You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Eniola Badmus kilọ fun awọn to n bu pe o ti sanra ju lati dẹyin lẹyin oun.
O ṣeeṣe ki ẹ ti ẹ ti maa gbọ bi awọn eeyan kan maa ṣe maa n sọ pe, ara sisan kii ṣe arun.Lo difa fun gbajugbaja oṣere tiata Yoruba, Eniola Badmus to ke gbajare si awọn eeyan to maa n bu ẹnu atẹ lu lori ayelujara pe o ti sanra ju.Eniola sọ pe "Eẹyin eeyan ẹ ma ran mi lọ si iboji ọsan gangan, ni ṣe ni sanran o, mi o ji yin lẹran jẹ."
- Kí làwọn nǹkan tó lè rán ọkùnrin sí ọ̀run alákeji lásìkò ìbálòpọ̀ pẹ̀lú obìnrin?
- Nkechi Blessing vs Toyin Abraham: Nkechi tí tọrọ ìdáríjí ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́ akẹgbẹ́ rẹ̀, Toyin Abraham
- Ó ti tó àsìkò kí Nollywood fòpin sí èré ilé babaláwo lílọ - Clarion Chukwura
- Àrẹ̀mọ Ooni Adeyeye Ogunwusi ti wọ Ààfin Ile Ife fún ìgbà àkọ́kọ́
- Ara mi rẹwà ló jẹ́ kí n máa ṣí ara sílẹ̀- Victoria KolawoleỌrọ ti Eniola sọ ree loju opo Instagram lati kilọ fun awọn eeyan to maa n bu pe o ti tobi ju.
O ni ara oun ti wọn fi n bu oun naa ni oun pa owo wọle fun oun.Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni "ara ti ẹ n bu yii na lo n mu oujẹ wọle fun mi, bakan naa ara ti ẹ n bu yii naa lo maa n fun yin ni ayọ ati idunu ti ẹ ba n wo mi lori ẹrọ tẹlifiṣọn yin nile."Eniola tun rọ awọn ololufẹ, ẹbi ati ọrẹ to maa n sọ pe o ti tobi ju lati bu omi suru mu.
O ni "ẹyin ti ẹ n fun mi lọrun lori ọrọ ara sisan yii, ẹ jọwọ ẹ fi mi lọrun silẹ ki n ṣaye mi bo ṣe wu mi."Eniola tun ṣalaye nipa bi awọ eeyan ṣe maa n bu lojojumọ nitori o jẹ ẹni to sanra, o si sọ pe eyii ko dun mọ oun ninu.Oṣere naa pari ọrọ rẹ pe bi awọn eeyan ṣe maa n bu ẹni to ba sanra lo n mu ki ọpọ ninu wọn ronu pa ara rẹ.