Gómìnà ìpínlẹ̀ Osun kéde òfin kóńlé ó gbélé n’íjọba ìbílẹ̀ Orolu àti Irepodun lórí ìjà ilẹ̀

Gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke ti kede ofin konle o gbele ni ijọba inilẹ Orolu ati Irepodun lẹyin ti rogbodiyan bẹ silẹ lori ija ilẹ laarin ijọba ibilẹ mejeeji.

Kọmiṣọnna eto iroyin ati ilanilọyẹ, Họnọrebu Kolapo Alimi lo kede igbesẹ gomina yii ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Aiku.

Ṣaaju ni iroyin kan ti sọ pe awọn eeyan kan ṣekupa agbẹ kan ti orukọ rẹ n jẹ Sodiq Alamu ni abule Opapa to wa ni ijọba ibilẹ Irepodun.

Gomina Adeleke sọ pe oun ti gbọ nipa ija ilẹ laarin ilu Ifon ati Ilobu, eyi lo si jẹ ki oun paṣẹ konle o gbele lati ri pe alaafia jọba.

Gẹgẹ bi atẹjade naa ṣe sọ, ofin konle o gbele yii yoo maa bẹrẹ ni ago mẹjọ alẹ titi di ago mẹfa aarọ ọjọ keji.

Eeyan tabi ọkọ ko si gbọdọ rin lasiko konle o gbele yii ni ijọba ibilẹ mejeeji tọrọ kan.

Gomina ni igbesẹ yii ṣe pataki lati le dena fifi ẹmi ṣofo ati biba dukia jẹ nitori ilẹ.

Gomina Adeleke sọ pe ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ pe o n rin gbere gbere kaakiri yoo foju wina ofin.

Gomina wa rọ gbogbo awọn tọrọ kan ni ijọba ibilẹ mejeeji pe ki wọn semẹdọ, ki wọn si gba alaafia laaye.

Awọn ọmọbibi ilu Ifon ti fẹsun kan olori ologun oriilẹ, ọgagun Taoreed Lagbaja pe to jẹ ọmọbibi Ilobu pe o fẹ lo agbara rẹ lati fi agidi gba ilẹ awọn.

Amọ, ọgagun Lagbaja ti fesi pe ọrọ ko ri bẹ rara.