Títí tí Mohbad fi jáde láyé, inú ẹ̀rù ló ń gbé - Iya Mohbad

Iya to bi olorin takasufe to di oloogbe, Ilerioluwa Aloba ti ọpọ mọ si Mohbad ti sọrọ fun igba akọkọ ti ọmọ jade laye.

Ninu fọnran kan to wa lori ayelujara, pẹlu omije ni Iya Mohbad fi ranti awọn igba igbẹyin ọmọ rẹ, to si tun fẹsun kan Afeez Fashola ti ọpọ mọ si Naira Marley ati awọn akẹgbẹ rẹ pe wọn fiya jẹ Mohbad to ko di pe o jade laye.

O ko si nnkan to jọ mọ pe Mohbad ni aarun ọpọlọ sugbọn o fi di rẹmulẹ pe inu ẹru ti ọmọ oun gbe titi to fi jade laye.

Lori fọnran kan to waye lori ayelujara ni bi ti Mohbad ti sọrọ pe wọn fun oun ni nkan funfun lati mu.

“Ọmọ mi wa ni ile orin nigba ti ọwọ tẹ awọn yooku. Ko si ni ile pẹlu wọn nigba ti wọn wa.

“Inu ẹru ni Ọmọ mi n gbe ti ti to fi di ọjọ to jade laye. Gbogbo wahala yii bẹrẹ lọjọ to darapọ mọ ileeṣẹ orin Marlian. Lati ọjọ naa ko ni isimi rara.

“Ọpọ igba ni wọn pe mi, ti wọn si sọ bi Naira Marley ati awọn eeyan rẹ ṣe n fiya jẹ ọmọ mi.

“Ọmọ mi kọ lati lọ ṣe awọn isẹ kan nitori o gbọ pe awọn eeyan Naira Marley wa ni bẹ.

‘Ọmọ mi o ni aarun ọpọlọ’

Iya Mohbad ni ko si nnkan to jọ mọ pe Mohbad ni aarun ọpọlọ sugbọn oun dakẹ lati ọjọ yi ọmọ oun ku nitori wọn ko fun oun laye lati sọrọ.

“Ọmọ ni iyawo ati ọmọ, Bawo ni awọn eeyanj yoo ṣe ni o ni aarun ọpọlọ.

“Nigba ti mo dele lọjọ Aje ni mo gba ipe pe ọmọ mi ti jade laye, ẹni ti mo wa pẹlu ni ọjọ diẹ sẹyin.

“Gbogbo ẹyin ti ẹ n gbe iroyin ofege nipa rẹ, ẹ bẹru Ọlọrun. Gbogbo ẹni to lọwọ ninu iku Mohbad nio yoo ri ibinu Ọlọrun.

'Mo mọ pe ọmọ gun igi kọja iwe nigba to tọwọ bọ adehun pẹlu Naira Marley'

Iya Mohbad tẹsowaju pe oun mọ pe ọmọ oun ti kọja aye rẹ nigba ti o sọ fun oun pe oun tọwọbọ adehun pẹlu Naira Marley.

“Mo mọ pe wahala ti wa nigba to sọ fun mi nipa Naira Marley

“Mo n bẹ gbogbo ọmọ Naijiria lati ran mi lọwọ lori idajọ ododo.”

A kò fún Mohbad ní májèlé jẹ ní àgọ́ wa- NDLEA

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ to n gbe ogun ti ogun oloro lorilẹede Naijira, Femi Babafemi bu ẹnu atẹlu ọrọ kan to ja kiri lori ayelujara pe olorin to di oloogbe, Ilerioluwa Aloba ti ọpọ mọ si Mohbad jẹ majele lasiko to wa ni ahamọ NDLEA.

Babafemi, ninu ọrọ to gbe sori ayelujara X lọjọ Satide, salape Mohbad ko si lara awọn eeyan ti ajọ NDLEA ko ni ile orin Marlian ninu ọdun 2022.

