You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Portable gba ìtúsílẹ̀ ní àhámọ́ ọlọ́pàá, ó fi ọ̀rọ̀ síta
Gbajugbaja olorin takasufe, Habib Okikiola, ẹni ti ọpọ mọ si Portable ti kuro ni ahamọ ileeṣẹ ọlọpaa gba beeli rẹ.
Bẹẹ ba gbagbe, Portable ni ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa tẹ lẹyin to fo ẹnu abawọle ile kana lati saa mọ ọlọpaa lọwọ.
Fọnran mii to lu ori ayelujara ṣafihan bi awọn ọlọpaa ṣe n wọ Portable nilẹ lati gbe sinu ọkọ ayọkẹlẹ ti wọn gbe wa, ti wọn si fi sẹkẹsẹkẹ si lọwọ.
Agbẹnusọ Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Benjamin Hudenyin ti wa fidi iroyin naa mulẹ, to si oun ko le sọ boya Portable ti san owo to jẹ fun awọn to ra ọkọ ayọkẹlẹ G-wagon lọwọ wọn sugbọn Portable ti kuro ni ahamọ ọlọpaa.
Portable sun ahamọ ọlọpaa ni Ọjọ Isẹgun mọju nitori o kun lati pese oniduro ti yoo mu gba beeli.
Ohun ti a ko le fidi rẹ mulẹ ni boya Portable ti san owo to ku fun awọn to ra ọkọ ayọkẹlẹ G-wagon lọwọ wọn.
Portable sọrọ lẹyin to kuro ni ahamọ ọlọpaa
Habib Okikiola, ti ọpọ mọ si Portable ti fọhun sita lẹyin to kuro ni ahamọ ọlọpaa.
O ni gbagbọ pe Ọlọrun ju gbogbo nnkan lọ, to si ni ki awọn ololufẹ sọ amin ti wọn ba gbagbọ.
Ko ki n ṣe igba akọkọ ree ti Portable yoo wọ wahala pẹlu Ileeṣẹ ọlọpaa.
Ni ọdun to kọja ni Portable dero ile ẹjọ lẹyin to ba awọn ọlọpaa wọ wahale ni agbegbe Sango Ota.
Ẹsun mẹfa ni wọn fi kan Portable, ti wọn si wọ lọ ile ẹjọ nipinlẹ Ogun
Lara awọn ẹsun ni pe o lu ọkunrin kan ni agbegbe Otta ti ẹni naa si fi ẹsun kan an lọdọ Kọmisọna ọlọpaa ipinlẹ̀ Ogun.
Báwo ló ṣe yẹ kí afurasí kan hùwà lásìkò tí Ọlọ́pàá bá fẹ́ mú u?
Ọpọlọpọ igba ni ileeṣẹ ọlọpaa ti fẹ mu gbajugbaja olori takasufe, Habib Okikiola, ẹni ti ọpọ mọ si Portable, to si jẹ pe o ma n fẹ kọju oro si wọn ni.
Nigba akọkọ ti ọlọpaa fẹ́ mu Portable tori bo se fiya jẹ ọmọsẹ rẹ kan, se ni akọrin takansufe naa n pariwo le awọn ọlọpaa naa lori.
"Ọbọ ni mi, inu ọgba ẹranko ni mo n gbe" ni ariwo ti Portable mu bọ ẹnu.
Ni ọjọ isẹgun ti wọn tun fẹ mu tori pe ko san owo mọto to ra tan, se ni Were Olorin naa fo ògiri, to si fẹ sa mọ awọn ọlọpaa lọwọ.
Ko si jẹ ohun iyalẹnu pe ọpọ awọn eeyan lo ma n fẹ salọ nigba ti ileeṣẹ ọlọpaa ba fẹ mu wọn pe wọn furasi pe wọn lọwọ ninu iwa ọdaran.
N jẹ iwọ mọ pe sisa fun ọlọpaa to wa mu ọ lodi sofin, to si le sọ eeyan sọgba ẹwọn?
Eyi lo jẹ ki BBC Yoruba kan si awọn agbofinro ati agbẹjọrọ lati ṣalaye ohun ti ofin sọ nipa titako igbesẹ ọlọpaa lati mu ni bii afurasi.
Ki lo yẹ ko ṣe ti ọlọpaa ba fẹ mu ẹ lọ si agọ wọn?
Ileeṣẹ BBC Yoruba kan si agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ogun, Ọmọlola Odutola ati Agbẹjọro agba Adesina Ogunlana lati pese idahun si ibeere naa
Ninu alaye rẹ, Omolola Odutola ni ẹnikẹni ti Ọlọpaa ba lọ ka mọle pe ko tẹle wọn ni a le ṣapejuwe gẹgẹ bii afurasi, to si le ṣe iranlọwọ fun ọlọpaa ninu iwadii wọn.
