You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àwọn nǹkan mẹ́jọ tó yẹ kó o mọ̀ nípa Dorcas Adeyinka tí ọlọ́pàá kéde pé àwọn ń wá
Lati igba ti iroyin ti jade pe awọn ọlọpaa n wa ilumọọka lawujọ, Dorcas Adeyinka lawọn eeyan ti n beere pe iru eeyan wo gan ni Dorcas Adeyinka ti awọn ọlọpaa fi gbe bana rẹ si igboro aye pe awọn nwa.
Diẹ lara awọn ohun ti a ri ṣa jọ nipa rẹ niyi.
Ọmọ orilẹ ede Naijiria to tun jẹ ọmọ orilẹ ede ilẹ Gẹẹsi ni Darocas Adeyinka.
Ọdun meje ni Dorcas Adeyinka wa to fi lọ si UK. Ní UK lo ti kẹkọọ alakọọbẹrẹ, girama ati fasiti.
Ni ile ẹkọ giga fasiti University of East London lo ti kẹkọọ gboye ninu imọ ofin.
Dorcas Adeyinka ti pe ogoji ọdun loke eepẹ.
Gẹgẹ bi nnka to kọ soju opo Facebook rẹ, Dorcas Adeyinka jẹ olokoowo to di gbajugbaja latara iṣẹ to yan laayo.
Bakan naa lo jẹ ẹlẹyinju aanu to si maa n polowo fun awọn ile iṣẹ lori ayelujara.
O ni ikanni iroyin lori ayelujara to pe orukọ rẹ ni TMS blog.
Ọmọ bibi ipinlẹ Ekiti ni.
Ọ̀pọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ tí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá kà sí Dorcas Adeyinka lọ́rùn rèé, tó fi di ẹni tí ọlọ́pàá ń wá
Ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria ti kede pe awọn n wa gbajumọ kan ni awujọ ati ori ayelujara, Dorcas Adeyinka, ti ọpọ eeyan tún n pe ni Boss Lady.
Lara awọn ẹsun ti ileesẹ ọlọpaa sì ka si lọrun ni ẹsun ijinigbe, iṣekupani, idunkoko si ẹmi, gbigba riba ati awọn ẹsun mii to lodi si ofin orilẹede Naijiria.
Bo ti lẹ jẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa ko sọrọ pupọ lori awọn ẹsun ti wọn ka si obinrin naa lọrun, amó wọn rọ awọn araalu lati fa obinrin naa le Ileeṣẹ ọlọpaa to ba wa ni tosi lọwọ ti wọn ba ri.
Ileeṣẹ ọlọpaa ṣapejuwe Adeyinka gẹgẹ bi sọrọsọrọ lori ayelujara lati ilu Ekiti ati Ibadan, ti wọn si tun juwe rẹ bi Ọlọrun ṣe ṣẹda rẹ.
Ileeṣẹ ọlọpaa tun jẹ ko di mimọ pe Ilu Ọba ni Adeyinka n gbe, to si ma wa lorekore si agbegbe Ikeja, Ogugua, Fagba, Otta ati Sango.
N ko ni dẹkun iwa rere ti mo n hu, eyi to n bi awọn ọta mi ninu - Dorcas Adeyinka fesi
Nigba to n fesi si ikede ileeṣẹ ọlọpaa lori ayelujara ikanni Facebook, Adeyinka rọ ileeṣẹ ọlọpaa lati ma se iṣẹ wọn ni ilana ti ofin gbe kalẹ.
O tun jẹ ko di mimọ pe oun ma da ileeṣẹ ọlọpaa loun ti wọn ba kesi oun pe koun wa.
“Emi nikan ni mo ni gbogbo ẹsun yii? A le ṣe ju bayii lọ lorilẹede yii.
“Ṣe ẹ ti ṣe iwadii yin, ki ẹ to kede sita pe ẹ n wa mi? Se mo ti fi igba kan ma da yin lohun, ti ẹ ba ransẹ si mi?
Koburu, Ma wa si ọọfisi yin laipẹ.
“Emi ni Dorcas Adeyinka, Ọmọ ilẹ gẹẹsi atata. Ẹ ṣeun.”
Adeyinka tun salaye pe niwọn igba ti inu oun mọ, oun ko ni bẹrẹ ohunkohun.
"N ko ki jẹ ki iṣẹ rere mi to n bi ọta ninu, to si pese iranlọwọ fun awọn aiani wa sopin nitori o wa ninu mi.
"Gbogbo awọn to n kọ ikọkukọ nipa mi lori ayelujara ni wọn tun gbe fọnran ihoho mi sita."
Ki lo ti ṣẹlẹ saaju?
Iwadii wa fihan pe Ileẹjọ Magistrate niluu Wuse ni Abuja ti ransẹ pe awọn eeyan meji to n lo ayelujara fun ẹsun ibanilorukọ jẹ si Dorcas Adeyinka, ti wọn si tun fi fọnran ihoho rẹ sita lori ayelujara.
Ninu iwe ẹjọ ti ọjọ kẹsan an oṣu kearun un ọdun 2024, adajọ Emmaunel Iyanna paṣẹ fun awọn olujẹjọ meji naa – Tolulope Adeoye, ti ọpọ mọ si Abike Jagaban ati Tolulope Odegbami, ti ọpọ mọ si Olowosibi, lati fara han si ile ẹjọ lọjọ kẹrin oṣu kẹfa ọdun 2024 lati wa wi tẹnu wọn.
Adeyinka ko fi igba kankan ma da ileeṣẹ ọlọpa lohun – Agbẹjọro
Pelumi Olajengbesi, to jẹ agbẹjọro fun arabinrin Docas Adeyinka ni eti awọn ti kun si orisiris iroyin to gba ori ayelujra kan pe Ileeṣẹ ọlọpaa n wa onibara oun fun ẹsun kan tabi omiran.
O ni ohun to jẹ ohun iyalẹnu fun awọn ni pe ikede naa wa lati oju opo ayelujara ileeṣẹ ọlọpaa.
Olajengbesi ni ileesẹ ọlọpaa si fẹ jẹ ki di mimọ fun gbogbo araalu pe Adeyinka ko fi igba kankan kọ eti ikun si ipe ileeṣẹ ọlọpaa.
“Onibara mi lo sa lọ sọdọ awọn ọlọpaa lati jẹ ki wọn mọ pe awọn eeyan kan n gbe fọnran ihoho rẹ kiri lori ayelujara.
Sugbọn o jẹ ohun iyalẹnu pe Ọlọpaa n dunkoko mọ onibara mi lati jẹ ko dakẹ lori ọrọ naa.
“Ko ki n ṣe igba akọkọ ree ti onibara mi yoo wa ninu ipo yii, ninu oṣu kejila ọdun to kọja, wọn pe lẹjọ sugbọn ile ẹjọ pada da lare.
“Pe wọn kede eeyan to si wa ni ita lanaa ọjọ kọkanla oṣu karun un nibi ti wọn ti fi oye da lọla tumọ si pe boya awọn eeyan kan ti tọwọ bọ oju opo ayelujara ileeṣẹ ọlọpaa.
“Pẹlu gbogbo eyi, onibara mi setan lati faran ni ilana ti ofin gbe kalẹ .”