You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo àwọn nǹkan tó yẹ kó o mọ̀ nípa Saulos Chilima, igbákejì ààrẹ Malawi tó jáde láyé lẹ́ni ọdún 51
- Author, Wedaeli Chibelushi
- Role, BBC News
Láti ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn ni Saulos Chilima tó dolóògbé lẹ́ni ọdún mọ́kànléláàdọ́ta ti wà ní ipò igbákejì ààrẹ orílẹ̀ èdè Malawi.
Nínú ọkọ̀ òfurufú tó jẹ́ ti ológun tó já lulẹ̀ ní ẹkùn àríwá orílẹ̀ èdè náà lọ́jọ́ Ajé ni Chilima pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ sí.
Ó ti kọ́kọ́ jẹ́ igbákejì fún Peter Mutharika, ẹni tó mu kúrò lẹ́ka okoòwò ṣíṣe láti wá ṣe igbákejì rẹ̀ nígbà tó díje fún ipò ààrẹ.
Kí ó tó di igbákejì ààrẹ Malawi lọ́dún 2014, òun ni adarí iléeṣẹ́ ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ Airtel Malawi, tó sì jẹ́ àkọ́kọ́ ọmọ orílẹ̀ èdè náà ti yóò jẹ́ olórí ní iléeṣẹ́ náà.
Àmọ́ lẹ́yìn ọdún mẹ́rin tó ti jẹ́ igbákejì Mutharika, òun àti ààrẹ ní èdè àìyedè bí ó ṣe ní ààrẹ kò ṣiṣẹ́ tó láti gbógunti ìwà àjẹbánu àti dídá ààbò bo àwọn aráàlú.
Òfin Malawi kò fàyè gba ààrẹ láti yọ igbákejì rẹ̀ nípò nítorí náà Mutharika kò rí Chilima yọ nípò igbákejì ààrẹ bẹ́ẹ̀ náà sì ni Chilima kọ̀ láti fipò rẹ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú bó ṣe ń bu ẹnu àtẹ́ lu ìṣèjọba náà.
Lẹ́yìn náà ló dá ẹgbẹ́ òṣèlú tirẹ̀ tó pe orúkọ rẹ̀ ní United Transformation Movement (UTM) sílẹ̀ bí ó ṣe ń pè fún àyípadà ọ̀tun ní orílẹ̀ èdè Malawi.
Ó díje sípò ààrẹ lọ́dún 2019 àmọ́ ipò kẹta ló gbé tí Mutharika sì gbégbá orókè níbi ètò ìdìbò náà.
Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní orílẹ̀ èdè náà ní àwọn kùdìẹ̀kudiẹ kan wà nínú ètò ìdìbò náà àti pé Mutharika kọ́ ló jáwé olúborí níbi ètò ìdìbò ọ́hún tó sì pé fún àtúndì ìbò.
Chilima parapọ̀ mọ́ Lazarus Chakwera tó gbé ipò kejì níbi ètò ìdìbò náà láti ṣe igbákejì rẹ̀ níbi àtúndì ìbò lọ́dún 2020 tí wọ́n sì jáwé olúborí.
Lọ́dún 2022 ni òun ní òun bẹ̀rẹ̀ sí ní kojú ẹ̀sùn ìwà àjẹbánu fẹ́sùn wí pé ó ń gba owó ẹ̀yìn lọ́wọ́ àwọn tó bá gbé iṣẹ́ àkànṣe àmọ́ tó jiyàn gbogbo ẹ̀sùn náà.
Ààrẹ Chakwera, nígbà tí lò lè gbaṣẹ́ lọ́wọ́ Chilima, ní òun kò ní fi àkóso iṣẹ́ àkànṣe kankan sí Chilima lọ́wọ́ fún gbogbo ìgbà tó ń kojú ìgbẹ́jọ́ náà.
Ní oṣù tó kọjá ni wọ́n yọ gbogbo ẹ̀sùn tí wan kà sí Chilima láì sọ ìdí rẹ̀ tí wọ́n fi yọ àwọn ẹ̀sùn náà ní èyí tó sì ń fa awuyewuye láàárín àwọn aráàlú.
Kí Chilima tó gba ipò gẹ́gẹ́ bí igbákejì ààrẹ, ó ti ṣiṣẹ́ ní àwọn iléeṣẹ́ ńláńlá bíi Unilever àti Cocacola.
Onímọ̀ nípa ètò ọrọ̀ ajé ni tó sì kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ọ̀mọ̀wé nínú ẹ̀kọ́ ìmọ̀ àkóso.
Yàtọ̀ ipò igbákejì ààrẹ tó dìmú, òun ni mínísítà fún ètò ọrọ̀ ajé àti ẹ̀ka tó ń rí ọ̀rọ̀ aráàlú.
Ní ọjọ́ Kejìlá, oṣù Kejì ọdún 1973 ni wọ́n bi ní ẹkùn Ntcheu ní ààrin gbùngbùn Malawi.
Ìyàwó kan, Mary àtọmọ méjì, Sean àti Elizabeth ló fi sílẹ̀ sáyé.
