Ta a ni Natasha Osawaru, tí 2face Idibia kéde pé òun fẹ́ ẹ́ fẹ́?

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọrọ nipa ohun to ṣẹlẹ si igbeyawo gbajugba olorin takasufe, Innocent Idibia, ẹni ti ọpọ mọ si 2face, lo tun gba ọna tuntun yọ si awọn ololufẹ rẹ.

Ni bi ọsẹ diẹ sẹyin ni 2face kede pe oun ati iyawo rẹ, Anni Idibia ti fopin si igbeyawo wọn.

Ni ọjọ Isẹgun ana, ọjọ kọkanla oṣu keji ọdun 2025 ni 2face tun gbe fọnran miran sita, to si n fi idi erongba rẹ lati fẹ Natasha Osawaru, ọmọ ile igbimọ aṣofin nipinlẹ Edo, mulẹ.

Saaju ni fọnran kan ti kọkọ lu sita nibi ti ọpọ eeyan ti suru bo 2face nigba to se abẹwo si ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Edo.

Ọpọ eeyan lo bẹrẹ si ni sọ pe 2face wa si ile igbimọ aṣofin lati wa sabẹwo si ọkan ninu awọn amofin, Natasha Osawaru.

Lẹyin abẹwo si ile igbimọ aṣofin ni 2face gbe fọnran mi sita, to to isẹju mẹta, to si sọrọ nipa ohun to sẹlẹ ni ile igbimọ aṣofin Edo ati ajọsepọ rẹ pẹlu ọmọ ile igbimọ aṣofin, Natasha Osawaru.

Ninu fọnran naa, 2face ni ki onikaluku maa sọ ohun ti wọn ba fẹ sọ nitori oun ni oun gbe ọrọ wa sita fun wọn lati da si.

"Fun ẹni to ba fẹ gbọ, mo ti sọ otitọ temi. Ẹ tẹsiwaju lati se ariyanjiyan. Gbogbo wa ni a ma wapa ni igbẹyin."

Ta a ni Natasha Osawaru

Orukọ abisọ rẹ ni Natasha Irobosa Osawaru ṣugbọn ọpọ ma n pe ni Ọnarebu Natasha.

O jẹ oloṣelu ati ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Edo, to si tun jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party.

Ohun ti a ko jọ lati ikanni ajọ eleto idibo ni pe o wa lati ijọba ibilẹ Egor nipinlẹ Edo.

Wọn bi ni ọjọ kẹrinla oṣu kọkanla ọdun 1994. Yoo pe ọmọ ọdun mọkanlelọgbọn ni ọdun 2025.

Lọwọ yii, oun ni igbakeji olori ẹgbẹ oṣelu to pọju ni ile igbimọ aṣofin nipinlẹ Edo.

Natasha kawe gboye imọ ofin lati fasiti Igbinedion nipinlẹ Edo ati ni fasiti Full Sail lorilẹede Amẹrika.

Ko to darapọ mọ oṣelu, o jẹ ọkan gboogi lara ọmọ ẹgbẹ to n pe fun idagbasoke awọn obinrin lawujọ.

Ta a ni Innocent Idibia?

Wọn bi gbajugbaja olorin innocent Idibia,ẹni ti ọpọ mọ si 2face niluu Jos nipinlẹ Plateau.

O wa lati ipinlẹ Benue.

2face jẹ onkọrin to lamilaka lagbaye, to si kọ ọpọ orin, gba ọpọ ami ẹyẹ lorilẹede Naijiria, ni ilẹ Afirika ati lagbaye lapapọ.

Saaju ko to ma da kọrin, o wa ninu ẹgbẹ akọrin Plantashun Boiz, ti wọn si jẹ mẹta ti wọn jọ n kọrin.

Oun, Faze ati Blackface