O fikun pe ti awọn afurasi yii ba saa fun ọlọpaa, o tumọ si pe irufẹ eeyan bẹẹ jẹbi ẹsun ti wọn furasi pe o mọ nipa, ti wọn si lẹtọ lati wọ lọ si ile ẹjọ.
Sisa fun ọlọpaa lọtọ jẹ ẹsẹ to lodi sofin orilẹede Naijiria.
“Ọrẹ araalu ni ọlọpaa jẹ, ti a si n ṣe iṣẹ wa lati pe abo fun awọn araalu, ti a si tun wa awọn ọdaran.
“Gbogbo eeyan lo jẹ oni mimọ titi ile ẹjọ ba yi pada pe o jẹ bi ẹsun kan tabi omiran.
“Ti ọlọpaa ba fẹ mu eeyan, ko nilo lati ma saare kiri, to ba fi le sare, o n sọ fun wa pe o ju ofin lọ.
“ O n sọ fun wa pe o ti ṣe nnkan ti a furasi pe o ṣe tabi o mọ nipa. Iwadii ti ọlọpaa n ṣe ko tumọ si pe o jẹbi ẹsun ti wọn furasi pe o ṣe.
“Gbiyanju wọn nipa mọ si nipa iwadii wa, to ba fi le saa, o tumọ si pe mọ nipa rẹ.”
Odutola gba awọn araalu ni imọran pe o ṣe koko fun wọn lati tẹle ọlọpaa lasiko ti wọn ba wa mu pe wọn ẹjọ lati rọ sugbọn eyi ku tumọ si pe ọdaran niwọn.
Ki ni ofin sọ nipa sisa fun ọlọpaa?
Agbẹjọro agba, Adesina Ogunlana ni otitọ ni pe Ileeṣẹ ọlọpaa ni ẹtọ ati agbara labẹ ofin lati mu ẹnikẹni ti a le pe ni afurasi lorilẹede Naijiria.
O ni awọn ọlọpaa ma mu eeyan lati gbọ ọrọ lẹnu rẹ ti yoo wulo fun iwadii wọn sugbọn o ni awọn ọlọpaa le agbara yii ti wọn ba igbagbọ pe ẹni ni tọtọ jẹ afurasi.
Ogunlana ni ọpọlọpọ ni awọn ọlọpaa mu araalu to ba ṣe wọn lai ni iwe mumimumi.
“Awọn eeyan le wa ni iwaju ile wọn, oju titi paapa awọn ọdọ lai ni idi, to si lodo sofin.
“Ko lẹtọ lati ba ọlọpọọ ja ijakadi, lọ ibọn mọ wọn lọwọ tabi ma saa kiri.
“Eeyan ni lati kọkọ bere pe iwe munimuni wọn n kọ.”
"Ẹru lo n ba ọpọlọpọ ti wọn n fi saa fun ọlọpaa"
Ogunlana tẹsiwaju pe ni ọpọ igba bi awọn ọlọpaa ṣe ma n ṣe awọn eeyan ti wọn mu lo ba ọpọ eeyan lẹru ti wọn n fi saa.
“Ki ṣ e nnkan to da ni sugbọn bi wọn ṣe ma ṣe ti wọn mu eeyan, boya igbaju, igbati igbamu ni wọn yoo lo, ti ko yẹ ko ri bẹ, tabi ki wọn fi tajutaju si loju, ti mọ ẹyin kanta, gbogbo eyi lo n dẹru ba araalu lo fi jẹ pe wọn fẹ hu iwa odi sofin.
“Awọn ọlọpaa yii ni wọn ko ki n ṣe ọrẹ wa ni ọpọ igba sugbọn sibẹsibẹ awọn araalu kan jọ ara wọn loju ti ofin ko si fi aye silẹ fun iwa bẹẹ.”
“Nigba mii awọn ọlọpaa mii le fẹ mu eeyan ni ihoho ti wọn si ni gba laye ko wọ aṣọ tẹlẹ wọn.”
Ki lo yẹ ko ṣe nigba ti ọlọpaa ko ba wa lai mu iwe munimuni dani?
Agbẹjọro Ogunlana ni ko si bo ti le ri, ti ọlọpaa ba ti mu iwe munimuni dani, eeyan ni lati tẹle sugbọn awọn ibeere kan to yẹ ki eeyan bi awọn ọlọpaa bẹẹ.
“Ẹ bere pe iwe munimumi da, ẹsẹ wo ni mo ṣe sugbọn ọpọ igba awọn ọlọpaa ko ki n ṣe bẹ.
“Ti wọn ba da awọn ibeere pe iru ẹsẹ to sẹ re, pe agbẹjọro rẹ, ọpọ eeyan o ni ma bẹru lati tẹle wọn.”
