Ohun tó yẹ kóo mọ̀ nípa Oke Igeti áti ọdún ifá

Ayẹyẹ ọdun ifa ati orisa ti bẹrẹ lati ọjọ kejidinlogun oṣu karun un ọdun 2024, ti awọn ẹlẹsin ibilẹ kaakiri gbogbo ilẹ Yoruba si peju lati rin irinajọ lọ si ilẹ mimọ naa.
Awọn elesin ifa naa ni wọn ko ra wọn jọ ni ilu Ado Ekiti ti o je orirun ifa lati ṣe ayajọ Ọdun Ifa ati Orisa agbaye Oke Igeti 2024.
Lẹyin ti wọn ti lọ kaakiri gbogbo awọn ile orisun oriṣa ni ipinlẹ Ekiti, ni wọn ayẹyẹ naa si Oke igeti nibi Ọrunmila fi ṣe ibugbe nigba ti o wa ni ile aye.
Oke-Igeti ni wọn wa bayii je ile Ọrunmila nibi ti gbogbo awọn onifa lagbaye ti wa ma n bo ifa paapọ ati lati se iwure leẹkan lọdun.

Lara awọn nkan ti o wa ni Oke Igeti ni awọn ape ti Ọrunmila fi n gbe ipese, igi Iyere Osun, ijoko Ọrunmila ati ikoko omi rẹ.
Wọn ni pataki ti Oke Igeti wa fun ni lati se wure gege bi ọmọ Ọrunmila
Lọjọ kejidinlogun oṣu yii ni wọn bẹrẹ si ni ma gba awọn eeyan kaakiri agbaye ni alejo, ti wọn si gbera lọ Ikole Ekiti ni odo Erinjinyan
Bakan naa ni wọn morile Esu Ijelu ati bi ti wọn gbagbọ pe Ogun lakaaye ti saa rẹ nigba to wa laaye.
Wọn tun gbera lọ Igbede Ekiti ni bu ti wọn gba gbọ pe o jẹ ile Osun ati ibẹ ni omi Osun ti san wa
Awọn ẹlesin isese ni gbogbo agbaye ti wa ro awọn ọmọ ilẹ kaaro ojire lati gbajumo ẹṣin awọn baba nla wọn nibi ayajọ Ọdun Ifa agbaye ni wọn sọrọ naa nigba ti wọn nṣe abewo si awọn ojubo isenbaye ti o wa kaakiri ipinle Ekiti.


Ki ni o wa ni Oke Igeti?
Ọpọlọpọ nnkan to jọ nnkan lo wa ni Oke Igeti, ti oke naa si ni ọpọlọpọ apere ti wọn fi n da ifa ati eyi ti wọn n fi pese ẹbọ ni aye ijọ















