Aráàlú fárígá bí Olórí aṣòfin ṣe fẹ́ fi ọ̀dọ́bìnrin 100 tí kò ní òbí lọ́kọ láì ró wọn lágbára

Ọpọ eeyan lori ayelujara ti wọn jẹ ọmọ Naijiria ni wọn ti n binu si bi Olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Niger ṣe fẹẹ fi awọn ọmọbinrin ọgọrun-un (100) lọkọ.

Awọn ọmọbinrin naa ko ni obi mọ latari awọn agbebọn to pa awọn obi wọn ninu awọn ikọlu nipinlẹ Niger.

Awọn ọmọbinrin naa ko lọ sileewe, bẹẹ ni ẹnikẹni ko fun wọn niṣẹ lati maa ṣe.

Eyi ni Olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa, Abdulmalik Sakindaji ṣe ni oun yoo ṣegbeyawo fun wọn, oun yoo si gbe gbogbo inawo to rọ mọ igbeyawo naa.

‘’Ìjọba Niger, ẹ má káwọ́ gbera lórí ẹ̀tọ́ àwọn ọmọbìnrin yìí’’

Lati gbeja awọn ọmọbinrin naa, ẹgbẹ kan ti wọn pe ni ‘Concerned Nigerian Citizens’, kọwe ifisun sijọba ipinlẹ Niger.

Ninu iwe naa, eyi ti ẹda rẹ n ja ran-in lori ayelujara, awọn ẹgbẹ tọrọ kan naa rọ ijọba Niger lati dide si ọrọ awọn ọmọ naa.

Wọn ni ki wọn ma ṣe jẹ ki igbeyawo tulaasi naa waye rara.

‘’Abala kejidinlogun ofin ilẹ wa ka pe gbogbo ọmọ lo lẹtọọ si ẹkọ ileewe alakọọbẹrẹ lọfẹẹ. Ẹkọ naa si jẹ dandan.

‘’Abala kẹẹẹdogun fun wọn lanfaani lati jẹ ẹni ọwọ, o si pe fun dida aabo bo ọmọ kọọkan.

‘’A rọ ijọba ipinlẹ Niger lati mu ẹtọ awọn ọmọ alailobi yii ni koko, ẹkọ wọn ṣe pataki pẹlu.

‘’Ẹ ma ṣe fipa mu wọn ṣegbeyawo, ẹ ṣeto bi wọn yoo ṣe raye gbe nile awọn ọmọ orukan tẹ ẹ ba kọ fun wọn.

‘’Kiakia la fẹ ki ijọba Niger bẹrẹ iṣẹ lori ọrọ yii, ko gbọdọ pẹ rara ti wọn yoo fi ṣeto igbe-aye ọmọluabi fun wọn’’

Bẹẹ ni ifisun naa wi.

Ọmọ Naijiria tẹ́wọ́ gba a, wọ́n buwọ́ lù ú pẹ̀lu ẹ̀dùn ọkàn

Bi ẹ́dà lẹta ifisun naa ṣe jade sori ayelujara lawọn ọmọ Naijiria ti tẹwọ gba a.

Ọpọ eeyan bẹrẹ si i buwọ lu u pe awọn faramọ ohun ti ẹgbẹ Concerned Nigerian Citizens n sọ funjọba Niger.

Wọn fi aidunnu wọn han bi wọn ṣe n pin in ka lori ayelujara.

Olórí ilé aṣòfin fẹ́ fi obìnrin 100 lọ́kọ, Mínísítà fọ́rọ̀ obìnrin pe ẹjọ

Erongba abẹnugan ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Niger, Abdulmalik Sarkindaji, lati fi ọgọrun-un kan (100) ọmọbinrin fun ọkọ ti n mi lẹsẹ bayii.

Eyi ri bẹẹ pẹlu bi Uju Kennedy-Ohanenye, minisita fun ọrọ awọn obinrin lorilẹ-ede Nigeria, ṣe ni oun ko ni i gba, to si gbe Sarkindaji lọ sile-ẹjọ.