Agbẹjọro Ogunlana ni bo ti lẹ jẹ pe o lodi sofin ki eeyan saa lasiko ti ọlọpaa fẹ mu lai mu iwe munimuni dani sugbọn saaju ohun gbogbo ẹmi ju llo ṣe koko.
O ni ọpọ igba ni awọn ma lọ mu awọn eeyan loru ati pe bi nnkan ṣe ri lasiko yii lorilẹede Naijiria, ẹru le ba eeyan.
“Elomii le ti ara mọ ile rẹ, pe o to ba di owurọ oun yoo si ilẹkun, ki wọn ka mọle looru.
“Ẹ mi o gba ọmọ Naijiria ni amọran pe ki wọn tẹle alasọ kankan loru.”
Kí ló tún gbé Portable dèrò àhàmọ́ ọlọ́pàá?
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti mu gbajugbaja olorin takasufe, Habeeb Okikiola, ẹni ti ọpọ mọ Portable fun ẹsun pe o kuna lati san owo to fi ra ọkọ G-Wagon.
Ohun taa ri gbọ ni pe Portable ra ọkọ ayọkẹlẹ G-wagon, ti owo rẹ jẹ milọnu mẹtalelogun naira sugbọn o san milọnu mẹtala fun oni mọtọ, to kọ lati san owo yooku.
Fọnran to wa lori ayelujara fihan pe ọpọ igba ni ẹni ti Portable jẹ lowo ti kesi sugbọn o ni Portable kọ lati san owo naa pada, eyi to fa to fi wa fi ọlọpaa gbe Portable.
Nigba ti akitiyan lati jẹ ki Portable san owo ja si pabo lo jẹ Ontaja mọto kesi ileeṣẹ ọlọpaa pe ki wọn wa dasi ọrọ naa.
Portable fo ẹnu ọna abawọle lati saa fun ọlọpaa
Fọnran to jade lori ayelujara safihan bi Portable ati awọn ọlọpaa ṣe n sọrọ nipa bi wọn mu iwe wa lati mu Portable.
Lasiko ti Portable n ba ọlọpaa sọrọ, ni o ṣadede fo ferese ẹnu ọna ile ti wọn ti n sọrọ sugbọn ọwọ pada tẹ.
Fọnran mii to lu ori ayelujara tun ṣafihan nigba ti ọwọ tẹ Portable, ti awọn ọlọpaa si fi sẹkẹsẹkẹ si lọwọ, ti wọn si gbẹ sinu ọkọ ayọkẹlẹ.
Ko pẹ ti iroyin nipa Portable lu sita lori ayelujara ni iwe adehun ti Portable tọwọ fun ọkunrin ti orukọ rẹ n jẹ Ogunsawo Temitope to ta ọkọ fun Portable, lori bi o ṣe ma san owo ati nnkan ti yoo ṣẹlẹ to ba kuna lati san owo.
Ninu Iwe naa Portable ni oun gba lati ra ọkọ ayọkẹlẹ Mercedes Benz GLE 350, oni awọ dudu ni owo toto milọnu mẹtadinlọgbọn naira, to si ṣe ileri lati san milọnu mejila ni bẹrẹ, iyẹn lọjọ kẹwaa oṣu kinni ọdun 2024.
O tun ṣe ileri pe oun yoo san milọnu marun un naira ni ọjọ kẹrinlelogun oṣu kinni ọdun 2024.
Portable tun sọ pe oun yoo san milọnu marun naira ni ẹmeji ọtọtọ ninu oṣu keji ọdun 2024, iyẹn ni ọjọ kẹwaa ati ọjọ kẹrinlelogun oṣu keji ọdun 2024.
Ni pari iwe adehun naa, Portable sọ pe ti oun ba kuna lati san owo pada fun Ogunsanwo Temitope, ko gba ọkọ ayọkẹlẹ naa pada lọwọ oun.
Ta a ni Portable, Were Olorin, Idaamu Adugbo?
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Portable ni ọmọ bibi ilu Abeokuta ni oun amọ Sango Ota ni wọn bi oun si, ti oun si gbe Mushin Olooṣa dagba.
O fikun pe ọdun kẹẹdogun ree ti oun ti bẹrẹ isẹ ofin kikọ amọ ọdun kẹwa ree ti oun ti di gbajumọ, ki Ọlọrun to wa ni ko zeh fun oun ni aipẹ yii.
Nigba to n salaye awọn ohun ti oju rẹ ti ri sẹyin. Portable tun salaye bi awọn eeyan bii ọdunrun se dawọ bo lati ja si ihooho ọmọluabi lori ẹsun pe o ji kẹkẹ Maruwa.