Àràbarà ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rèé tí wọn yóò fí gbé Ọba Charles III lásìkò ìwúyè rẹ̀

Ipalẹmọ ti n doju rẹ bayi fun eto iwuye Ọba ilẹ Gẹẹsi, Ọba Charles kẹta.
Ni iwaju oju ọna to lọ si aafin Buckinham Palace awọn araalu ti n pese de ayẹyẹ ati anfaani lati foju ba Ọba ni ọjọ Abamẹta.
Ni Westminster Abbey ni iwuye yi yoo si ti waye.
Amọ ati de ibi iwuye yi, ọkọ ayọkẹlẹ meji to wa loju iran yin yi ni wọn yoo fi gbe Ọba Charles ati iyawo rẹ
Ọkọ alawọ goolu yi jẹ aramọnda ti o yatọ kedere si awọn ọkọ miran.
Akọkọ ohun to mu ọkọ yi yatọ ni pe igba akọkọ ree ti wọn yoo lo nibi ayẹyẹ iwuye.
Lati ọdun 2014 ti wọn ti gbe ọkọ naa wa fun Ọbabinrin Elizabeth, ko si eeyan kankan to wọ inu rẹ tabi to lo lọ si ode.
Yatọ si eleyi, ọkọ ayọkẹlẹ yi gun ni iwọn mita marun un to si wuwo to tọọni mẹta.
Awọn igi olowo iyebiye to sọwọn ni wọn lo lati fi ṣe itẹnu ọkọ naa.
Ni apejuwe pẹlu awọn ọkọ miran, ọkọ goolu yi ga yatọ.
O si tun ni ade wura nla kan lori rẹ.
Lẹyin iwuye ọkọ aramọnda mi ti wọn yoo fi ẹsin fa ni yoo gbe Ọba Charles ati iyawo Ọba Camilla pada si Buckingham Palace.
Ni ti tiẹ, o fẹ ẹ ga to mita mẹrin to si gun to mita meje.
Ohun ni ọkọ todagba julọ ṣikeji lagbaye ni eleyi to ṣi n ṣiṣẹ.
Ọdun 1762 ni wọn ṣe ọkọ taa n wi yi.
Opin ọsẹ alarinrin ni iwuye yi yoo jẹ. Koda wọn tun ti kede ọjọ isinmi lọjọ Kẹjọ oṣu Karun nitori ayẹyẹ yi.






