You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
'A ti ṣetán láti gba ipò wa padà bí ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ṣe ti dáwa láre'
Lẹyin ti ile ẹjọ Kọtẹmilọrun ti gbe are fawọn alaga ijọba ibilẹ ni ipinlẹ Osun ti ile ẹjọ giga ipinlẹ naa ni ki wọn lọ rọkun nile lẹyin ti Gomina Ademola Adeleke gbakoso ijọba ipinlẹ naa, awọn alaga ijọba ibilẹ naa ni awọn ti ṣetan lati pada si ori aga wọn gẹgẹ bi alaga ijọba ibilẹ kọọkan wọn.
Ni asiko ti saa gomina ana ni ipinlẹ Osun, Gboyega Oyetola n pari lọ ni eto idibo sipo alaga ati kahunsilọ ni ijọba ibile ọgbọn to wa ni ipinlẹ naa waye nibi ti wọn ti dibo yan awọn alaga naa.
Ẹwẹ, ko ju bii oṣu meji lọ tawọn alaga naa fi wa lori ipo ti ile ẹjọ giga ti ijọba apapọ kan fi ni eto idibo to gbe awọn alaga ati kahunsilọ naa wọle ko kẹsẹ jari, ti gomina Ademola Adeleke si le awọn alaga ati Kahunsilọ ti wọn dibo yan naa kuro lori ipo.
Eyi mu ki awọn alaga naa gba ile ẹjọ Kotẹmilọrun lọ pe awọn ara ilu lo dibo yan awọn, ti awọn si nilo lati lo ọdun mẹta awọn pe lori ipo ti awọn yoo ba ti ẹ kuro nibẹ.
Ni ọjọ Aje ni Ile ẹjọ kotẹmilọrun to n jokoo niluu Akure wa gbe idajọ kalẹ pe ki awọn alaga ijọba ibilẹ pada si ipo wọn gẹgẹ bii alaga ijọba ibilẹ ati awọn kanselọ.
Ile ẹjọ ninu idajọ rẹ paṣẹ pe ki gbogbo alaga ijọba ibilẹ ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC pada sipo gẹgẹ alaga ijọba ibilẹ koowa wọn ni kiakia.
Amọ, ajọ eleto idibo nipinlẹ Osun, OSSIEC ni mimi kan o ni mi eto idibo ijọba ibilẹ to fẹ waye nipinlẹ Osun ni Ọjọ kejidinlogun oṣu keji ọdun 2025.
Ibeere to gba ẹnu ọpọ eeyan ni pe ki ni yoo ṣẹlẹ bayii paapaa sawọn alaga ti ile ẹjọ ni ki wọn pada sipo wọn ati awọn to n gbaradi lati kopa ninu eto idibo ijọba ibilẹ.
Eyi lo mu BBC News Yoruba kan si awọn ti ọrọ kan ni ipinlẹ Osun lati mọ ibi ti ọrọ de duro.
Abiodun Idowu, ọkan lara awọn alaga ìjọba ibilẹ naa, to tun jẹ Alaga ALGON lakoko naa ni awọn ti ṣetan lati pada sipo awọn lati ṣe ojuṣe ti ilu yan awọn fun.
Idowu, to jẹ alaga fun ijọba ibilẹ Ifedayo nigba sọ pe awọn ti ṣetan gba ẹtọ awọn pada gẹgẹ bii alaga ìjọba ibilẹ ati pe ko si ohun kankan n to da awọn duro mọ.
"Iṣẹ ti bẹrẹ lati igba ti ile ẹjọ kotemilorun ti dajọ are fun wa."
O fi kun ọrọ rẹ wi pe awọn ko ni gba ki eto idibo kankan waye ni ipinlẹ Osun ni ọjọ Kejilelogun, oṣu Keji Ọdun yii gẹgẹ bii ajọ eleto idibo nipinlẹ Osun ṣe n mura silẹ fun.
O tẹsiwaju pe awọn ko fẹ owo gba mabinu lọwọ Gomina Adeleke bikoṣe pe ki awọn pada sipo awọn ni.
Ko si a n pada lori eto idibo ti a fẹ ṣe - OSSIEC
Nigba ti BBC News Yoruba kan si alaga ajọ to n ri si eto idibo labẹnu ni ipinlẹ Osun, Hashim Abioye ni kii ṣe wi pe ile ẹjọ kotemilorun ni ki awọn Alaga ana pada si ọfiisi wọn rara.