Ọsẹ to kọja ni Sarkindaji kede pe oun yoo gbe gbogbo inawo to ba rọ mọ igbeyawo awọn ọmọbinrin ọgọrun kan nipinlẹ Niger, eyi ti rogbodiyan sọ awọn mi-in ninu wọn di alailobi mọ.

Abẹnugan Niger naa sọ pe oun fẹẹ ṣe bẹẹ gẹgẹ bi ọkan lara alakalẹ eto iranwọ toun ni fun ipinlẹ Niger ni.

Bakan naa lo ni oun ti ra gbogbo nnkan eelo ti ayẹyẹ naa nilo, oun yoo si ba awọn ọkọ san owo ori awọn ọmọbinrin wọnyi.

Ikede rẹ naa da awuyewuye silẹ, ṣugbọn Sarkindaji fesi pe oun kàn fẹẹ ṣagbatẹru igbeyawo naa ni, oun ko fi wọn lọkọ ni tipa.

Ọjọ kẹrinlelogun, oṣu karun-un ọdun 2024 yii lo fi ayẹyẹ igbeyawo ọlọpọ eeyan naa si.

Mi ò ní í gba irú ẹ̀, mo ti kọ̀wé sí ọ̀gá ọlọ́pàá, mo sì ti gba kóòtù lọ - Minisita fún ọ̀rọ̀ obìnrin

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ lori igbeyawo naa lọjọ Aje ọsẹ yii niluu Abuja, Uju Kennedy -Ohanenye, minisita fun ọrọ obinrin Naijiria, sọ pe,

‘’Mo fẹ ki abẹnugan ile igbimọ ipinlẹ Niger mọ pe igbesẹ rẹ yii lodi si ohun ti ileeṣẹ to n ri si ọrọ awọn obinrin n fẹ.

‘’Nitori kinni kan wa ti a n pe ni ẹtọ awọn ọmọ.

‘’A gbọdọ ro ọjọ iwaju awọn ọmọ yii ati ti awọn ọmọ ti yoo ti ibi igbeyawo naa jade.

‘’ Mo ti kọwe ifisun si ọga ọlọpaa pata lorilẹ-ede yii, mo si ti gba kootu lọ. Mo ni ki wọn da abẹnugan Niger lọwọ kọ lori ipinnu rẹ yii.

‘’Ki wọn ma jẹ ki igbeyawo naa waye titi ta a maa fi mọ ọjọ ori awọn ọmọbinrin naa.

‘’A gbọdọ mọ boya funra wọn ni wọn fẹẹ lọkọ abi ẹnikan lo fẹẹ fipa mu wọn, a si gbọdọ mọ iru awọn ọkọ ti wọn fẹẹ fẹ naa.’’

‘’Awọn ti ko ba fẹẹ lọ sileewe ninu wọn, a maa kọ wọn niṣẹ ọwọ, a maa ro wọn lagbara pẹlu rira irinṣẹ fun wọn"

Uju tẹsiwaju pe bi Sarkindaji ko ṣe ronu lati ro awọn ọmọbinrin naa lagbara, ti ko ronu lati ran wọn lọ sileewe tabi fun wọn lowo, ileeṣẹ ọrọ awọn obinrin yoo ṣeto iyẹn.

‘’Ileeṣẹ ọrọ obinrin ti pinnu lati maa ran awọn ọmọbinrin yii nileewe.

‘’Awọn ti ko ba fẹẹ lọ sileewe ninu wọn, a maa kọ wọn niṣẹ ọwọ, a maa ro wọn lagbara pẹlu rira irinṣẹ fun wọn.

‘’To bẹẹ ti wọn yoo le da duro nibi gbogbo ti wọn ba ti ba ara wọn, ti wọn yoo si le ṣe ipinnu iru ọkọ ti wọn ba fẹẹ fẹ.

‘’Bi abẹnugan ba waa fẹẹ tapa si awọn ohun ti mo la kalẹ yii, a jọ maa wọ ṣokoto ofin ni’’

Minista ọrọ obinrin sọ pe ijọba lẹtọọ lori ọmọ kankan labẹ ofin, ijọba ko si ni i laju silẹ ki ẹnikẹni fi ẹtọ ọmọ dun un.