Wo ǹkan méje tó yẹ kí o mọ̀ nípa Primeboy, ọ̀rẹ́ Mohbad tó wà ní àhámọ́ ọlọ́pàá

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko kede l'Ọjọru pe awọn n wa Owodunni Ibrahim ti ọpọ mọ si Primeboy lẹyin to kọ lati yọju fun ifọrọwanilẹnuwo lori iku ọdọmọde olorin, Ilerioluwa Aloba, Mohbad.

Primeboy ti ọpọ mi ni ọrẹ timọtimọ Mohbad ni kọmiṣọnna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Idowu Owohuwa ninu atẹjade ti SP Benhamin Hundeyin fi sita sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa yoo fun ẹnikẹni ti ba ri i ni miliọnu kan naira.

Wọnyii ni koko meje to yẹ ki o mọ nipa Primeboy tawọn ọlọpaa ni ko wa sọ tẹnu rẹ lori iku Mohbad.

i. Ohun akọkọ nipa Primeboy ni pe ọrẹ timọtimọ lati kekere ni Mohbad ati Primeboy jẹ.

Koda, wọn jọ ṣe kekere, wọn si jọ dagba ni Ikorodu nipinlẹ Eko ni.

ii. Labẹ ileeṣẹ agborin jade Dreams Ng. music label ni Primeboy wa.

iii. Primeboy naa ti ṣe awọn orin kan fun ra rẹ.

Lara awọn orin ti o ti ṣe ni awọn orin pẹlu akọle Balance, Omo Ologo ati Dey Play.

iv. O kọ orin pẹlu olorin mii to n jẹ Seyi Vibes.

Bakan naa lo tun kọrin papọ pẹlu Mohbad gan ẹni to maa n saaba kopa ninu fidio ori rẹ.

v. Primeboy n gbiyanju lati darapọ mọ ileeṣẹ agborin jade Zlatan’s Zanku ki Mohbad to jade laye.

vi. Primeboy wa lara awọn eeyan to wa ninu fidio to ṣe afihan oku Mohbad.

Fidio naa si tan kaakiri ori ayelujara ti ọpọ eeyan si ti pin in kiri.

vii. Primeboy fun ra sọrọ lori ayelujara laipẹ yii pe oun ko mọ nkan kan lori iku Mohbad.

Ileeṣẹ ọlọpaa sọrọ lori esi ayẹwo oku Mohbad ti ko tii jade

Ẹwẹ, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Olumiyiwa Adejobi ti ṣalaye pe kii ṣe iṣẹ awọn ọlọpaa lati ṣe ayẹwo oku Mohbad.

Ọgbẹni Adejobi ni awọn onimọ nipa eto ilera lo n ṣiṣẹ naa.

O fikun ọrọ rẹ pe oun ni igbagbọ wi pe ileeṣẹ ọlọpaa yoo sọrọ lori ayẹwo oku Mohbad nigba to ba ya.

Mo fẹ́ fa ara mi kalẹ fún ọlọ́pàá tẹ́lẹ̀, àwọn èèyàn kan ló ní kí n dúró kí wọn fi ránṣẹ́ pè mí - Primeboy

Ibrahim Owodunni, tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ sí Primeboy, tí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá kéde pé òun ń wá, ti fojú hàn síta.

Primeboy, tíí ṣe ọrẹ timọ-timọ pẹlu olóògbé Ilerioluwa Aloba, ti ọpọ eeyan mọ sì Mohbad, ní àwọn èèyàn kan fura si pe o mọ nípa ikú akọrin takasufe naa.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá sì lo kéde fún aráyé pé òun ti gbiyanju ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà láti ké sí Primeboy pé kò yọjú sì àwọn àmọ́ tó faake kọri láti yọjú.

Ìdí sì rèé tí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá fi kéde síta ni Ọjọ́rùú pé òun yóò fún ẹnikẹ́ni tí bá mọ ibi tí Primeboy wá ní ẹ̀bùn owó mílíọ́nù kan Naira.

Àmọ́ ni owurọ ọjọ́ kejì tí ìkéde náà waye, tíí ṣe Ọjọbọ, Primeboy fojú hàn síta pé òun ti ṣetán láti lọ fa ara òun kalẹ fún iléeṣẹ́ ọlọ́pàá tó kéde pé òun ń wá òun.

"Irọ nla ni pé àwọn ọlọ́pàá ránṣẹ́ pé mí ni aimọye igba amọ ti n ko jẹ́ wọn"

Primeboy ṣàlàyé ẹnu tiẹ̀ nínú fídíò ifọrọwanilẹnuwo kan tí iléeṣẹ́ ìròyìn TVC ṣe fún kò tó di pé ó fa ara rẹ silẹ fún ọlọ́pàá.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo náà, Primeboy ni irọ nla ni pé àwọn ọlọ́pàá ránṣẹ́ pé òun, òun kò sì jẹ wọn.

O ni lati igba ti ìṣẹ̀lẹ̀ ikú ọrẹ òun, Mohbad tí wáyé, ní òun ti fẹ gbéra láti yọjú iléeṣẹ́ ọlọ́pàá fúnra òun.

"Irọ ńlá ni pé àwọn ọlọ́pàá pe mi, àmọ́ ń ko dáhùn.

