Kí ló wà láàrin Portable àti Ìyàwó Alaafin?

Gbajugbaja Olorin, Habeeb Okikiola ti gbogbo aye mọ si Portable ti tu kẹkẹ ọrọ sita lori ibasepọ rẹ pẹlu Olori Alaafin tẹlẹ, Damilola.

Portable ṣalaye ọrọ lasiko to fi n kopa lori eto kan lori ayelujara.

O ni oun ko ba ti ni ohunkohun pẹlu iyawo Oba to ba jẹ pe Alaafin si wa laye ni.

O sọ ọrọ yii lasiko to n se ifọrọwerọ pẹlu Honest Bunch, to si jẹ ko di mimọ pe lẹyin Ọba, Ọba tun ni.

"Alatilẹyin mi lati ọjọ pipẹ ni, sugbọn nigba to ya, mo gbọ pe Ọba ti ku, lẹyin Ọba, Ọba tun ni

"Ka ni Ọba si wa, ẹ ko ni ri emi ati rẹ papọ nitori n ko ki tẹle Iyawo oni iyawo kiri."

Portable tẹsiwaju pe oun ni ifẹ si gbogbo awọn iyawo oun pata, ti oun si nifẹ wọn dọgba papọ

"Obinrin to ba ti fun mi ni ifọkanbalẹ, mo ma ni ifẹ rẹ.

"Iyawo mi to wa ni ile, ko fun mi ni ifọkanbalẹ lasiko ti ilu mọ mi lo jẹ ki lọ fẹ obinrin pupọ.

Ọmọ Ọkunrin mẹfa, Iyawo mẹrin ni mo ni bayii.

Portable jẹ ko di mimọ pe Ọmọ ọkunrin mẹfa ni oun ti bi, ti oun si ni Iyawo mẹrin ọtọtọ.

Ọjọ kẹfa, ọsu kẹfa ọdun 2023 ni Portable kede Akinyanju Omolarinde to bi ọmọ kunrin fuu un gẹgẹ bi iyawo tuntun.

Lati igba ti ikede ọmọ tuntun naa ti jade si ni awọn eeyan kan ti n bu ẹnu atẹ lu baba ati iya ọmọ tuntun.

Bi awọn kan ṣe n bu Portable pe o n bimọ kaakiri, ni awọn kan n bu iya ọmọ tuntun naa ni pataki, wi pe o loyun fun ọkọ ọlọkọ.

Awọn kan ti ẹ n gba iyawo ile Portable, Omobewaji, ni imọran lori ayelujara pe, ko kọ ọkọ rẹ silẹ nitori bo sẹ n fun awọn obinrin mii loyun.

Ṣugbọn ninu fidio kan to fi si ori ayelujara Instagram rẹ ni Ọjọru, Portable sọ pe pupọ ninu awọn to n fi imọran ranṣẹ si iyawo oun lori ayelujara Whatsapp, lo jẹ ara awọn ọrẹ rẹ ti oun ti fẹ ri.

O ni iyawo oun n ri itọju to peye gba, eyi ti ko le mu ko fi igbeyawo rẹ silẹ.

Taa ni Portable?

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Portable ni ọmọ bibi ilu Abeokuta ni oun amọ Sango Ota ni wọn bi oun si, ti oun si gbe Mushin Olooṣa dagba.

O fikun pe ọdun kẹẹdogun ree ti oun ti bẹrẹ isẹ ofin kikọ amọ ọdun kẹwa ree ti oun ti di gbajumọ, ki Ọlọrun to wa ni ko zeh fun oun ni aipẹ yii.

Nigba to n salaye awọn ohun ti oju rẹ ti ri sẹyin. Portable tun salaye bi awọn eeyan bii ọdunrun se dawọ bo lati ja si ihooho ọmọluabi lori ẹsun pe o ji kẹkẹ Maruwa.

Ọrọ pọ, ti Portable ba wa sọ, ẹ maa kalọ lati gbọ.