You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Taa ni Stanley Amandi, òṣèré tíátà tí ìjọba mú lórí ẹ̀sùn pé ó wà lára àwọn tó fẹ́ dìtẹ̀gbàjọba lọ́wọ́ Tinubu?
Iroyin to gba igboro kan bayii ni pe ijọba apapọ ti fi ṣikun ofin mu gbajugbaja olootu fiimu, Stanley Amandi, ti ọpọ awọn oolufẹ rẹ mọ si Stan K.
Wọn mu ọkunrin naa lori ẹsun pe o wa lara awọn to n ṣagbatẹru igbesẹ lati fi ipa gbajọba lọwọ Aarẹ Bola Tinubu.
Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, inu oṣu Kẹsan an, ọdun 2025 ni ọwọ tẹ ọkunrin naa to ti fi akoko igba kan ri jẹ alaga ẹgbẹ awọn oṣere, Actors Guild of Nigeria, AGN.
Ẹnikan to sunmọ afurasi naa amọ ti ko fẹ ki a darukọ oun ni lootọ ni wọn fi ṣikun ofin gbe niluu Enugu.
O ni awọn kọkọ ro pe ọọfisi ajọ ọtẹmuyẹ DSS lo wa tẹlẹ ti ẹgbẹ Actors Guild of Nigeria si n ba DSS sorọ lati fun laaye pe ki iyawo rẹ le yọju si.
A tun gbọ pe ajọ DSS fi iwe kan ranṣẹ si AGN lọsẹ to kọja pe ko si lakata awọn amọ ọdọ ahamọ ajọ Defense Intelligence Agency (DIA) lo wa.
Amọ ẹgbẹ naa ti bẹrẹ igbesẹ bayii lati le jẹ ki iyawo, dokita ati agbẹjọro rẹ ri latari pe o n ba aisan ẹjẹ riru finra.
Ninu ifọwerọ pẹlu BBC, alaga ẹgbẹ AGN, Abubakar Yakubu sọ pe iṣẹ tiata kan ni ọkunrin naa n ṣe lọwọ ni Enugu ki wọn to fi kele ofin gbe.
Taa ni Stan K Amadi?
Oṣere tiata ati oludari ere ni afurasi naa ti wọn bi lọjọ kẹfa, oṣu Kẹwaa, lọpọ ọdun sẹyin.
Ọmọ ẹya Igbo lati ipinlẹ Enugu ni ọkinrun naa, ẹsin ọmọlẹyin Kristi lo si n ṣe.
Lara awọn agba oṣere to ti ba ṣiṣẹ ni Nkem Owoh, Ngozi Ezeanu, Ruth Kadiri, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
O ni iyawo, o si ni awọn ọmọ.
Lara awọn ere to ti kopa ni Issakaba, Igodo, No shaking, The barrister, Another bondage, Heaven after hell, Torn Apart, Lionheart, Official Fracas ati ọpọ ere mii.