You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
NAFDAC ṣàlàyé ìdí tí wọ́n fi fòfin de pẹlẹbẹ, fònàgáú àtàwọn ọ̀tí inú ọ̀rá míràn ní Naijiria
Ajọ to n se amojuto ounjẹ ati ogun lorilẹede Naijiria, NAFDAC ti jẹ ko di mimọ pe awọn ko figba kankan kede pe ki awọn araalu ma pese ọti inu ọra pada, ti wọn si tun ṣalaye idi pato ti wọn fi fofin de tita ọti inu ọra naa.
NAFDAC ni awọn ko sọ pe ki awọn to n pọn ọti maa gbe ọti sita ṣugbọn opin ti de ba ọti inu ọra lorilẹede Naijiria.
Ninu atẹjade ti ọga agba NAFDAC buwọlu sita fun awọn akọroyin, Ọjọgbọn Mojisola Christianah Adeyeye ni awọn gbe igbesẹ lati da aabo bo awọn ọmọde ati ọdọ lọwọ minu awọn ọti to le pani lara yii.
"NAFDAC ti pada si ofin to tako tita ọti inu ọra lorilẹede Naijiria pẹlu ajọsepọ ile igbimọ aṣofin orilẹede Naijiria."
Gẹgẹ bii atẹjade naa ṣe ṣalaye, bi ọti inu ọra se wa kaakiri, to si wa fun owo perete jẹ ko rọnu fun awọn ọdọ lati ni anfani si ọti mimu, to si n ṣe ọpọ akoba fun ọjọ ọla.
Adeyeye ni bi awọn kọ 'Ko ki n se fun ọmọde' si ara ọti inu ọra ko se nkankan to yẹ ko ṣe rara, ko si tun wulo.
"Ọpọ obi ni ko mọ pe awọn ọmọ n mu ọti inu ọra yii nitori o kere lọwọ, owo rẹ ko si ọpọ, to si tun wa kaakiri," o ṣalaye.
O fikun pe ọpọ iwadii lati awọn ile ẹkọ lo n kọ oun lominu, ti olukọ kan si sọ pe akẹkọọ kan ko le jokoo fun idanwo lai mu ọti inu ọra.
Ọdun 2025, ile igbimọ aṣofin ti paṣẹ fun ajọ to n ri si oogun ati ounjẹ ni Naijiria, NAFDAC, atawọn ajọ mii lati ri daju pe ẹnikẹni ko ta ọti inu ọra ni Naijiria mọ bẹrẹ lati inu oṣu Kejila ọdun 2025.
Awọn aṣofin naa tun fẹnuko pe wọn ko ni fun awọn to n ta ọta ni aye mii lẹyin aṣẹ ti wọn pa yii.
Igbesẹ yii lo waye lẹyin ti aṣofin Asuquo Ekpeyong ni ijọba ko gbọdọ fun awọn to n ta ọti inu ọra naa laye mii mọ lati ko kuro nilẹ.
Iwọnyin lawọn igba ti ijọba ti gbẹsẹle ọti inu ọra ni Naijiria
Oṣu kejila ọdun 2018 - Ọdun naa ni igba akọkọ ti ijọba atawọn oniruru ajọ buwọlu adehun latin fopin si pipo ọti ninu ọra, paapaa awọn ọti ti iwọn rẹ ko ju 200ml.
Ọjọ kinni, oṣu Keji, ọdun 2024 – NAFDAC bẹrẹ si n ko awọn ọti naa lori igba lati le mu aṣẹ iwe adehun naa ṣe.
Oṣu keji si oṣu Kẹfa ọdun 2024 – Ile igbimọ aṣofin da si ọrọ naa wọn si rọ NAFDAC lati dawọ kiko rẹ kuro lori igba duro latari awọn ti yoo padanu owo ati iṣẹ wọn, paapaa ipa ti igbesẹ naa yoo ni lori ọrọ aje araalu to n ta a.
Oṣu Karun un, ọdun 2024 – NAFDAC gbẹsẹ kuro lori aṣẹ naa fun igba diẹ titi di ipari ọdun 2025 ki wọn le ṣe ipade pẹlu gbogbo awọn ti rọrọ naa kan.
Oṣu Kọkanla, ọdun 2025 – ile igbimọ aṣofin kan an nipa fun NAFDAC ko bẹrẹ aṣẹ naa ko si gbẹsẹle ọti inu ọra ni Naijiria lai fun awọn to n po o atawọn to n ta a n afikun gbendeke mii mọ.