Igbákejì Ààrẹ ní Malawi àtàwọn èrò míì di òkú nínú bàálù tó di àwátì
Igbakeji Aarẹ lorilẹede Malawi Dokita Saulos Chilima ni wọn kede pe o padanu ẹmi rẹ lasiko ijamba ọkọ baalu.
Akọwe agba fun orilẹede naa, Collen Zamba lo kede iroyin naa ninu atẹjade kan to fi sọwọ sita fun araalu.
O ni gbogbo igbiyanju awọn ẹlẹsọ abo lati ṣawari igbakeji aarẹ naa lo jasi pabo.
Ọkọ baalu naa to gbe igbakeji Aarẹ ati eeyan mẹsan an mii ni wọn ṣawari lowurọ ninu igbo Chikangawa.
Zamba ni gbogbo awọn to wa ninu baalu naa lo padanu ẹmi wọn.
“A ti fi iṣẹlẹ to arẹ orilẹede Malawi, Lazarus Chakwera leti, to si ti ransẹ ibanikẹdun si mọlẹbi igbakeji Aarẹ ati mọlẹbi gbogbo eeyan to padanu ẹmi wọn ninu ijamba naa.”
Aarẹ Ckakwera ti kede ọjọ kan fun idaro, to si palasẹ pe ki wọn fa asia orilẹede naa si idaji
Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe baalu to gbe igbakeji Aarẹ ilẹ Malawi Saulos Chilima ati awọn mẹsan min ti di awati lẹyin to ya bara kuro loju ọna rẹ gẹgẹbi atẹjade lati ọffisi Aarẹ wọn ti wi.
Atẹjade ọun fi kun pe owurọ ana ọjọ aje ni baalu ile isẹ Ologun ti orilẹ ede Malawi gbera kuro ni olu ilu ilẹ naa tiise Lilongwe.
Ọwọ aago mẹwa lo yẹ ki baalu naa balẹ ni papakọ ofurufu Mzuzu towa lapa Ariwa ilẹ naa.
Ninu ọrọ ti Aarẹ ilẹ Malawi, Lazarus Chakwera ba awọn eeyan sọ lalẹ ana lo ti sọ pe wọn ti bẹrẹ sini wa awọn eeyan ọun, bẹẹ ni awọn ikọ adoola ẹmi si ti wa lẹnu isẹ.
Baalu to gbe Igbakeji Aarẹ ọhun poora nigba to n lọ soju ijọba Malawi nibi eto isinku ọkan lara awọn Minisita wọn, Ralph Kasambara to jade laye lọjọ mẹta sẹyin
Iṣẹlẹ ọhun ni wọn sapejuwe gẹgẹbi eyi to buru jai ati wipe awọn osisẹ Ologun ti bọ soju isẹ pẹlu asẹ wipe wọn gbọdọ tẹsiwaju titi digba ti baalu naa yoo fi di riri.
Aarẹ naa sọpe ẹru ba ohun gẹgẹbi ẹru tiwa lọkan kaluku sugbọn wọn koni duro lori sisa akitiyan nipa bi baalu naa yoo ti di wiwari pelu awọn eeyan ti isẹlẹ naa ko ba gba ẹmi won.
Aarẹ Chakwera lo fagile irin ajo oju ofurufu rẹ lọsi ilu Bahamas nirọlẹ ana.
Ọgagun Valentino Phiri sọ fun Aarẹ naa wipe, ko tii sẹni to mọ idi pato ti baalu naa fi di awati, bakan naa ni Minisita eto iroyin ilẹ Malawi Moses Kunkuyu salaye fun BBC wipe igbesẹ to gbona ti n lọ lọwọ lati wa baalu naa lawari.
Igbakeji Aarẹ ọhun lo fẹ lọ soju ijọba ilẹ Malawi nibi eto isinku ọkan lara awọn Minisita wọn, Ralph Kasambara to jade laye lọjọ mẹta sẹyin.
Ogbẹni Kunkuyu tọka si i pe papakọ ofurufu to yẹ ki baalu naa ti balẹ lapa Ariwa ilẹ naa ni ko fi bẹẹ jina si ibi ti eto isinku naa yoo ti waye.
Lọdun 2022, niwọn fi pampẹ ọba gbe igbakeji Aarẹ naa fun ẹsun gbigba owo towa fun isẹ akanse to jẹ ti ijọba, sugbọn tile ẹjọ ju ọwo ọrọ naa silẹ losu to kọja lai fi alaye idi ipinu wọn lede rara.
Ta ni Saulos Chilima jẹ gan?
- Atọkasi nipa eto oselu rẹ, Ọmọwe Chilima di ipo adari to lokimi mu ni awọn ile isẹ to lorukọ bii Unilever and Coca Cola mu.
- Ẹni ọdun Mọkanlelaadota ni.
- Baale ile ọlọmọ meji si ni pẹlu.
- Loju pẹpẹ agbaye ijọba ilẹ naa wọn ti sapejuwe Ọmọwe Chilima gẹgẹbi ẹni to mosẹ rẹ nisẹ,to si jẹ alaṣeyori eeyan.
- O ni iwe ẹri PhD ninu ẹkọ amojuto ọrọ to niisẹ pẹlu Imọ.