O ni ohun ti ile ẹjọ Kotẹmilọrun ṣe idajọ le lori ni ẹjọ ti ẹgbẹ oṣelu PDP ipinlẹ Osun pe lori idibo to gbe awọn alaga ijọba ibilẹ naa wọle lasiko ijọba Gomina Oyetola ni ile ẹjọ kotemilorun dahun.
Abioye la a mọlẹ pe eto idibo ijọba ibilẹ ti awọn ti n gbaradi fun yoo waye ni Ọjọ Kejilelogun oṣu Keji yii, ti ko si si ẹnikankan to le da duro rara.
O ni ajọ OSSIEC tabi ijọba labẹ idari Gomina Ademola Adeleke ko ni owo kankan ti yoo san fun awọn alaga ti ile ẹjọ giga ti fi ọwọ osi juwe ile fun rara.
"Ẹnikẹni ba kọja aye rẹ lati tẹ ofin mọlẹ tabi da ilu ru latari idajọ ti ile ẹjọ kotemilorun ṣe, iru ẹni bẹẹ yoo foju wina ofin."
Adeleke kọ lo le awọn alaga ana nipo, ile ẹjọ ni – Kolapo Alimi
Kolapo Alimi, ẹni to jẹ Kọmisanna fun eto iroyin nipinlẹ Osun ti wa sọ afọmọ ọrọ pe kii ṣe Gomina Ademola Adeleke lo fi ọwọ osi juwe ile fun awọn alaga naa gẹgẹ bi awọn eeyan kan ṣe n gbe kiri bikoṣe ile ẹjọ.
Alimi sọ pe awọn ko ri ninu idajọ ti ile ẹjọ Kotemilorun ṣe wi pe, ki awọn alaga ana naa pada si ọfiisi rara.
O ni Gomina Ademola Adeleke ti paṣẹ fun awọn agbofinro lati duro ni ẹnu ọna ijọba ibilẹ kọọkan lat5i fi eto aabo mulẹ, ki wọn si ma ṣe fi aye gba ẹnikẹni ninu awọn alaga ana lati wọle.
O fi kun wi pe eto idibo ijọba ibilẹ ti awọn fẹ ṣe yoo waye gẹgẹ bii Alaga eleto idibo ṣe kede
Ki ni ofin sọ?
Amofin agba kan ni ipinlẹ Muhydeen Adeoye ni ootọ ni pe ile ẹjọ giga lo fi ọwọ osi juwe ile fun awọn alaga naa ti wọn si pe ẹjọ naa nija gẹgẹ bo ṣe wa labẹ ofin.
"Sugbọn, wọn ti lọ si ile ẹjọ kotemilorun, ti a si mọ labẹ ofin wi pe, ko si ohun to buru nibẹ lati pe fun ẹjọ kotemilorun.
"Eyi ni ẹgbẹ oṣelu APC ẹka ti ipinlẹ Osun ṣe, ti ile ẹjọ kotemilorun si da wọn lare ni ana ọjọ Kẹwaa, oṣu Keji, ọdun yii."
Adeoye ni ti ọrọ ba ri bayii, gomina Adeleke nilo lati fi aye gba aṣẹ ile ẹjọ, ki wọn da gbogbo eto idibo ti wọn n gbero tẹlẹ duro lati bọwọ fun aṣẹ ile ẹjọ.
O wa gba ijọba Gomina Ademola Adeleke nimọran lati da ọwọ idibo sipo alaga ijọba ibilẹ duro, ki wọn lọ sile ẹjọ to ga julọ nilẹ wa, to ba jẹ pe wọn le gbọ ẹjọ naa.
Muhydeen Adeoye, ni ko tọna labẹ ofin lati mu ki idibo naa ko waye lẹyin ti ile ẹjọ Kotemilorun ti ṣe idajọ.
APC, PDP l‘Osun tẹsẹ̀ bọ ṣòkòtò kan bílé ẹjọ̀ kòtẹ́milọ́rùn ṣe ní káwọn alága ìjọba ìbílẹ, tí gómìnà Adeleke yọ nípo, bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ padà lọ́gán
Ile ẹjọ kotẹmilọrun to n jokoo niluu Akure ti gbe idajọ kalẹ pe ki awọn alaga ijọba ibilẹ ti Gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke yọ nipo nigba ti o bọ sipo gẹgẹ bii Gomina, pada si ipo wọn gẹgẹ bii alaga ijọba ibilẹ ati awọn kanselọ.
Ile ẹjọ ninu idajọ rẹ lọjọ Isẹgun paṣẹ pe ki gbogbo alaga ijọba ibilẹ ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC pada sipo gẹgẹ alaga ijọba ibilẹ koowa wọn ni kiakia.
