You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọkùnrin tí wọ́n fi kíndìnrín ẹlẹ́dẹ̀ rọ́pò kíndìnrín rẹ̀ pàpà jáde láyé
Ọkunrin akọkọ ti wọn fi kindinrin ẹlẹdẹ rọpo kindinrin rẹ ti jade laye lẹyin oṣu meji ti iṣẹ abẹ waye.
Richard “Rick” Slayman, ẹni ọdun mejilelọgọta ni aisan kindinrin n ba finra tẹlẹ ko to di pe o ṣe isẹ abẹ ninu oṣu kẹta ọdun 2024.
Ile iwosan Massachusetts General Hospital sọ lọjọ Aiku pe, awọn ko ti ri ẹri kankan to tọka si pe iṣẹ abẹ fifi kindinrin ẹlẹdẹ rọpo kindinrin rẹ lo ṣeku pa.
Awọn iṣẹ abẹ fifi kindinrin ẹlẹdẹ rọpo kindinrin eeyan lo ti lulẹ tẹlẹri, saaju ki iṣẹ abẹ Slayman to jẹ aṣeyọri.
Ni afikun si aisan kindinrin to n ṣe Slayman, o tun ni aarun itọ suga ati ifunpa to ga.
Ni ọdun 2018, o ṣe iṣẹ abẹ ti wọn fi kindinrin eeyan rọpo kindinrin rẹ sugbọn lẹyin ọdun marun un, kindinrin naa pana iṣẹ.
Lẹyin to ṣe iṣẹ abẹ kindinrin ẹlẹdẹ lọjọ kẹrindinlogun oṣu kẹta, awọn dokita rẹ fidi rẹ mulẹ pe, ko nilo ayẹwo kindinrin mọ nitori kindinrin ẹlẹdẹ to wa lara rẹ n sisẹ daada.
“Rick gba lati ṣe iṣẹ abẹ fifi kindinrin ẹlẹdẹ paarọ kindinrin tiẹ lati pese ireti fun ọpọlọpọ eeyan to nilo iṣẹ abẹ naa lati wa laye"
Awọn dokita naa ni “Slayman yoo jẹ apẹẹrẹ ireti fun awọn to n fi kindinrin parọ lagbaye.
A si dupẹ lọwọ rẹ fun bi o se gba wa gbọ, to si gba lati ṣe iṣẹ abẹ naa,” Ile Iwosan MGH sọ ninu atẹjade ti wọn fi lede.
Ile iwosan MGH ni inu awọn bajẹ pupọ lori iku Slayman, ti wọn si ransẹ ibanikẹdun si awọn mọlẹbi rẹ.
Awọn mọlẹbi Slayman ni iwuri nla ni itan aye Slayman jẹ fun ọpọlọpọ.
“Rick ni idi kan pataki ti oun fi gba lati ṣe iṣẹ abẹ naa ni lati pese ireti fun ọpọlọpọ eeyan to nilo iṣẹ abẹ naa lati wa laye.
“Ohun ti Rick gbe se lo jẹ manigbagbe. fun awa mọlẹbi, Rick jẹ eeyan kan to fẹran awọn to wa layika rẹ, to si ma pa wọn lẹrin.
“O lo gbogbo akoko rẹ fun awọn mọlẹbi, ọrẹ ati awọn alabasiṣẹpọ rẹ,”
Nigba ti Slayman fi kindinrin ẹlẹdẹ rọpo kindinrin rẹ, ko kii ṣe igba akọkọ ree ti wọn yoo lo ẹya kan lara ẹlẹdẹ fi rọpo ti eeyan.
Eeyan meji ti wa saaju ti wọn fi ọkan ẹlẹdẹ rọpọ ọkan wọn sugbọn igbeṣẹ naa pada ja si iku, ti awọn eeyan meji ti wọn ṣe iṣẹ abẹ fun un naa si jade laye.