You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àlàyé rèé lórí bí gbájúẹ̀ ṣe ń lu aráàlú ní jìbìtì ní UK, Amẹrika, Australia àti Canada
- Author, Elaine Chong
- Role, BBC Trending
- Reporting from, UK
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Ọpọ awọn onijibiti ori ayekujara lo ti bẹrẹ si n dojukọ awọn eeyan ilẹ China bayii lati gba owo ati dukia wọn lọna ẹburu.
Lẹyin ti wọn gba ọpọ eeyan ni UK, Amẹrika, Australia ati Canada, ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii, bẹẹ ni awọn ti wọn ko sọwọ awọn onijibiti naa n wa awọn afurasi ọhun ki wọn le foju wina ofin.
Ọmọ orilẹede Malaysia ni Mungnee amọ ilu London lo fi n ṣebugbe.
Obinrin kan pade rẹ lagbegbe Harrow Road ni West London pẹlu omije loju, o si n beere ibi ti awọn oniwosan ilẹ China wa tori ọkọ oun n ṣaisan.
Loju kan naa ni ẹlomiran ba wọn nibẹ, to si sọ pe oun mọ oniwosan ọhun ati pe oun le mu awọn mejeji de ibi to wa.
Mungnee ba wọn lọ lọna ati ṣeranwọ fun obinrin ti ọkọ rẹ n ṣaisan.
Ibi ti wọn ti n lọ ni obinrin mii tun ti pade wọn, ti oun ni tirẹ sọ pe oun mọ oniwosan naa, koda mọlẹbi oun ni.
"Oniwosan atawọn obinrin ti wọn jọ lọ sọdọ rẹ gba 4000 Pọnu lọwọ Mungnee ati eṣọ ara fun adura, eyi ti wọn ko da pada"
Nigba ti wọn de ọdọ oniwosan naa ti wọn sọrọ, oniwosan ọhun sọ pe Mungnee funra rẹ ni iṣoro, o si nilo iranlọwọ.
Lẹsẹ kan naa ni oniwosan ọhun bẹrẹ si n mẹnuba awọn iṣoro ti Mungnee ni ninu igbeyawo rẹ, ẹsẹ ọtun rẹ to n dun un atawọn nnkan mii ti Mungnee ko sọ nibẹ.
Lẹyin naa ni oniwosan ọhun sọ fun Mungnee pe “ọmọ rẹ ọkunrin yoo ni ijanba ọkọ laarin ọjọ mẹta si asiko yii, yoo si gba ibẹ jade laye.”
O wa sọ fun wi pe oun le yanju iṣoro ti Mungnee n dojukọ atawọn iṣoro mii to ṣeeṣe ko waye lọjọ iwaju.
Lẹyin eyii, oniwosan naa atawọn obinrin ti wọn jọ lọ sọdọ rẹ sọ fun Mungnee pe ko ko owo diẹ ati eṣọ ara sinu apo kan fun adura, pẹlu ileri pe wọn yoo da awọn nnkan naa pada fun un.
Ọkan ninu wọn tẹle lọ sile rẹ lati ko awọn ẹṣọ ara to wa nibẹ, wọn tun gba owo to le £4,000 ninu apo iṣuna rẹ.
Wọn ko gbogbo rẹ sinu apo kan, amọ Mungnee gbagbọ pe asiko ti wọn n ṣe eyii ni wọn paarọ apo naa.
Nigba ti wọn gbadura si apo ti owo ati ẹṣọ ara rẹ wa ninu rẹ tan da pada fun.
Ṣugbọn nigba ti yoo fi de ile, biriki, akara oyinbo ati igo omi meji lo ba ninu apọ ọhun.
O ni lara awọn dukia ti oun padanu sọwọ awọn onijibiti naa ni awọn ẹsọ to ti wa ninu iran oun fun ọjọ pipẹ ati eyii ti iya-iya ati iya oun fi jogun fun oun.
Ki lo n jẹ Blessing Scam?