Báwo ni máa ṣe gba iwe ìpè àwọn ọlọ́pàá, tí ń kọ ní jẹ wọn.

Kódà, kí wọn tó ní àwọn n wa mi gan ni mo ti fẹ yọjú sí wọn láti lọ ṣàlàyé ẹnu mi nítorí ṣe ni àwọn èèyàn ń fi ẹ̀sùn kàn mí lọ́nà aitọ pé mo mọ nípa ikú Mohbad.

Àmọ́ àwọn èèyàn kan ló gbà mí nímọ̀ràn pé kí n ṣe sùúrù ná, kí n máa tí yọjú sáwọn ọlọ́pàá àmọ́ kí n dúró na, káwọn ọlọ́pàá fúnra wọn ránṣẹ́ pè mí.

Mo wa dúró títí, n kò gbọ ìpè ọlọ́pàá àmọ́ lójijì, mo kan bá ara mi lórí ayélujára pé àwọn ọlọ́pàá ń wá mi.

Onírúurú awọn èèyàn sì lo ń pe mi pé àwọn ọlọ́pàá tí kéde ẹ̀bùn owó mílíọ́nù kan Naira lórí mi, láti fún ẹnikẹ́ni tó wà mọ ibi tí mo wà."

Primeboy ni ṣe ni ẹnu ya òun lórí ìkéde yìí, tí jìnnìjìnnì sì dá bo òun, tí òun sì ké sí agbẹjoro òun nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

" Àwọn ẹbí àti Agbẹjoro mi ni kí n fara balẹ pe kò sí ohunkóhun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí mi, niwon igba ti n ko mọ ohunkóhun nípa ìṣẹ̀lẹ̀ ikú Mohbad.

Mo sì ti dé ibi yìí báyìí láti dá ara mi silẹ fáwọn ọlọ́pàá."

"Èmi ni mo dúró bíi ìyá fún Mohbad nígbà kéreké, màmá mi ló máa ń fún àwa méjèèjì ní oúnjẹ"

Primeboy ṣàlàyé pé ọrẹ àti ìgbà kékeré òun ni Mohbad jẹ, àwọn sì di jọ dàgbà ni àdúgbò kan naa ni.

" Gbogbo ìgbà tí kò rí ìyá rẹ, tí ìyàwó ìyá rẹ sì ń fòòró ẹ̀mí rẹ, emi ni mo dúró bíi ìyá fún Mohbad nigba naa, èmi nìkan ló ri.

Mama mi lọ máa ń fún àwa méjèèjì ní oúnjẹ papọ nígbà náà, a sì fẹran ara wa gidigidi."

Primeboy ni òun kò wà pẹlu Mohbad lọ́jọ́ to kú yìí, tori lẹ́yìn tó pari ere to lọ ṣe, ó ti oun bọ silẹ nínú mọto ni.

" Ó pe mi lórí aago lọ́jọ́ Ẹtì pé kí n wá sí Lagos Island, n kò tiẹ̀ mọ pe o ni agbo ijo kan tó ti fẹ lọ kọrin.

Nígbà tí mo dé ibẹ, a ń ṣeré lọ sọ fún mi pé òun ni ère tòun fẹ lọ ṣe, tó sì ni ka dijọ lọ sibẹ."

"Mo fẹ kawọn ọlọpaa mu iyawo Mohbad daadaa tori ko ye mi idi to se n ya aworan mi"

Primeboy tun salaye idi ti Mohbad se ni ki oun sọkalẹ ninu mọto rẹ lai se ti ija.

Òun àti ìyàwó rẹ ń sọ̀rọ̀ àṣírí kan lọwọ, lo ṣe ni kí n sọ kalẹ nínú ọkọ ayọkẹlẹ rẹ"

Primeboy wá ń taraporo pe o ya mi lẹ́nu pé ọpọ eeyan ti ko mọ bí mo ṣe jẹ́ sì Mohbad lọ wà ń fi ẹ̀sùn kan mi pé mo mọ nípa ikú rẹ̀.

" Mo fẹ́ kí wọn ṣe àwárí ikú to pa Mohbad, kí awọn ọlọ́pàá sì mú ìyàwó rẹ dáadáa nítorí kò yẹ òun ìdí tó ṣe ń yà àwòrán òun lọ́jọ́ náà."

Primeboy wa kasẹ ọrọ rẹ nilẹ pe oun to pamọ loju eniyan, kedere lo han si Ọlọrun Ọba.

Primeboy tí ọlọ́pàá ń wá lórí ikú Mohbad ti jọ̀wọ́ ara rẹ́ f’ọ́lọ́pàá

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko ti kede pe Owodunni Ibrahim Oluwatosin ti ọpọ mọ si Prime boy ti jọwọ ara rẹ silẹ fun ọlọpaa.

Ileeṣẹ ọlọpaa kede pe awọn n wa Prime boy lọjọru lori ọrọ iku akọrin takasufe ni, Mohbad ti wọn n ṣe iwadi lọwọ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin ṣalaye loju opo ayelujara X rẹ pe ni kete ti o jọwọ ara rẹ ni “wọn fi si ahamọ fun ifọrọwanilẹnuwo ati awọn igbesẹ miran to yẹ.”