Á bẹ̀rẹ̀ ìkọlù padà tí Hamas kò bá tú gbogbo ọmọ Israel tó wà ní ìgbèkùn rẹ̀ sílẹ̀ títí Sátidé - Netanyahu

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Orilẹede Israel ni awọn yoo pada sidi ogun, ti awọn yoo si tun wọgile adehun jogun-o mi ti Hamas ba kuna lati tu awọn eeyan to wa ni ahamọ silẹ ni ọjọ Satide to n bọ.

Olootu ijọba Israel, Benjamin Netanyahu ti wa palaṣẹ ki gbogbo ọmọ ogun korojọ si agbegbe Gaza ṣugbọn Hamas ni Israel lo n mu idaduro ba adehun naa.

Hamas sun itusilẹ awọn eeyan to wa ni ahamọ to yẹ ko waye ni lopin ọsẹ yii siwaju, ti wọn si da Israel lẹbi pe o tapa si adehun wọn, bo ti lẹ jẹ pe wọn jẹ ko di mimọ pe awọn fẹ jẹ ki ogun mi.

"Aaye wa fun Amẹrika, Qatar ati Egypt lati da si ọrọ naa, ki adehun jogun o mi pada sipo"

Ohun to tẹ wa lọwọ ni pe awọn orilẹede Arab fẹ ki Hamas yara si mimu adehun naa sẹ, ki wọn si tu awọn eeyan Israel to wa ni ahamọ silẹ.

"Ti Hamas ko ba da awọn eeyan wa pada ni ọjọ Ṣatide, opin yoo de ba adehun," , Netanyahu ṣekilọ

Ninu ọrọ rẹ, olori ikọ Hamas Basem Naim sọ fdun BBC pe aye wa fun awọn orilẹede bi Amẹrika, Qatar ati Egypt lati da si ọrọ naa pe ki adehun jogun o mi pada sipo.

"A ko fẹ ki adehun yẹ, a n sa gbogbo agbara wa lati ri pe eyi ko waye , a ti setan lati tu awọn eeyan yii silẹ ti wọn ba dahun awọn ibeere wa."

Bakan naa ni Hamas ni wọgile erongba Aarẹ Trump lati gba aṣẹ Gaza, ti wọn si ṣapejuwe ọrọ Aarẹ Trump gẹgẹ bii eyi ti ko bojumu.

Ẹ fagilé àdéhùn jógun-ó-mí àyàfi tí Hamas bá tú gbogbo ọmọ Israel tó wà nígbèkùn rẹ̀ sílẹ̀ - Trump

Aarẹ Donald Trump orilẹede Amẹrika ti sọ pe orilẹede Israel ni lati fagile adehun idawọ ogun duro to buwọlu ti ẹgbẹ Hamas ba kọ lati tu awọn ọmọ Israel ti wọn ko ni igbekun silẹ.

Aarẹ Trump ni Hamas gbọdọ tu awọn ọmọ Israel to jigbe ni Gaza silẹ titi ago mejila ọsan ọjọ Abamẹta to n bọ, bi bẹẹ kọọ, Israel gbọdọ ṣina bolẹ.

Trump sọrọ yii lẹyin ti Hamas sọ pe idi tawon ko fi tii tu awọn ọmọ Israel to wa ni akata awọn silẹ ni pe Israel si tapa si adehun jógun-ó-mí t'awọn jọ tọwọ bọ.

Ọmọ Israel mẹtadinlogun lo yẹ ki Hamas tu silẹ bo ti wa ninu adehun ti wọn jọ tọwọ bọ

Ẹwẹ, ijọba Israel ti ṣapejuwe igbesẹ Hamas gẹgẹ bi ọna lati doju adehun jógun-ó-mí t'awọn ṣe bolẹ.

Israel sọ pe awọn ọm'ogun oun ti wa ni igbaradi fun ohunkohun to ba ṣẹlẹ ni Gaza.

Ọmọ Israel mẹtadinlogun lo yẹ ki Hamas tu silẹ bayii gẹgẹ bi o ti wa ninu adehun ti wọn jọ tọwọ bọ.

Mẹjọ ninu awọn eeyan metadinlogun yii ni Israel sọ pe wọn ti ku, nigba to jẹ pe ọgọọgọrun un awọn ọmọ Palestine to wa lẹwọn ni Israel lo ti gb'ominira bayii.

Ṣaaju ipade rẹ pẹlu Ọba Jordan, Abdullah, Aarẹ Trump ni oun le paṣẹ idaduro iranwọ ti Amerika n ṣe fun Jordan ati Egypt ti wọn ba kọ lati gba awọn ogunlende lati Gaza.

Ọkunrin ọmọ Israel ẹni ọdun 86 ku si igbekun Hamas

Minisita ileeṣẹ ọmogun Israel, Katz, ti ranṣẹ ibanikẹdun si ẹbi Shlomo Mansour, lẹyin ti wọn kede iku rẹ laarọ ọjọ Ìṣẹgun.

Ni Kibbutz Kissufim ni wọn ti ko Mansour ni igbekun nibi to n gbe to si ti ṣiṣẹ bi ọga agba ileeṣẹ ti wọn ti n sin adirẹ.

Mansour wa lara eeyan mẹtalelọgbọn ti ijọba Israel fẹ ki Hamas kọkọ fun lominira ni igbekun rẹ.

Ọgbẹni Katz sọ loju opo X rẹ pe ijọba yoo tẹsiwaju akitiyan rẹ lati ri pe gbogbo ọmọ Israel to wa ni igbekun Hamas gbominira bo ya wọn si wa laaye tabi wọn ti ku.

Ẹwẹ, agbẹnusọ fun Hamas, Sami Abu Zuhri, ni Aarẹ Trump gbọdọ ranti pe ati Hamas ati Israel lo gbọdọ tẹ le adehun ti wọn jọ buwọlu ti o ba fẹ ki gbogbo ọmọ Israel to wa ni igbekun Hamas gbominira.

Zuhri ni iwa idunkoko mọ ni kii ṣe ọna abayọ sí ọrọ to wa nilẹ, bi ko ṣe wi pe o maa n ba nnkan jẹ si ni.

Lanaa ọjọ Aje ni Trump sọ pe ibọn yoo maa ro lakọlakọ ti Hamas ko ba tu awọn ọmọ Israel to ku ni igbekun rẹ silẹ titi ago mejila ọsan ọjọ Abamẹta to n bọ.

Ti ẹ o ba gbagbe, ọmọ Israel merindinlogun ni Hamas ti tu silẹ, pẹlu ireti pe yoo tun fawọn mẹtadinlogun mii lominira ninu eyi ti Israel sọ pe mẹjọ ninu wọn lo ti ku.