You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
A ti ṣetán láti yan àwọn aṣòfin – Ìjọba ológun orílẹ̀-ede Gabon
Aarẹ ologun lorilẹ-ede Gabon, Ọgagun Brice Oligiu Nguema ti sọ pe oun yoo yan igbimọ alakoso ati awọn aṣofin laipẹ.
O ni eyi yoo jẹ ki wọn maa jokoo papọ lati jiroro lori idagbasoke orilẹ-ede naa.
Nguema lo sọrọ naa laipẹ yii loju opo ikanni X rẹ lẹyin ipade to ṣe pẹlu Aarẹ Faustin-Archange Touadéra.
Nguema ati Aarẹ Touadéra pade ni Central African Republic l’Ọjọru ọsẹ yii, nibi ti ọrọ naa ti jade.
Bi o tilẹ jẹ pe Ọgagun Nguema ko tii sọ patọ ọjọ ti yoo yan awọn alẹnulọrọ ati awọn aṣofin naa, ṣugbọn ikede naa lo waye latari awuyewuye to ti n lọ nipa awọn aadọrin ti yoo maa jokoo nile igbimọ aṣoju-ṣofin ati awọn aadọta mii ti yoo maa jokoo nile igbimọ aṣofin agba.
Ninu oṣu Kẹsan an to kọja yii ni Ọgagun Oligui Nguema yan awọn olori l’awọn ile igbimọ aṣofin wọnyi ti wọn yoo si ṣakoso titi d’igba ti wọn yoo yan awọn ti wọn yoo jọ maa jokoo.
Ipade ti Nguema ṣe pẹlu Aarẹ CAR lo waye lẹyin to ti kọkọ lọ ba awọn Aarẹ Equitorial Guinea ati Congo Brazzaville ṣe ipade, nibi to ti lọ bẹbẹ fun ifọwọsowọpọ ati atilẹyin wọn.