Ẹwẹ, ajọ eleto idibo nipinlẹ Osun, OSSIEC naa ti pe ẹjọ tako idajọ ile ẹjọ, ti wọn jẹ ko di mimọ pe ko ṣeeṣe rara.
Alaga ajọ eleto idibo naa, Hashim Abioye ni mimi kan o ni mi eto idibo ijọba ibilẹ to fẹ waye nipinlẹ Osun ni Ọjọ kejidinlogun oṣu keji ọdun 2025.
Igbaradi idibo ijọba ibilẹ si n lọ lọwọ, idajọ ile ẹjọ ko si yi nkankan pada - PDP
Abioye sọ eyi lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ niluu Osogbo lọjọ Aje lori idajọ ile ẹjọ kotẹmilkọrun nipa ẹjọ ti awọn alaga ẹgbẹ oṣelu APC pe.
Ọdun 2022 ni ẹgbẹ oṣelu APC gbe ijọba ipinlẹ Osun lọ si ile ẹjọ lori iyọnipo awọn alaga ijọba ibilẹ to ba gomina ana sisẹ ti wọn yọ nipo.
Alaga ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Osun, Sunday Bisi ti wa fi da awọn araalu loju pe igbaradi eto idibo ijọba ibilẹ si n lọ lọwọ, ti idajọ ile ẹjọ ko si yi nkankan pada.
Ninu atẹjade kan to buwọlu fawọn akọroyin, PDP wọgile erongba ẹgbẹ oṣelu APC pe ile ẹjọ ti paṣẹ pe ki wọn pada sipo gẹgẹ bi alaga.
"Nnkan ko yi pada rara. A n gbaradi fun eto idibo ijọba ibilẹ. A ti kan si awọn agbẹjọro wa pe ile ẹjọ to ga ju ti ya.
"A ni lati tako ọna ẹburu ti ẹgbẹ oṣelu APC fẹ gba lati da ijọba ru gẹgẹ bi wọn ṣeeṣe ni ọdun 2022."
Bakan naa ni alaga ẹgbẹ oṣelu APP nipinlẹ Osun, Odesola Titus naa wọgile erongba ẹgbẹ oselu APC lati awọn alaga ijọba ibilẹ to yan pada sipo.
Odesola ni ko si nnkan to jọ mọ pe awọn alaga ti tẹlẹ n pada bọ sipo .
O wa rọ awọn araalu lati bẹrẹ si ni gbaradi fun eto idibo ijọba ibilẹ ninu oṣu keji yii.
A ko ni fi aye gba ki irufẹ ohun to wa nipinlẹ Rivers, waye nipinlẹ Osun – Ile igbimọ aṣofin
Olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Osun, Adewale Egbedun ti ṣekilọ fun ẹgbẹ oṣelu APC pe ki wọn ma ni erongba lati da wahala silẹ ni Osun lẹyin idajọ ile ẹjọ.
Egbedun ni awọn n ke pe ọga agba fun ileeṣẹ ọlọpaa lati ri pe wọn gba igbesẹ lati da bobo fun ẹmi ati dukia awọn araalu nipinlẹ Osun.
"A ko ni faya gba ohun to waye nipinlẹ Rivers waye ni Osun," Egbedun ṣekilọ
Bakan naa ni olori ile fẹsun kan Gomina ana nipinlẹ Osun, Gboyega Oyetola pe o lọwọ ninu ija oṣelu to fẹ bẹ silẹ nipinlẹ Osun
APC fesi pe ko tọ si olori ile asofin l‘Osun lẹnu lati nawọ abuku si Oyetola pe oun lo n da Ọsun ru
Ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress ti bu ẹnu atẹ lu iha ti ẹgbẹ oṣelu People Democratic Party kọ si idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun naa.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ẹgbẹ oṣelu APC, Kola Olabisi fisita lori idajọ naa, o bu ẹnu atẹ lu olori ile igbimọ aṣofin, Adewale Egbedun lori bi o ṣe mu ọrọ Gomina Oyetola bọnu lori ohun to n sẹlẹ lọwọ nipinlẹ Osun.
"Ko tọ si olori ile lẹnu lati nawọ abuku si Gomina Oyetola pe oun lo n da Ọsun ru.
"Ki lo de to jẹ pe ori PDP nikan wọn ki n tẹwọ gba aṣẹ ile ẹjọ?
Ẹgbẹ oṣelu APC tun fẹsun kan PDP pe wọn ni erongba lati tapa si ofin orilẹẹde Naijiria, ti wọn ko si fẹ ki idajọ ile ẹjọ fẹsẹ mulẹ.