Àṣìrì ọgbọ́n tí àwọn ọmọ Nàìjíríà ń lò láti fìyà jẹ àwọn tó ń ní ìbálòpọ̀ akọsákọ àti abosábo tú
Àṣìrì ọgbọ́n tí àwọn ọmọ Nàìjíríà ń lò láti fìyà jẹ àwọn tó ń ní ìbálòpọ̀ akọsákọ àti abosábo tú

Ìbálòpọ̀ láàárín akọsákọ tàbí abosábo jẹ́ ohun tó lòdì sí òfin Nàìjíríà kódà ó ní ìjìyà tó gbópọn lábẹ́ òfin.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pẹ́ ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè ní àgbàyé ló ti ń fọwọ́ sí ìbáṣepọ̀ láàárín akọsákọ tàbí abosábo, ọ̀pọ̀ orílẹ̀ èdè ní ilẹ̀ Adúláwọ̀ ló ṣì korò ojú sí ìwà yìí.
Nínú ìwádìí yìí, BBC ṣàwárí bí àwọn kan ṣe kó ara wọn jọ láti máa fi ìyà jẹ àwọn ènìyàn tí wọ́n bá ti mọ̀ wí pé wọ́n ń hu irú ìwà yìí.
Àwọn tí wọ́n ti lùgbàdì ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ní wọ́n máa lẹ́yìn tí àwọn bá ti jọ ń sọ̀rọ̀ ni wọ́n máa ń lu àwọn tí wọ́n sì máa ń gba owó lọ́wọ́ àwọn láti dènà bíba àwọn lórúkọ jẹ́.