O ni ọkunrin m mẹfa ati obinrin meji ni ọwọ tẹ lasiko naa, awọn ni Oniyide Azeez(Zinolesky), Owoeye Micheal (m) ati Abimbola Ogbe (m).

Awọn yooku ni Dominica Chinwe (f), Olaolohun Shubomi Mariam (f) ati Ibrahim Alawo (m).

“Bi nnkan ṣe lọ ree lasiko ti a ṣe abẹwo si ile orin Marlian ninu oṣu keji ọdun 2022, isẹlẹ yii ni awọn kan ti iroyin ofege pe ajọ NDLEA lo fun Mohbad ni majeje, eyi to jẹ irọ to jina si otitọ.

“Mo le ro pe wọn gboya lati sọ eleyi lasiko ti ọwọ ofiun ba tẹ wọn.”

Alaye yii jade lẹyin ti fọnran oloogbe naa gba ori ayelujara, nibi to ti n sunkun nibi ile kan to da bi ile iwosan.

Ninu fọnran naa, Mohbad ni awọn eeyan lu oun ni alubami, ti wọn si fun oun ni nnkan funfun lati mu.

“Wọn fun omi lati mu, omi yẹn wa ninu ike. Wọn mo n lo ogun oloro. Emi nikan ni mo mu omi naa, wọn ko fun awọn yooku. N ko le parọ. Nigba to ya wọn ni ki ma lọ si ile, ki awọn yooku si duro.”

Abẹ́rẹ́ tí wọ́n fún Mohbad ni mo rò pé ó ṣekú paá - Baba Mohbad

Baba onkọrin to di oloogbe, Ilerioluwa Aloba ti ọpọ mọ si Mohbad ti sọrọ nipa iku ọmọ rẹ.

Ninu fọnran kan to jade lọjọ Satide, Joseph Aloba salaye pe oun ro pe abẹrẹ ti wọn fun Mohbad lo ṣekupa.

“Nnkan ti mo ni pe abẹrẹ ti wọn fun lo ṣekupa. N ko mọ awọn eeyan to gbe lọ si ile iwosan sugbọn gẹgẹ bi nnkan ti mo gbọ, o bẹrẹ si ni ma bi lẹyin to gba abẹrẹ, ti wọn si tun gbe lọ si ile iwosan."

"N ko gbọ nkankan lẹnu dokita nitori n ko si ni bẹ. Wọn gbe pada wa si ile, ti mo si ri oku rẹ.

“Mo pinu pe ki wọn gbe oku rẹ wa si Ikorodu fun eto isinku nitori mo gba gbọ pe Oluwa to fun mi naa lo gba pada.

A ko le ni Naira Marley lo ṣekupa Mohbad

Baba Mohbad ni oun mọ nipa ede ayede to wa laarin Naira Marley ati Mohbad sugbọn oun ko gbagbọ pe Naira Marley lo ṣekupa Mohbad

"Nigba ti Mohbad ati Naira Marley ni ede ayede, mo le fi ọwọ gboya pe nkankan ko ṣe ọmọ mi nitori lọjọ naa mo lọ ba, ti mo si gbadura fun, o dẹ sọ fun mi pe oun fẹ jade .

“Nigba naa ni ọrẹ kan wale, to si fun mi awọn ẹri bi wọn ṣe na Mohbad ni Marlian House

“Mo fẹ fi ẹsẹ rin lọ ile Naira Marley sugbọn ẹru bami nitori n ko mọ nkan ti ma ba pade nib. Igba kan wa ti Naira Marley pe sugbọn mo gbinyanju lati pe pada sugbọn ko wọle.

“Mo ti gbọ ọpọlọpọ nkan sugbọn sugbọn a ko le ni Naira Marley lo wa ni di rẹ. Wọn ṣe ikọlu si Mohbad nigba to sisẹ pọ pẹlu Zlatan sugbọn Naira Marley ko si pẹlu awọn to wa sibẹ.”