Mothers Day: Àyájọ́ ìrántí àwọn ìyá àti ìdí tí ẹnu kò fí kò lórí ọjọ́ yìí lágbayé

O ṣeeṣe ki wọn ti fi ọrọ ikini ranṣẹ si ọ loni ni imọriri pataki ipa tawọn iya n ko lawujọ.

Idi ni pe loni ni ọpọ eeyan ni Naijiria n ṣe ajọyọ awọn iya taa mọ si Mothers Day.

Ọjọ pataki ni ọjọ yii jẹ lati fi se ayẹsi awọn mama wa, gbigbe oṣuba fun jijẹ abiyamọ ati mimọ riri okun to wa laarin awọn iya ati awujọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Toun ti bi ayajọ awọn obinrin ti se pataki si, awọn kan ti n sọ pe ninu awọn ayajọ to wa laye, ko si eleyi to n fa iruju bi ayajọ awọn iya.

Pataki ọjọ yii kọ lo n fa awuyewuye, bi kii se pe ko si aridaju pato lori ọjọ ti wọn n ṣe ayajọ naa gan.

Ki lo fa iruju nipa ayajọ awọn obinrin:

Bẹrẹ lati oṣu Keji ọdun lawọn ọrọ ikini ayajọ yii ti maa n gba ori afẹfẹ kaan.

Ko tan sibẹ, yoo tẹsiwaju wọ inu oṣu Kẹta ikẹrin ati ikaarun ọdun.

Ko da awọn mii a tun maa se ayajọ ọjọ yii ninu oṣu Kẹjọ ọdun ati igba kigba to ba fẹ si wọn lọkan.

Iruju ayajọ awọn obinrin naa de ọdọ awọn ile ijọsin Aguda ati awọn ti Anglican ,debi pe ọjọ ọtọtọ ni wọn ya sọtọ ni iranti ọjọ yii.

Ọjọ wo wa ni ojulowo ayajọ awọn iya lagbaye?

Wọn a maa se ayajọ ọjọ awọn iya, o kere tan, lorileede aadọta jakejado agbaye ṣugbọn kii ṣe ọjọ kanna ni wọn maa n se.

Ibi ti eeyan ba wa ni yoo tọka si ọjọ ti yoo ba wọn se ayajọ yii.

O ṣe pataki lati mọ pe ọjọ Aiku ni ayajọ awọn obinrin maa n bọ si, paapa lawọn orileede ti ijọ Aguda ati Anglican ba ti fẹsẹ rinlẹ.

Koda wọn ya orukọ sọtọ fun ọjọ naa eleyi ti wọn n pe ni ''Mothering Sunday''

Ayajọ awọn obinrin a tun maa yi pada nitori bi onka oju ọjọ naa ṣe n yi pada.

Lawọn orileede kan , ayajọ naa maa bọ si ọjọ Aiku kẹrin ninu oṣu awẹ Lent.

Eyi to se koko ni pe ni Naijiria, ijọba ko fontẹ lu ayajọ awọn obinrin bii tawọn ayajọ mii to ni ọjọ isinmi lnu isẹ ti wọn ya sọtọ fun wọn, bii Keresimesi ati ọdun Ileya musulumi.

Orisun ayajọ iya:

Akọsilẹ taa ri fi han pe awọn eeyan ilẹ Greece lo kọkọ ṣe ayajọ awọn obinrin pẹlu bi wọn ṣe maa n se ajọdun na ni ayẹsi Rhea ati Cybele, to jẹ bi yeye orisa.

Nigba ti ọjọ sun siwaju kuro bọ si igba taa n pe ni Middle Ages, wọn ni aṣa kan tawọn eeyan fi maa n ṣe abẹwo si ilu ti wọn ti bi wọn tabi ile ijọsin wọn.

Ọjọ yii a maa ṣe deede ọjọ Aiku kẹrin ninu oṣu awẹ Lent.

Nigba taa n wi yi, awọn ọmọde a maa kuro ni ile lọ ṣiṣẹ ni ilu mii lati igba ti wọn ba ti wa ni nkan bi ọmọ ọdun mẹwaa.

Anfaani ayajọ yii ni wọn fi n pada sile, to si pada di ayajọ iya lagbegbe naa..

Nilẹ Gẹẹsi, ayajọ ayẹsi Rhea ati Cybele yii lo yira pada wa di Mothering Sunday.

Bo tilẹ jẹ pe wọn n pe ni ayajọ iya, amọ ko ni ajọṣepọ pẹlu iru eleyi ti wọn a maa ṣe ni Amẹrika.

Bawo ni ayajọ iya se bẹrẹ ni Amẹrika:

Ni Amẹrika, ọjọ Aiku keji ninu oṣu Karun ni wọn ya sọtọ fayajọ yii.

Orisun ayajọ naa la tọ ipasẹ rẹ de bi iṣẹlẹ kan nibi ti arabinrin kan Anna Jarvis, ti se isin iranti fun iya rẹ lọjọ kejila oṣu karun ọdun 1907.

Ko pẹ si igba naa lawọn eeyan bẹrẹ si ni kọ ise rẹ, to si di ayajọ ni ọdun 1914 nigba ti aarẹ sọ di ọjọ isinmi lorileede naa, ti wọn a maa se lọjọ Aiku keji oṣu Karun.

Ọpọ orileede agbaye lo maa n se ayajọ yii ni igba ọtọọtọ laarin ọdun bakan naa.

Ọjọ tawọn orilẹede lagbaye n ṣe ayajọ awọn obinrin:

Kaakiri agbaye awọn ọjọ ayajọ awọn obinrin ree:

  • Guernsey, Ireland, Isle of Man, Jersey, Nigeria ati United Kingdom, Ọjọ Aiku keji ninu oṣu Lent tori naa ayajọ ọdun yii bọ si Sunday, 27 March
  • Mother's Day 2022 ni Amerika jẹ Sunday, 8 May
  • Ni Mexico ati awọn orileede Latin amẹrika mii, ayajọ yii bọ si ọjọ Kẹwa oṣu Karun ọdọọdun
  • Thailand, wọn a maa ṣe ayajọ yii ni ọjọ Kejiula oṣu Kẹjọ ọdun, to ṣe deede ayajọ ọjọ ibi ọbabinrin ilẹ naa.

Awọn orileẹde mi to so ayajọ mii mọ ayajọ awọn obinrin lagbaye ni Russia, Bulgaria, Serbia, Afghanistan, Romania ati awọn miran

Diẹ ree lara awọn ọrọ manigbagbe tawọn eeyan n kọ niranti ayajọ awn obinrin:

"Bi mo ba fẹ juwe iya mi, bi igbape ki a maa sọrọ nipa agbara ti iji lile ni''- Maya Angelou

"Gbogbo ohun ti mo da, ati eleyi ti mo gbero lati da laye, ọpẹlọpẹ iya mi ni''- Abraham Lincoln

"Iṣẹ iyanu to n rin laarin wa ni mama mi jẹ" - Leonardo DiCaprio

"Ifẹ lo bi wa saye, ifẹ si ni mama wa." - Rumi

"Ko si ọwọ ẹni to daabo bo ẹni bi ti iya mi." - Princess Diana

"Awọn iya wa dabi gọọmu to le nkan pọ. Koda bi wọ́n ba lọ tan, wọn a si maa so mọlẹbi papọ." - Susan Gale