi lọ sun, ti Igboho naa si wọ iyara rẹ lọ.
O ni isẹju marun lẹyin igba naa ni awọn osisẹ DSS de, tawọn si n gbọ iro ibọn to n dun lakọ lakọ lai ri eeyan kankan.
"Gẹgẹ bii musulumi, se ni mo n ka ẹsẹ alukurani nitori mo ri pe isẹlẹ naa le gba ẹmi mi, mo si yọju loju ferese, ni mo ba ri awọn osisẹ DSS naa.
Awọn kan fo ogiri wọle lati wa si ẹnu ọna fun awọn yoku, ti mo si lọ ji awọn eeyan yoku pe iku ti de nitori ko si ọna ta le gba bọ."
Ademola ni wakati mẹta ni wọn fi n yin ibọn naa, wọn wa si iyara ti oun sun, ti oun si silẹkun fun wọn, ti wọn si gba ẹgbẹrun lọna ọọdunrun naira ti Igboho fun oun lati lọ ba oun ra nnkan kan.
Ọkan ninu wọn mu owo naa, ti wọn si so mi lọwọ pẹlu ankọfu, wọn ti mi lọ si ita lati lọ dara pọ mọ awọn eeyan youku ti wọn ko nile Igboho.
Iyalẹnu nla lo jẹ nigba ti mo ri oku Adogan to n ta mọto ni Osogbo nilẹ pẹlu Alfa, ti wọn wa ninu agbara ẹjẹ, a si dijọ sọrọ titi wọ aago mejila abọ idaji ọjọ naa ni.
Lẹyin naa ni awọn DSS yii bẹrẹ si ba awọn mọto to wa ninu ọgba ile naa jẹ, ti wọn si tun fẹ sun ile ọhun."
Ademola tẹsiwaju pe ko si ẹni to doju ija kọ awọn osisẹ DSS naa gẹgẹ bi wọn se sọ.
Bi wọn se pa Adogan ati Alfa ree:
O ni Adogan ni wọn pa ninu baluwẹ to sa si nigba ti wọn ba Alfa to n kirun lọwọ, Afọju ti ko riran ni, ti wọn si yinbọn mọ.
"Wọn ko awa pẹlu oku awọn mejeeji de ẹka ileesẹ DSS to wa ni Ekiti, ki wọn to fi mọto kan gbe oku awọn mejeeji lọ.
Awa mejilelogun ni wọn ko nile Igboho, ọkunrin mejila ati obinrin mẹwa.
Amọ nigba ti a de Ekiti, wọn da obinrin mẹsan silẹ, ti wọn si n beere pe ta lo n jẹ Lady K ninu wọn.
Lady K ati awọn ọkunrin yoku ni wọn ko lọ to fi mọ ọlọpaa kan to n sọ Adogan amọ wọn ko fi oju rẹ han ni Abuja, oun si ni wọn kọkọ fi silẹ."
Awọn ohun ti wọn ko nile igboho ree:
Ademola ni awọn osisẹ DSS ko goolu, ọpọ owo, ẹrọ ibaraẹnisọrọ, pẹlu ẹrọ ayaworan CCTV pẹlu ologbo kan.
Bakan naa lo ni wọn pa ologbo mẹrin, ti wọn si tun ko MP3 ati ọpọ nnkan miran, ti wọn si gbe Ologbo ti wọn ro pe Sunday Igboho lo di Ologbo naa.
Babalawo mẹta ni DSS mu wa sile Sunday Igboho
Ademola ni Sunday Igboho wa nile lọjọ ti isẹlẹ naa waye, awọn DSS gan foju ganni rẹ babalawo mẹta si ni wọn ko wa pẹlu.
"Lẹyin ti wọn yin ọpọ ibọn si igun ile naa, ni wọn ko sadede ri Sunday Igboho mọ amọ wọn ro pe o lọ sa pamọ ni.
Amọ Igboho kii se eeyan lasan, oun gan ni Akọni Oodua, igba yii ni awọn babalawo wọn n pe ọfọ ki Igboho le yọju pada.
Lẹyin eyi ni Awọn babalawo naa ni Igboho lo di Ologbo naa, idi si niyi ti wọn se n pa awọn ologbo yii.
Asọ ibilẹ lasan ni awọn babalawo yii wọ, amọ awọn DSS ko wọn wọnu ile nigba ti wọn ko ri Igboho, ti wọn si n pe ọfọ.
Osisẹ ogun ati igba sọja lo wa sile Sunday Igboho:
Ademola tẹsiwaju pe awọn osisẹ DSS ogun lo wa sile Igboho, tawọn sọja aarin wn si le ni igba.
O ni ọpọ awọn DSS yii lo wa lati ipinlẹ Oyo, ti oun si ka ọkọ to le ni mẹtadinlaadọsan 87, nigba ti wọn n ko awọn lọ.
O fikun pe wọn tun wa pẹlu ọkọ itọju alaisan pajawiri Ambulance pẹlu nitori wọn mura bi ẹni to n lọ soju ogun ni.
Inu aja ilẹ lọọfisi DSS ni wọn kọkọ fi wa pamọ si:
Ademola salaye pe inu aja ilẹ to wa ni ọọfisi awọn DSS ni Abuja ni awọn kọkọ wa fun ọjọ meji, ti awọn ko si mọ ohunkohun to n sẹlẹ rara.
Lẹyin naa lo ni wọn tun ko awọn lọ si inu ahamọ miran nibi ti awọn ti pade awọn ẹya Hausa ati Fulani, ti ọpọ wọn jẹ afurasi ọmọ ẹẹgbẹ Boko Haram ati IPOB.
Se ni wọn pin awa atẹle Igboho ti wọn ko si oniruuru ahamọ ọtọọtọ amọ o ni oun ko kabamọ pe oun jẹ alatilẹyin Igboho.