Ohun tí a mọ̀ nípa ìbúgbàmù àti ìró ìbọn tó dún ní pápákọ̀ òfúrufú Niger

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Iro ibọn ati ibugbamu ti dun lakọlakọ lagbegbe papakọ ofurufuilu Naimey, lorilẹde Niger.

Awọn oṣojumikoro atawọn fidio lati ibẹ ṣafihan bi awọn ohun ija to n koju ado oloro lati oju ofurufu ṣe n siṣẹ.

Awọn alaṣẹ ti sọ pe ko si wahala mọ bayii amọ wọn ko sọrọ pupọ nipa ohun to ṣẹlẹ ni pato.

O ṣoro lati sọ ohun to ṣokunfa ibugbamu naa tabi boya ẹnikẹni farapa nibẹ.

Titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ, ileeṣẹ ọmọ ogun orilẹede baa ko sọ nnkankan nipa iṣẹlẹ naa.

Awọn to n gbe lagbegbe ti papakọ ofurufu Diori Hamani International Airport wa sọ pe nnkan bii aago mejila oru lawọn gbọ iro ibọn ati ibugbamu naa.

Olugbe agbegbe naa kan tilẹ sọ fun BBC pe oun ri ti awọn kan n yinbọn lati papakọ naa si awọn baalu to n fo.

Awọn mii to n gbe nibẹ juwe iṣẹlẹ ọhun bii eyii to da ibẹrubojo si ọkan awọn.

Ọkan lara awọn olugbẹ naa to jẹ obinrin sọ pe "A ko ri oorun sun lalẹ ana, niṣe ni inu yara ati gbogbo ile wa n mi titi nitori ibọn ati ibugbamu naa."

Obinrin mii to ba awọn akọroyin sọrọ sọ pe "ana ni igba akọkọ ti mo maa kọkọ gbọ iro ibọn."

Awọn iroyin kan ti a ko le fidi rẹ mulẹ sọ pe awọn eeyan kan ju ado oloro sinu papakọ ofurufu naa lẹyin wọn ti kọkọ kọju ija si awọn ẹṣọ to wa nibẹ.

Ileṣẹ to n ṣọ irinnajo ọkọ ofurufu, FlightRadar24 jabọ pe pupọ awọn baalu to yẹ ko kuro ni papakọ ofurufu naa ni wọn ti dari si awọn ibomii.

Nigba ti yoo di afẹmọju Ọjọbọ, obtitibiti awọn ẹṣọ alaabo lo dari si papakọ ofurufu naa gẹgẹ bii ileeṣẹ iroyin AFP ṣe jabọ.

Abdourahamane Tiani, to ditẹgbajọba lọdun 2023 lo n tukọ Niger lẹyin to le Aarẹ ti ilu dibo yan kuro nibẹ.

Gẹgẹ bii awọn orilẹede to fẹgẹkẹgbẹ rẹ, Burkina Faso and Mali, Niger n koju iṣoro awọn alakakiti ẹsin Islam to n ṣe ikọlu lemọlemọ.

Laarọ Ọjọbọ lawọn ololufẹ ijọba ologun naa ṣe iwọde lati ṣatilẹyin fun un.

Ohun alumọni uranium ni orilẹede naa fi n ṣọrọ.