‎Mi ò lè gbà kí ìyà jẹ ọkọ mi rara, ìdí nìyí tí mo fi ń wà lẹ́yìn rẹ̀ nígbà gbogbo - Oluremi Tinubu, ìyàwó ààrẹ Nàìjíríà

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Aya Aarẹ orilẹede Naijiria, Oluremi Tinubu, ti sọ pe itọju ọkọ oun ati itọju ile lo jẹ oun logun julo.

Arabinrin Oluremi sọrọ yii lasiko to sabẹwo si ọgba ile ẹkọ Fasiti Ọbafemi Awolowo to wa ni ilu Ile-Ife nibi to ti fun ile ẹkọ Fasiti naa lẹbun ọkọ.‎

‎Lakoko ti o n ba awọn akẹkọọ ati gbogbo awọn to peju sibi eto naa sọrọ, Oluremi sọ pe iṣẹ olukọ ni oun fi bẹrẹ irinajo oun, ati pe oun fẹran lati maa ṣe itọju awọn akẹkọọ paapa ile ẹkọ ti oun ba ti kẹkọọ gboye.

‎''Mi o le fara mọ ki iya ko jẹ ọkọ mi rara, nitori naa ni mo ṣe maa n wa lẹyin ọkọ mi nigba gbogbo.

Mo maa n ṣe eleyii lati le ma jẹ ki ẹgbin tabi iya kankan ko jẹ ọkọ mi.

‎Mi o lero pe mo le di aya aarẹ orilẹ-ede Naijiria rara,'' Aya Aarẹ lo sọ bẹẹ.

Oluremi Tinubu wa rọ gbogbo awọn akẹkọọ lati ma sọ iran wọn nu ati lati ni afojusun pẹlu ifarada ni gbogbo ọna wọn.

‎Ninu ọrọ tiẹ, Ọba Adeyeye Ogunwusi Ẹnitan Ọọni ti Ile-Ifẹ ni ''ẹmi ko ri iyawo Aarẹ orile-ede Naijiria, Oluremi Tinubu, bi aya Ààrẹ, ṣugbọn mo ri i gẹgẹ bi iya.

Lati igba ti mo ti wa ni ile ẹkọ giga ni mo ti maa n gbọ orukọ iyawo Aarẹ ni daadaa, ti mo si maa n gba adura lati pade wọn.

‎Lati igba ti mo si ti mọ aya Aare Oluremi, mi o tii kabamọ pe mo mọ wọn nitori wọn maa n ṣe bi iya fun mi ni gbogbo igba ti mo ba ti nilo iranlọwọ wọn.

‎Oba Ogunwusi wa rọ gbogbo awọn oludari atawọn akẹkọọ Fasiti Ọbafemi Awolowo lati mọ riri oun ti aya Aarẹ ṣe fun wọn, ki wọn si moju to o daadaa.