Anthony Joshua sọ̀rọ̀ lórí ìjàmbá ọkọ̀ tó gbẹ̀mí ọ̀rẹ̀ rẹ̀ méjì, Ó ní 'Ọkàn mi gbọgbẹ́'

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gbajugbaja abẹṣẹkubiojo Anthony Joshua ti sọrọ fun igba akọkọ lori ijamba ọkọ to ṣẹlẹ lopopona marosẹ ilu Eko si Ibadan nibi ti ọrẹ rẹ meji ti padanu ẹmi wọn.

Joshua kẹdun awọn ọrẹ rẹ meji, Latif Ayodele ti inagijẹ rẹ n jẹ Latz ati Gami Sina, o ni awọn mejeeji dabi ọmọ iya oun.

Nigba to n sọrọ ninu fidio kan to fi lede loju opo Facebook rẹ, Joshua dupẹ lọwọ gbogbo awọn ololufẹ rẹ ati gbogbo eeyan fun ifẹ ati atilẹyin wọn lori iku Latz ati Sina.

Ilumọọka akẹṣẹ naa farapa ninu ijamba to ṣẹlẹ lọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Kejila ọdun 2025.

Joshua ni ijamba ọhun ṣẹlẹ lojiji lẹyin toun atawọn ọrẹ oun mejeeji ti pinnu nnkan tawọn jọ fẹ ṣe papọ ni ipari ọdun to kọja.

''Emi atawọn ọrẹ mi ti ṣe alakalẹ oriṣiiriṣii nnkan ti a fẹ ṣe ni ipari ọdun 2025.

A rinrin a jo lọ sile lati lọ ri awọn ẹbi wa, amọ, gbogbo eto naa daru lojiji pẹlu ijamba to ṣẹlẹ.

Awọn obi, mọlẹbi, awọn ọrẹ to fi mọ emi gan an ko kan padanu Latz ati Sina lasan, a tun padanu awọn eeyan ti a fẹran.

O ni ipa tawọn mejeeji yii n ko ninu igbesi aye wa.

Lakọkọọ, ọrẹ ni wa ki a to di alabaṣiṣẹpọ, a jọ maa n ṣe ọpọlọpọ nnkan papọ.

Mo ṣetan lati ṣe atilẹyin fun ẹbi Latz ati Sina - Anthony Joshua

Mo ṣetan lati ṣe atilẹyin fun ẹbi awọn mejeeji tori mo mọ nipa nnkan ti wọn fẹ ṣe fun ẹbi wọn.

Ojuṣe mi ni lati ṣe nnkan ti wọn ni lọkan lati ṣe fun ẹbi wọn, bo tilẹ jẹ pe a o le foju ri wọn mọ.

Ohun ti o yẹ lati ṣe fun mi ni eleyii ati oun to tọ fawọn idile wọn,'' Joshua lo sọ bẹẹ.

Gbajugbaja abẹṣẹkubiojo naa tun dupẹ lọwọ awọn eeyan to kọkọ debi ti ijamba ọkọ naa ti ṣẹlẹ.

Bakan naa ni o tun dupẹ lọwọ awọn to gbe Latz ati Sina ati oun naa lọ si ile iwosan lẹyin ti ijamba naa ṣẹlẹ tan.

Joshua ko ṣai dupẹ lọwọ gbogbo awọn araalu ti wọn gbadura foun lori ijamba to ṣẹlẹ.

Anthony Joshua ko gbagbe lati dupẹ lọwọ awọn dokita to tọju rẹ nile iwosan ti wọn gbe e lọ.

Bakan naa lo tun dupẹ lọwọ aṣoju olu ileeṣẹ ijọba ilẹ Gẹẹsi ni Naijiria, SimonField, gbajugbaja oniṣowo Aliko Dangote ati Femi Otedola fun atilẹyin wọn.

Abẹṣẹkubiojo naa tun dupẹ lọwọ Gomina Dapo Abiodun ipinlẹ Ogun, Babajide Sanwo-Olu ipinlẹ Eko atawọn ẹṣọ eleto aabo fun ipa ribiribi ti gbogbo wọn ko lori nnkan to ṣẹlẹ.

Ẹwẹ, Ọgbẹni Adeniyi Kayode to jẹ awakọ Anthony Joshua ti foju bale ẹjọ niluu Sagamu lori oniruuru ẹsun to fi mọ iwa aibikita loju popo.

Adajọ majisireeti Olajumoke Somefu ti sun igbẹjọ siwaju si ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu Keji ọdun yii.