You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Taiwo Asaniyi ló n gbọ́ bùkáàtà wa láti 2019 tí mo ti fẹ̀hìntì - Baba awakọ̀ ofufufú tó já ní Kaduna
Baba awakọ ofurufu to wa baalu ileeṣẹ ologun to ja ni Kaduna lọsẹ to kọja, Asaniyi Taiwo, ti sọ pe Ọlọrun nikan lo le tu oun ati ẹbi oun ninu lori iku ọmọ oun.
Taiwo Asaniyi jẹ ọkan lara awọn ọmọ ogun to ku ninu baalu naa.
Nigba to n ba ileeṣẹ akoroyinjọ News Agency of Nigeria sọrọ nile rẹ to wa nilu Ibadan, Ọgbẹnu Rufus, ẹni ọdun mejilelọgọta sọ pe oun jiya pupọ nitori ki awọn ọmọ oun le gbe igbeaye idẹrun.
"Ọdun mejilelọgbọn ni mo fi ṣe iṣẹ oko mọ iṣẹ olukọ, nitori ki awọn mi le ni eto ẹkọ to dara ju."
O ni Taiwo to ku yii naa lo n gbọ bukaata ẹbi oun lati ọdun 2019 ti oun ti fẹhinti lẹnu iṣẹ.
"Oun lo n gbọ gbogbo bukaata ẹbi, nitori pe oun ni akọbi l'ọkunrin.
"Ibukun lo jẹ fun wa ati awọn ẹbi wa. Gbogbo ero mi ni pe ide inira ti já ninu ẹbi wa ni, ṣugbọn Ọlọrun mu u lọ."
Àbọ̀ wá bá ni ọ̀rọ̀ Iyabo Ojo àti Yomi Fabiyi lórí ọ̀rọ̀ bàbá Ijẹsha - Damola Olatunji, ẹgbẹ́ TAMPAN
Bakan naa ni ẹni to jẹ akọbi idile naa, Arabinrin Oluwatoyin Olaoye sọ pe igbeaye rere ti aburo oun gbe lo jẹ itunu fun ẹbi.
Koda, o ni Taiwo pe oun ni ọjọ kan ṣaaju ijamba naa pe ki oun fi iwe ẹru ìdána ti awọn ẹbi iyawo oun fẹ gba ranṣẹ.
Iroyin sọ pe oṣu diẹ si asiko yii lo yẹ ki oloogbe naa ṣe igbeyawo.
"O sọ fun mi pe ileeṣẹ ologun ni ki oun lọ fun eto ẹkọ kan ni United Kingdom, eyi ti yoo bẹrẹ ni ọjọ kejila, oṣu Kẹfa.
Awọn obi oloogbe Taiwo rawọ ẹbẹ si ijọba apapọ, pe ko fun awọn ẹgbọn ati aburo Taiwo ni isẹ, ki ironu iku rẹ o ma ba a mu ẹmi wọn lọ.