'$1,600 ni mo san fún àwọn tó lù mí ní jìbìtì owó Hajj, mi ò rí Mecca lọ'

Ni ofiisi ajọ to n risi irinajo Hajj ati Umrah to wa ni ilu Saudi Arabia, ni okunrin kan ti n jẹ Suleiman al-Shaer ọmọ ilẹ ede Palestine jokoo si pẹlu iporuru ọkan bo ti mu iwe irinna ilẹ Egypt rẹ dani.

Lẹyin wakati diẹ, o ṣakiyesi pe oun ti kosi pampẹ awọn onijibiti to fi ayederu iwe irinna ti wọn buwọlu lati ile iṣẹ to wa fun ọrọ Hajj ransẹ si i.

Ni ọsẹ kan ṣaaju ni Sulaimon ti de si Ilu Mecca lati ilu Egypt pẹlu iwe irinna abẹwo ṣiṣe, kete to gunlẹ lo ti kan si ile iṣẹ to polowo ọrọ irinajo Hajj naa fun-un nipasẹ itakun ayelujara.

Nitori pe iye owo ti irinajo naa yoo na ko fi bẹẹ pọ rara, pẹlu ero ọkan pe ile iṣẹ naa le ran oun lọwọ, ṣugbọn o bọ si pampẹ awọn onigbajuẹ.

‘Mo san owo fun wọn, wọn fi iwe irinna silẹ Hajj ṣọwọ si mi, Amọ laipẹ ni mo ṣakiyesi pe mo ti bọ sọwọ, tori pe gbogbo iwe ti wọn fi ransẹ ayederu ni’

Suleimon salaye wi pe iṣẹlẹ naa ko fun oun lanfaani ati kopa ni bi eto Hajj lọdun yii, bẹẹ ni awọn aṣoju ile iṣẹ naa kọ lati gbe ipe rẹ lori ẹrọ ilewọ.

Wọn ko fun mi lanfaani ati wọle si Mecca

Agbani nimọran ajọ to wa fun irin ajo Hajj ati Umrah to tun jẹ alabojuto awọn ile iṣẹ eleto igbafẹ ni ilẹ Saudi Arabia, Saad al-Qurashi, pẹlu ojuṣe rẹ ti wa lọrọ ṣiṣe ayẹwo iwe irinna awọn to ba wa si Mecca.

O sọ fun BBC pe ọpọ eeyan lo saba maa n wa ni iru ipo ti suleimon wa, lẹyin igba tiwọn ba ti gunlẹ si olu ile iṣẹ wọn tan.

Al-Qurashi salaye tẹsiwaju sii pe iporuru ọkan lo saba maa n bawọn eeyan naa nigba ti ajọ ọun ba ti sọ fun wọn pe ayederu ni iwe irinna ati ẹgba ọwọ awọn arinrin ajo to wa lọwọ wọn

Kete ti eyi ba ti ṣẹlẹ, Wọn yoo fagile irinajo iru ẹni bẹẹ, lẹyin to si ti padanu obitibiti owo sọwọ awọn ile iṣẹ onigbajuẹ naa tan.

O tọka sii pe, oun ti kẹẹfin irufẹ iṣẹlẹ bẹẹ ni igba mẹta ọtọọtọ laarin ọsẹ kan, ati wipe awọn oniṣẹ jibiti naa pọ rẹkẹtẹ ni awọn ilu bii Syria, Egypt ati Iraq lasiko Hajj.

Ṣọra fun awọn ile iṣẹ abani sẹ eto irin ajo nigba to ku diẹ ki ọjọ pe

Al-Qurashi wa gbawọn eeyan nimọran lati maa ṣora fun awọn ile iṣẹ abani sẹ eto irin ajo nigba tọjọ ku diẹ ko pe, nipa biwọn ti n gbe iwonba owo perete le irin ajo naa lori pẹlu ṣiṣe ipolonpo rẹ kikan kikan loju itakun ayelujara.

Suleimon sọ fun BBC lati ori ẹrọ ilewọ lasiko towa ni offiisi ajọ to n mojuto irin ajo Haaj ọun, wipe aṣiṣe nla ni oun sẹ nigba ti oun fi ọpọlọpọ owo ransẹ si ile iṣẹ naa lai ṣayẹwo wọn daada.

Suleimon ko sai gba awọn eeyan niyanju lati yago fun owo fifi ranṣẹ si ẹnikẹni tabi ile iṣẹ ile okeere to n bani ṣe eto irin ajo Hajj ti ko ba gbontẹ to munadoko.

Agbeyẹwo eke ati ipolongo aṣini lọna

Suleimon nikan kan kọ lo padanu ọrọ Hajj naa.

Bakan na, Farouk Abdel Wahab oṣiṣẹ eleto ilera kan to n gbe ni ilu UK ṣalaye fun BBC pe, oun ko lero pe, oun ati awọn molẹbi oun lee faragba lọrọ naa, lẹyin igba tiwọn dowopọ pẹlu ile iṣẹ eleto igbafẹ kan nilu ọun.

