Nkechi Blessing: Gbogbo ẹ̀yin tó n dúró de àwòrán kí ẹ tó gbàgbọ́ pé mo ti ṣe ìgbéyàwó, ẹ má dúró pẹ́

Yoruba sọ pe ẹni ti a n gbe iyawo bọ wa a ba, kii garun wo o.

Ṣugbọn ọrọ ko ri bẹẹ fun awọn ololufẹ ere Yoruba , paapaa to jẹ ololufẹ ati alatilẹyin gbajugbaja oṣerebinrin, Nkechi Blessing Sunday, to ti n reti lati gbọ iroyin nipa igbeyawo rẹ.

Ko fẹ ẹ wọpọ ninu awọn ololufẹ rẹ to mọ pe o ti ṣe igbeyawo.

Nkan to han sita ni pe o ti bi ọmọ ọkunrin kan, ti ọjọ ori rẹ wa ni abẹ ọdun marun-un.

Bakan naa, laipẹ yii ni Nkechi bẹrẹ si ni fi aworan gbajugbaja oloṣelu kan, Opeyemi Falegan han sita.

Bo tilẹ jẹ pe ọpọ lo ro pe awọn mejeeji kan n yan ara wọn ni ọrẹ nia ko le sọ boya oun ni ọkọ rẹ.

Akiyesi si fihan pe oruka igbeyawo ma n wa lọwọ rẹ ninu awọ̀n aworan to n fi sita.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọ ṣa, ninu ọrọ naa to kọ si oju opo Instagram rẹ lo tun ti sọ pe oun n gbe ọkọ oun pamọ lati ọjọ yii nitori ki oun le dabo bo igbayawo oun ni.

O jẹ nkan to wọpọ fun awọn gbajumọ, paapaa awọn osẹre ni Naijiria, lati ma a fi aworan awọn ati ololufẹ wọn si ori ayelujara.

Ṣugbọn, Nkechi Blessing sọ pe ki oju awọn abanijẹ lori ayelujara ma ba a ri ọkọ oun ni.

Nigba to n sọrọ, pẹlu aworan kan to fi si oju opo Instagram rẹ, eyi to n sọrọ nipa ipinya laarin ọkọ ati iyawo, Nkechi sọ pe "gbogbo yin n duro de pe ki n fi aworan igbeyawo mi sita kẹ ẹ to gbagbọ pe mo ti ṣe igbeyawo. Ẹrin yin pa mi.

"Igbeyawo ni emi NBS n fẹ, kii ṣe ayẹyẹ igbeyawo. Mi o si ṣetan lati sọ igbeyawo mi di nkan idaraya fun yin."

O ni botilẹ jẹ pe aworan rẹ ti gba ọna ẹburu wọ ori ayelujara, iyẹn ko ni ki oun ma a sọrọ nipa igbeyawo oun nibẹ.