Tinubu fòǹtẹ̀ lu lílá ọ̀nà túntun láti Iseyin sí Okeho lọ Iganna l‘Oyo

Ijọba apapọ ti kede awọn akanṣe iṣẹ tuntun mọkanlelogun ti yoo bẹrẹ laipẹ yii lẹyin ipade igbimọ alaṣẹ rẹ to waye niluu Abuja fun ọpọ wakati.

Agbẹnusọ fun Aarẹ, Bayo Onanuga, lo fi ikede naa sita loju opo X rẹ lẹyin ipade naa pe lara awọn iṣẹ ọhun ni fifi ontẹ lu iwe irinna laarin ọjọ meji pere.

Ipade igbimọ ilu na lo waye lati ọjọ Aje ti wọn si pari rẹ lọjọ Iṣẹgun.

Lẹyin ipade ọhun ni ijọba buwọlu awọn igbesẹ atawọn iṣẹ akanṣe tuntun, eyii to ni yoo tubọ jẹ ki ọrọ aje Naijiria gboro si, ti ara yoo si tu awọn araalu.

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ lẹyin ipade ọhun, minisita feto iroyin, Mohammed Idris, sọ pe ijọba Naijiria ti n ṣe atunṣe si ilana fifun alejo ni iwe asẹ irinna fisa, eyii ti yoo maa jade laarin wakati mejidinlaadọta pere.

Gẹgẹ bii ọrọ rẹ, eyii yoo jẹ iwuri fun awọn olokowo lati ilẹ okere lati wa dowopọ pẹlu Naijiria.

Eto tuntun mọkanlelogun ti ijọba apapọ ṣẹṣẹ buwọlu

  • Pipese ilegbe lọpọ yanturu fun araalu, eyii yoo waye pẹlu ajọṣepọ ijọba apapọ atawọn ileeṣẹ aladani. Ijọba ni eyii yoo pese iṣẹ fun awọn eeyan, yoo tun mu owo ti iye to tiriliọnu meji naira si apo ilu.
  • Owo ibode ni papakọ ofurufu; eyii yoo waye ni gbogbo papakọ ofurufu to wa ni Naijiria, koda, ti Aarẹ ba n rinrinajo, wọn ni oun naa yoo san owo ibode ọhun.
  • Ijọba fofin de gbigbẹ ilẹ tabi kọnga ni kilomita mẹwaa si gbogbo afara ijọba apapọ.
  • Laarin ọsẹ mẹrin pere ni ijọba yoo ṣe agbeyẹwo eto irinna fun awọn aririnjo lati ilẹ okere, yoo si ṣeeṣe fun awọn to ti ni iwe irinna awọn orilẹede kan lọwọ tẹlẹ lati fisa lati wọ Naijiria lai gba fisa mii mọ.
  • Ijọba buwọlu rira, ati ṣiṣe idanilẹkọọ fun awọn ti yoo bojuto irinṣẹ ti wọn n lo ni papakọ ofurufu Murtala Muhammed to wa niluu Eko, eyii ti iye rẹ le ni biliọni mẹrin naira.
  • Ijọba buwọlu rira ohun elo ‘Special Purpose Vehicle’ ti yoo mu ki ayelujara jafafa si ni Naijiria ni ida 60% si 70%.
  • O tun buwọlu eto ti yoo mu ki ajọ NITDA maa pa owo wọle si.
  • Igbimọ ijọba buwọlu sisọ ile ijọba Naijiiria to wa ni ojule 324, ladugbo Jackson, ni San Francisco, nilẹ Amẹrika di ibi ti wọn yoo ti maa ṣe idanilẹkọọ nipa imọ ẹrọ, iye owo ile naa le ni miliọnu meje dollar.
  • Ijọba buwọlu kikọ ibudokọ kaakiri ilu Abuja, eyii ti iye owo rẹ to biliọnu mọkanlelaadọta naira.
  • O buwọlu iṣẹ agbaṣe fun ileeṣẹ Messrs El & Matt Nigeria fun atunṣe oju ọna Kwaita-Yebu niluu Abuja, iye owo iṣe naa jẹ N7.6b.
  • O buwọlu iṣẹ agbaṣe fun ileeṣẹ Messrs Visible Construction Limited lati kọ ile ẹjọ kọtẹmilọrun niluu Abuja ni owo ti iye rẹ to N37.2b.
  • Ijọba buwọlu ipese ina adugbo lagbegbe Bill Clinton Drive, loju ọna papakọ ofurufuru Abuja ni owo ti iye rẹ to N412m.
  • O fi aṣẹ si ibeere ileeṣẹ aṣọbode Naijiria, NIS, lati ra ọkọ Toyota Land Cruiser Buffalo V6 ti iye rẹ to N12.5 b.
  • O fun ileeṣẹ Messrs Yuan Resources Limited laṣẹ lati maa bojuto ẹka eto tẹtẹ fun ọdun marundinlogun.
  • O buwọlu atunṣe oniruru ọna ninu eyii ti Iseyin-Okeho-Iganna wa ninu rẹ.
  • O buwọlu abala keji oju ọna eti okun Lagos-Calabar ti iye owo rẹ to N1.6tr.
  • Ijọba buwọlu atunṣe oju ọna Koton-Karfe–Abaji ni Abuja ati ọna Abuja-Lokoja ni ipinlẹ Kogi ni owo ti iye rẹ to N89b.
  • Ijọba buwọlu atunṣe oju ọna Lokoja-Benin lagbegeb Okpela, Auchi, Uromi, Ekpoma ati bẹẹbẹẹ lọ, ileeṣẹ BUA Cement lo gbeṣẹ ọhun fun ni N120b.
  • Ijọba buwọlu atunṣe oju ọna Kaima-Tesse ni Kwara, Benin-Agbor ni Benin, ati Ngaski-Wara ni Kebbi ni owo ti iye rẹ to N546b.
  • O buwọlu akanṣe iṣẹ oju ọna fun ileeṣẹ Messrs CCECC ni Kano, iye owo iṣẹ naa jẹ N230b.
  • Eyii to buwọlu kẹyin ni oju ọna Sokoto-Illela-Badagry, ti yoo wa lara oju ọna eti okun Lagos-Calabar.