Ìpàdé ìjọba àpapọ̀ àti NLC lórí ìdúnkookò ìyanṣẹ́lódì forí ṣánpọ́n

Ipade ijọba apapọ ati ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC lori idunkooko iyanṣẹlodi ti wọn ṣe niluu Abuja lọjọ Aje fori ṣanpọn.

Minisita ọrọ awọn oṣiṣẹ ati igbniṣiṣẹ, Simon Lalong ati igbakeji rẹ, Nkeiruka Onyejeocha ṣepade pọ pẹlu aarẹ ẹgbẹ NLC, Joe Ajaero atawọn olori ẹgbẹ naa lati dawọn duro lori igbesẹ wọn lati gunle iyanṣẹlodi.

Amọ, wọn o le fẹnu ko lori nkankan pẹlu awọn ohun ti ẹgbẹ oṣiṣẹ n beere fun.

Ijọba apapọ yoo si tẹsiwaju ipade rẹ pẹlu ẹgbẹ NLC.

Bakan naa, minisita yoo tun ṣepade pọ pẹlu ẹgbẹ oṣiṣẹ TUC naa.

Ìjọba àpapọ̀ ránṣẹ́ pé NLC lórí ìdúnkookò ìyanṣẹ́lódì

Ijọba apapọ ti ransẹ pe ẹgbẹ osisẹ lorilẹede Naijiria, NLC lori ero wọn lati gunle iyansẹlodi ọlọjọgbọrọ.

Bi ẹgbẹ osisẹ n ṣe n gbero lati gunlẹ iyansẹlodi lori igbesẹ ijọba apapọ lati yọ owo iranwọ epo bentiro ati bi nnkan ṣe nira fun awọn eeyan lorilẹede Naijira, Minisita fun ọrọ awọn osisẹ ati igbanisisẹ, Simon Lalong ransẹ fun ijiroro lori ọna abayọ.

“Minisita fun ọrọ osisẹ ati igbanisisẹ, Simon Bako Lalong, ti ransẹ pe ẹgbẹ osisẹ fun ipade lori erongba wọn lati gunle iyanṣẹlodi,” agbẹnusọ ẹka ileeṣẹ ijọba, Olajide Oshundun lo kede ọrọ.

“Minisiti ti kede awọn ti ọrọ kan lati kan si awọn olori ẹgbẹ osisẹ NLC fun ipade lojo kejidinlogun oṣu kẹsan an ọdun 2023, to si se koko ti awọn ajọ naa joko ti ijọba lati wa ọna abayọ fun ero iyansẹlodi.

Oshundun ni Minisita n tẹle asa Aarẹ Bola Tinubu lati pese anfani fun ijiroro laarin ẹgbẹ osisẹ ati ijọba, ti wọn yo si pese idahun si ibeere ẹgbẹ NLC ati TUC.

Ko to di asiko yii, Minisita ni kọkọ pe fun ipada laarin Ijọba ati ẹgbẹ osisẹ NLC ati TUC sugbọn ẹgbẹ osisẹ TUC nikan lo yọju.