You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ẹ̀wọ̀n ń rùn lórí ọmọ Ààrẹ Amẹrika lẹ́yìn tó jẹ̀bi ẹ̀sùn lílo oògùn olóró àti ìbọn lọ́nà àìtọ́
Ile ẹjọ kan nilẹ Amẹrika ti sọ pe ọmọ Aarẹ Joe Biden, iyẹn Hunter Biden, jẹbi ẹsun lilo oogun oloro ati nini ibọn lọwọ lọna ti ko tọ.
Ọmọ Aarẹ naa ti n reti idajọ rẹ bayii lẹyin eto jẹbi ẹsune ti wọn fi kan an.
Ẹwọn ọdun marundinlọgbọn ni ijiya to pọju ti ofin ilẹ Amẹrika gbe kalẹ fun ẹni to ba jẹbi irufẹ ẹsun naa amọ awọn onimọ kan ti sọ pe o ṣeeṣe ki wọn ma ṣe irufẹ idajọ bẹẹ fun ọmọ Aarẹ ọhun.
Ohun ti a mọ nipa ẹjọ naa ati ohun to le ṣẹlẹ lẹyin idajọ Hunter ree.
N jẹ o ṣeeṣe ki Hunter ṣẹwọn?
Ti ile ẹjọ ba dajọ ẹwọn fun ọmoo Aarẹ naa, awọn onimọ ni o ṣeeṣe ki wọn ma fun ni ọdun marundinlogun ti ofin gbe kalẹ fun ẹsin nini ibọn mẹta naa ni ikawọ.
Olukọ imọ ofin kan nile ẹkọ South Texas College of Law Houston, Dru Stevenson sọ pe yoo jẹ ohun iyalẹnu ti Hunter ba ri ẹwọn to to ọdun marun un he.
O ni “Irufẹ ijiya bẹẹ wa fun awọn ọdaran pọnbele tabi awọn ti ajọ ọtẹlẹmuyẹ FBI ti n wa tẹlẹ.”
Ninu ọrọ rẹ, o ni o ṣeeṣe ki ọmọ Aarẹ naa ṣẹwọn, o si ṣeeṣe ko ma ṣẹwọn, amọ to ba maa ṣẹwọn, ẹwọn naa le ma to ọdun meji ti yoo ṣe.
Stevenson ni “O ṣoro lati sọ ohun ti yoo ṣẹlẹ, amọ mo ro pe o le ṣẹwọn.”
Amofin naa fi kun pe wọn le fun Hunter ni ijiya kekere dipo ko dero ẹwọn.
Igba wo ni idajọ Hunter Biden yoo waye?
Ireti wa pe laarin ọsẹ diẹ si asiko yii ni adajọ Maryellen Noreika yoo gbe idajọ rẹ kalẹ.
Amọ ṣaaju idajọ naa, iroyin ni o ṣeeṣe ki wọn ma fi ọmọ Aarẹ ọhun si atimọle.
Ti wọn ba tilẹ ṣedajọ ẹwọn fun gan, ko di dandan ko lọ sẹwọn lọjọ kan naa, o le mu ọjọ ti yoo fa ara rẹ le awọn alakoso ọgba ẹwọn lọwọ funra rẹ.
Amofin kan, Neama Rahmani ti sọ fun BBC pe Hunter Biden lẹtọọ lati pe ẹjọ kotẹmilọrun tako idajọ ti wọn ba ṣe fun laarin ọgbọn ọjọ lẹyin idajọ naa.
Hunter Biden wọ gau ofin lẹyin to lọ ra ibọn kan ninu oṣu Kẹwaa, ọdun 2018, eyii to wa lọwọ rẹ fun ọjọ mọkanla gbako.
Lasiko to ra ibọn ọhun , o ni mimu oogun oloro cocaine jẹ baraku fun oun.