Ohun to ṣẹlẹ si Mungnee yii ni wọn n pe ni “blessing scam.”
BBC ba ọpọ awọn ti wọn ti ko sọwọ gbajuẹ “blessing scam” sọrọ, iriri gbogbo wọn fara jọra.
Gbogbo awọn eeyan naa lo padanu owo wọn sọwọ awọn oni gbajuẹ ọhun laarin wakati perete lọjọ kan pere.
Ni ti Mungnee, aarin wakati mẹta pere ni wọn pari iṣẹ tirẹ.
Anqi Shen, to jẹ Ọjọgbọn nipa imọ ofin ni fasiti Northumbria, to tun ti fi akoko igba kan ri jẹ ọlọpaa ni China sọ pe “blessing scam” jẹ ọkan gboogi lara awọn ọna gbajuẹ atijọ ti awọn eeyan n lo.
Tuyet van Huynh ti bẹrẹ si n kede lori ikanni agbaye lati ṣe itaniji fun awọn eeyan nipa “blessing scam” lẹyin ti wọn lu iya rẹ ni jibiti ọpọlọpọ owo ninu oṣu Karun un, ọdun yii.
Upton, to wa ni East London ni iya rẹ ọhun ti n ra ọja ki awọn obinrin mẹta kan to lọ ba ki wọn to lu u ni gbajuẹ.
Awọn ọlọpaa ni Amẹrika, Canada, ati Australia ti bẹrẹ si n ṣekilọ faraalu nipa “blessing scam” ọhun.
Ni UK, Mungnee ati iya Tuyet ti lọ fi ọrọ naa to ọlọpaa ilu London leti, awọn ọlọpaa ọhun si sọ pe kii ṣe ti wọn ni akọkọ iru rẹ ti yoo ṣẹlẹ.
Tuyet ni oun gbọ pe wọn ti lo gbjauẹ “blessing scam” naa fun ọpọ awọn mii ni Lewisham, Romford, Liverpool ati, Manchester.
Iya Tuyet sọ pe oun ko mọ bi awọn onijibiti naa ṣe tan oun jẹ.
Tuyet ni ṣe lo da bii pe ṣe ni wọn lo oogun fun iya oun lati le lo gbajuẹ ọhun fun un.
Amọ o ni o ṣeeṣẹ ko jẹ pe oogun kan ti wọn n fi ewe “Devil’s Breath” po pọ ni wọn lo fun iya oun bo tilẹ pe ko ri ẹri kankan pew ọ ṣe bẹẹ.
A ko le sọ boya wọn n lo oogun “devil’s breath” naa lati lu awọn eeyan ni jibiti nilẹ Gẹẹsi, to ba ri bẹẹ gan, yoo ṣoro lati fidi rẹ mulẹ.
A gbọ pe oogun naa maa n tete poora ninu agọ ara eeyan, fun idi eyii, nigba ti Tuyet ṣe ayẹwo fun iya rẹ lọjọ keji ti wọn lo gbajuẹ fun, o ti pẹ ju.
Lisa Mills, to jẹ ogbontarigi ninu ajọ Victim Support sọ pe yatọ si oogun lilo, awọn oni gbajuẹ ni awọn ọna mii ti wọn fi n mu awọn ti wọn ba fẹ lo gbajuẹ fun.
Lọwọ yii, ọwọ ofin ko tii tẹ awọn onijibiti naa amọ awọn mọlẹbi awọn ti wọn gba ni awọn ko ni sinmi titi ti ọwọ yoo fi tẹ wọn.
Mungnee sọ pe “mo ti sọ fun ọlọpaa pe mo ṣetan lati fun ni ohun ti yoo gba ki ọwọ le tẹ awọn afurasi naa.”
Ohun to ba Mungnee ninu jẹ julọ ni pe awọn ọmọ ilẹ China bii tirẹ naa lo lu u ni jibiti.
Austin Landis wa lara awọn to ko iroyin yii jọ lati Colombia.