Farouk,ọmọ bibi ilẹ pakistan salaye fun BBC pe, ija ọlọjọ pipẹ ni oun ba ile iṣẹ naa ja ki wọn ti ṣeleri lati da owo ti ko si nilẹ pada fun oun.

Ẹwẹ, Farouk sọpe owo naa pada bọ si oun lọwọ lẹyin ọpọlọpọ ipolongo, O ni lẹyin ọdun mẹta ni oun ṣẹṣẹ ni anfaani lati lọ si Mecca nigba ti asiko Hajj ko tii to lati fi imu finlẹ nipa ile iṣẹ to lee ba ṣeto irin ajo naa laini wahala ninu rara.

Ori atẹ ile iṣẹ Nusuk

Ọdun 2020 ni Farouk ni iriri naa.

Ori atẹ Nusuk ti ijọba ilẹ Saudi Arabia safihan ni oju ọna to ṣe bofinmu ti iforujọsilẹ ṣiṣe eto irin ajo lo si Hajj iyẹn fun awọn musulumi nilu Europe,US ati Australia nikan.

Nipasẹ Nusuk ọun, awọn arinrin ajo naa yoo tọka si irufẹ eto ti wọn fẹ, pipese gbogbo iwe ti wọn ba beere fun ati bi owo yoo si di sisan lọna to fidi mulẹ.

Ni afikun anfaani wa fun awọn olugbe ilu Saudi Arabia lori atẹ Nusuk lati wa kopa nibi eto Hajj lẹyin ti wọn ba ti seto iforukọsilẹ nipaṣẹ itakun ayelujara ti ile iṣẹ to n risi irin ajo Hajj ati Umrah nilẹ naa.

Bakan na ni awọn ẹlẹsin Islam lati orile ede miran lee kopa leto ọun lẹyin tiwọn ba ti gba iwe irinna nipasẹ awọn ajọ to n mojuto irin ajo Hajj lorilẹ ede koowa wọn.

Ọna lati yago fun awọn onijibiti lori irin ajo Hajj

Ile iṣẹ ọlọpaa ilẹ UK wa gba awọn eeyan nimọran wipe ki wọn maa farabalẹ lati yan ile iṣẹ eleto igbafẹ to ba jẹ ọmọ ẹgbẹ ajọ abani seto irinna tilẹ Britain.

Bakan naa ni awọn orilẹ ede bii Indonesia, Pakistan, Naijiria ati United Arab Emirates ni irun awọn ajọ naa lọdọ wọn.

Ọ gba bẹẹ, ajọ abani ṣeto irin ajo Hajj ni ilẹ UK fi ṣekilo wi pe gbogbo ọrọ adehun to ba wa laarin arinrin ajo ati ile iṣẹ to seto naa lo gbọdọ wa ninu iwe akọsilẹ, yatọ fun adehun afẹnusọ tabi ori ẹrọ ilewọ nikan.

Awọn arigbamu ẹkọ

Awọn ẹkọ ti Farouk ri kọ ni lati maa ṣọra fun gbigbarale awọn agbeyẹwo afara jọ otitọ lori itakun ayelujara.

“Iriri mi ni wi pe, ọpọ awọn ile iṣẹ naa lo maa n san owo gọbọi fun awọn kan lati bawọn kọ awọn ọrọ didun sori itakun ayelujara ki awọn eeyan lee ni igbagbọ ninu wọn.

Farouk salaye wi pe awọn eeyan to pọ loti bọ sinu pampẹ wọn lẹyin ṣiṣe ayederu ipolongo naa loju opo.

Gẹgẹbi iṣiro ti ijọba ilẹ Saudi Arabia ṣe, Wọn fihan pe iye awọn eeyan to rin irin ajo Hajj lọ din diẹ ni milliọnu meji, pẹlu bi ida aadọrun lara wọn ti gun baalu wa sibẹ.

Agbẹnusọ fun ajọ naa sọ fun ile iṣẹ BBC pe ida mẹta ninu awọn to bọ sọwọ awọn gbajuẹ ni wọn lọ kọwe ẹsun lori iṣẹlẹ ọun, ati pe awọn eeyan to fara gba ju ninu ni ọjọ ori wọn ko ju ọdun mejilelogoji sisalẹ.

O tẹsiwaju fikun ọrọ rẹ pe bi wọn ti safihan atẹ ile iṣẹ Nusuk lo ti mu adinku ba iṣọwọ ṣiṣẹ awọn onijibiti naa.

Ile iṣẹ ọun yoo mojuto eto irin ajo Hajj awọn orilẹ ede bii mẹrindinlaadoje, bẹẹ ni wọn wa fun ṣiṣe ayẹwo gbogbo iwe ti awọn eeyan fi forukọsilẹ, ati bi owo irin ajo naa yoo ti di sisan lọkọọkan ejeeji.