Kí ló ṣẹlẹ̀ tí ṣokóléètì àti kòkó ṣe ń fi ojoojúmọ́ gbówó lórí?

Oríṣun àwòrán, Reuters
- Author, Nkechi Ogbonna
- Role, BBC News
- Reporting from, Lagos
O ṣeeṣe ki o ṣakiyesi pe ṣokoleeti ti o fẹran ti wọn ju iye owo ti wọn n ta a tẹlẹ lọ.
Jafar Mohammed, to n ta tii gbigbona niluu Kano sọ fun BBC pe iye ti oun n ta tii ti pọ ju ti tẹlẹ lọ, eyi ko si ṣẹyin bi awọn nnkan ti oun po pọ ṣe wọn si.
Gbogbo eyi ko ṣẹyin bi ‘cocoa’ to jẹ eroja ti wọn fi n ṣe tii ṣe gbowo lori ni ida 130% laarin ọdun kan sẹyin.
Awọn to n gbin kòkó sọ pe o ri bẹẹ latari ọgbẹlẹ atawọn arun to n kọlu oko kòkó.
Oju ọjọ El Niño to kọlu awọn orilẹede bii Ghana ati Ivory Coast, to jẹ orilẹede meji to ni eso kòkó julọ nilẹ Afrika tun ṣakoba fun eso ọhun.
Jack Scoville, to jẹ onimọ nipa iye owo ọja ni ajọ Price Futures Group sọ pe “awọn oniṣowo n kọminu lori bi wọn ko ṣe ni le ri ere to tọ jẹ lọdun yii latari bi oju ọjọ ṣe ri pẹlu wahala ti El Niño n da silẹ.”
Ni ti Mohammed to n ta tii, o ni “inu mi ko dun bi ọja naa ṣe n gbowo lori amọ ko si nnkan ti mo le ṣe si.”
Mohammed, to maa n pa nnkan bii ẹgbẹrun mẹta naira loojọ tẹlẹ ni oun gbọdọ fi kun owo ọja oun ki ti oun ko ba fẹ kogba wọle.
Iwọ oorun ilẹ Afrika ni wọn ti n ri ida 70% kòkó ti wọn fi n tii ati ṣokoleeti lagbaye.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Kí ló ṣokùnfà ìṣòro náà?
Lati ọdun meji sẹyin ni iye koko ti wọn n ri ka ni Ghana ati Ivory Coast ti n dinku.
Ajọ to n bojuto ọrọ koko ni Ghana, COCOBOD sọ pe arun kan to maa n mu ki koko wu ti pa ilẹ oko ti iye rẹ to ẹka 500,000 rẹ.
COCOBOD ni arun naa maa n pa kook bẹẹ lo tun maa ba ilẹ oko jẹ.
Oju ọjọ to mooru ju bo ṣe yẹ lọ naa tun pa kun iṣoro ọhun.
Ni Ivory Coast, tọọnu koko ti iye rẹ to 2.3m ni wọn ri nibẹ laarin ọdun 2022 si 2023 amọ ami ti wa pe o ṣeeṣe ki wọn ma ri to iye naa lọdun 2023 si 2024.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Bo tilẹ jẹ pe iye to wu onikaluku lo n ta koko rẹ ni Naijiria, COCOBOD lo n ṣakoso iye owo koko ni Ghana.
Ni Ghana ati Ivory Coast, ijọba lo maa n pinnu iye owo ti won gbọdọ ta koko.
Lọdun to kọja, ijoba Ghana kede pe awọn to n ta koko jere ti iye rẹ to ida aadọta ṣugbọn inu awọn agbẹ to n gbin koko naa ko dun si iye to wọle si apo wọn.
Awọn agbẹ naa ni iya ti wọn n jẹ lori koko ko to iye owo ti awọn funra wọn n ri lori rẹ.
Ẹwẹ, awọn ti ọrọ kan bii ajọ to n ri si ọrọ koko lagbaye, ICO, ti ke si awọn ileeṣe to n po ṣokoleeti ati ijọba pe ki wọn kowo to pọ sori koko ki nnkan le rọrun fun awọn agbẹ to n gbin koko naa atawọn araalu to n ra tii ati ṣokoleeti atawọn nnkan mii to n jade lati ara koko.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Lọsẹ to kọja, ileeṣẹ Soapry, to n ṣe ipara nilẹ Gẹẹsi sọ fun awọn onibara rẹ pe ọwọngogo koko n ni ipalara lori owo oun.
Oludasilẹ ileeṣẹ naa, Andy Knowles sọ fun BBC pe oun ti fi owo ti ileeṣẹ naa ni si ipamọ ra koko tan latari bi koko ṣe wọn to.












