You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Lizzy Anjorin and Toyin Abraham: Ṣé lóòtọ́ ni ìjà ti parí láàrin Toyin Abraham àti Lizzy Anjorin?
Lẹyin o rẹyin, Lizzy Anjorin Lawal ti sọ awọn ẹsẹ ti Toyin Abraham Ajeyemi ṣẹ ẹ ti ija wọn fi bẹrẹ.
Lasiko to n sọrọ ni ọjọ Iṣẹgun, ninu ipade ori ayelujara kan ti gbajugbaja agbohunsafẹfẹ, Esther Aboderin Esabod ṣe pẹlu awọn mejeeji lati ba wọn pari ija, Anjorin sọ pe o ti to ọdun mejila ti ẹṣẹ Toyin ti bẹrẹ.
Ọdun 2019 ni ija to n waye laarin arẹwa oṣerebinrin mejeeji yii bẹrẹ nigba ti Toyin bi ọmọ rẹ akọbi, Ire.
Lizzy sọ nigba naa pe ile alagbo ni Toyin bi ọmọ rẹ si, ati awọn ọrọ mii to tun sọ.
Kilo sọ ọrọ naa si, ni awọn ololufẹ awọn mejeeji bẹrẹ si ni gba ọrọ naa bi ẹni gba igba ọti, eyi to tun mu ki ina ija naa ko burẹkẹ sii.
Lẹyin asiko diẹ, ọpọ eeyan lo lero pe ija naa ti pari, nitori pe awọn ololufẹ wọn ko gbọ nkankan nipa rẹ mọ.
Ṣugbọn laipẹ yii ti Lizzy Anjọrin bi ọmọ rẹ tuntun, Florida, ni eefin ija naa tun bẹrẹ si ni ru soke, paapaa nigba ti obinrin kan jade sita lori ayelujara pe ọkọ oun ni Lizzy fẹ.
Bi awọn ololufẹ wọn tun ṣe bẹrẹ ija re o.
Ẹsun ti Lizzy kọkọ fi kan Toyin ni pe oun lo n fun awọn akọroyin ori ayelujara ni owo lati maa ba orukọ oun jẹ, ati lati maa gbe ayederu iroyin nipa oun ati igbeyawo oun.
Nitori eyi si ni Esabod ṣe bọ si ori ayelujara pẹlu Lizzy, ti wọn si bẹrẹ si nii sọ oriṣiriṣi ọrọ nipa Toyin ni ọjọ Iṣẹgun.
Kinni Toyin gbọ eyi si, ni oun naa fun Esabod ni esi pe oun fun ni ọjọ mẹta pere, ti nkan buruku yoo fi sẹlẹ si.
Ni ọrọ ija ba tun di iṣu ata yan-an-yan.
'Ẹẹmeji pere ni mo fi oju kan Lizzy ri laye mi'
Nkan kan to wọpọ ninu ọrọ ti awọn mejeeji sọ ninu ipade naa ni pe awọn kii ṣe ọrẹ.
Ko si ju ẹẹmeji si ẹẹmẹta ti wọn rira ni ojukoroju lọ.
Amọ nigbẹyin, Toyin pada fi oun tutu ba Esabod sọrọ lẹyin ti oṣerebinrin mii, Iyabọ Ojo da si ọrọ naa.
Bayii ni Esabod ṣe pe Toyin ati Lizzy si ipade oni fidio lori ayelujara Instagram, nibi to ti n beere lọwọ ẹni kọọkan wọn nkan to fa ija.
Ohun ti Toyin sọ ni pe oun ko mọ ẹṣẹ ti oun ṣẹ Lizzy, biko ṣe pe o n di ẹbi nkan ti awọn ololufẹ oun ba sọ nipa rẹ ru oun.
'Ọjọ ti mo kọkọ foju kan Toyin Abraham lo ti ṣẹ mi'
Amọ ninu ọrọ ti ẹ, Lizzy sọ pe ni bi ọdun mejila sẹyin ni Toyin ti kọkọ ṣe nkan to dun oun.
O ni "ni ileeṣẹ tẹlifisan MITV ni emi ati Toyin ti kọkọ pade.
"Ija kan wa laarin emi ati Iyabọ Ojo. Mo ṣi n gbiyanju lati ki Toyin nigba ti a pade lẹnu ọna abawọle si MITV, a fi bo ṣe bẹrẹ si ni i pariwo pe ṣe iwọ lo n ba Auntie Iyabọ ja?"
O ni Toyin sọ pe ki oun ṣi ikùn oun sita lati fihan pe lootọ ni oun (Lizzy) ti bimọ ri bi oun ṣe n sọ kiri.
Lizzy sọ pe pẹlu itiju ni oun fi ṣi ikun naa, nitori pe o fi dandan le e.
Ẹṣẹ keji ti Lizzy tun sọ pe Toyin ṣẹ ẹ ni pe o kọ iwe si awọn alaabo ni orilẹ-ede Saudi Arabia, lati yẹ ẹru oun wo fun oogun oloro.
O ni bakan naa ni ẹnikan ti sọ fun oun ri pe ọrọ ibajẹ ni Toyin n sọ kiri nipa oun.
Ohun ti Toyin sọ lori gbogbo ẹsun yii ni pe oun ko jẹbi. O ni kii ṣe oun lo n ran awọn ololufẹ oun tabi fun oniroyin kankan lowo lati ba orukọ Lizzy jẹ.
Botilẹ jẹ pe ko si ẹnikẹni ninu awọn mejeeji to sọ ni taara pe ija ti pari, igbagbọ awọn ololufẹ wọn ni pe ija wọn ti pari lẹyin ti kaluku sọ nkan to n dun lọkan.