You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ikọ̀ agbébọn tuntun fi ìdí ibùba rẹ̀ kalẹ̀ sí Zamfara
Iroyin to n tẹ wa lọwọ bayii ni pe ikọ agbebọn mi-in tun ti ṣi ibuba tuntun si ipinlẹ Zamfara, lagbegbe Kuryar Madaro, ijọba ibilẹ Kauran Namoda.
Dan Sa'adi ni wọn pe olori ikọ agbesunmọmi tuntun ọhun.
Ẹnikan to ba BBC sọrọ lai darukọ rẹ niluu naa, ṣalaye pe Dan Sa'adi lo n ko awọn ikọ apaayan ti wọn ti tuka tẹlẹ jọ pada si Zamfara, to si n gba owo lọwọ wọn lati di ọmọ ẹgbẹ tuntun.
Akojọpọ awọn agbebọn tuntun yii ni wọn n ṣiṣẹ ikọlu pọ, bi awọn araalu ṣe wi.
Wọn fi kun un pe gbogbo igbiyanju awọn ẹṣọ alaabo nipinlẹ Zamfara, ko mu nnkan kan wa.
Wọn ni awọn agbebọn to ṣẹṣẹ de yii n kọlu awọn lọ ni.
" Awọn agbebọn to yatọ si awọn ta a ti mọ tẹlẹ ni wọn n kora jọ bayii ti wọn si n da ibuba tuntun silẹ.
"Ẹnikan to n jẹ Dan Sa'adi ni olori wọn. O ti fẹrẹ gba gbogbo ilu tan pẹlu bo ṣe n gba awọn agbebọn mi-in mọra to si n gbowo lọwọ wọn."
Araalu kan lo sọ bẹẹ fun BBC.
O fi kun un pe inu ibẹru lawọn n gbe bayii, nitori awọn agbebọn naa ti da ẹru si ọkan awọn eeyan agbegbe ti oju ti kara wọn mọ naa, ki i ṣe agbegbe to tobi bo ṣe sọ.
BBC kan si Alukoro ẹka aabo Western Front, Ọgagun Abubakar Abdullahi, lati mọ boya o ti gbọ nipa Dan Sa'adi ati ikọ rẹ, ṣugbọn a ko gbọ ohunkohun lati ọdọ re.
Kí ni ìjọba Zamfara n ṣe?
Ọkan lara awọn ipinlẹ Ariwa ti ijinigbe ati ikọlu ti maa n waye pupọ ni Zamfara.
Laipẹ yii ni awọn abajade iwadii kan fidi ẹ mulẹ, pe wọn ti n ṣe aṣeyọri lori ilakaka wọn lati ṣẹgun awọn agbebọn.
Ṣugbọn ni bayii, awọn agbegbe kan tun ti n ke gbajare pe inu ewu lawọn wa ni Zamfara.
Gomina ipinlẹ Zamfara, Dauda Lawal Dare, ti fi ọpọ igba sọ pe oun ko ni i figba-kan-bọkan ninu lori ọrọ awọn agbebọn naa.
Ninu ifọrọwerọ ti Gomina Dauda ṣe pẹlu BBC Hausa lo ti ni oun pinnu bẹẹ, nitori gbogbo ileri ti awon agbesunmọmi ṣe lasiko ipade alaafia tawọn jọ ṣe ni wọn ko tẹle.
Gomina ipinlẹ Zamfara sọ pe ohun toun le fi ba wọn dunaa-dura ni bi wọn ba da gbogbo nnkan ija ọwọ wọn silẹ.
Ipinlẹ Kaduna toun naa n koju igbesunmọmi, ti ba awọn eeyan naa dunaa-dura alaafia, wọn si gbagbọ pe alaafia ti n jọba lawọn apa ibi kan nipinlẹ naa ju ti tẹlẹ lọ.
Ẹ o ranti pe o ti le lọdun mẹwaa ti ikọlu awon agbebọn ti gogò ni Iwọ-Oorun Ariwa Naijiria.
Ẹmi to le lẹgbẹrun lo ti sọnu, dukia bajẹ, ileewe ko ṣee lọ mọ, okoowo ati iṣe oojọ si di afibẹruṣe.