You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
NLC àti ìjọba àpapọ̀ tako ara wọn lórí ìyanṣẹ́lódì tí yóò wáyé nínú ọ̀sẹ̀ yìí
Ninu igbiyanju rẹ lati ri daju pe ẹgbẹ oṣiṣẹ, NLC, ko da iṣẹ silẹ lọjọ Iṣẹgun ati Ọjọru to ọsẹ yii gẹgẹ bii ileri rẹ, ijọba apapọ ti sọ pe oun yoo tun ba ẹgbẹ naa ṣe ipade.
Amọ ẹgbẹ ọhun ti sọ pe ko si oun ti yoo yẹ iyanṣẹlodi ọlọjọ meji naa bo tilẹ jẹ pe oun ṣetan lati tẹsiwaju lati ma aba ijọba jiroro.
Lọwọ yii, awọn ọmọ ẹgbẹ naa lawọn ipinlẹ kan ti ni awọn ti ṣetan lati da iṣẹ silẹ, nigba ti awọn ọmọ ẹgbẹ lawọn ipinlẹ mii sọ pe awọn yoo jiroro lọjọ Aje lati mọ igbesẹ ti awọn yoo gbe.
NLC, ninu atẹjade kan ti alaga rẹ Joe Ajaero ati akọwe rẹ, Emmanuel Ugboaja jọ fọwọ si lọjọ Ẹti sọ pe igbesẹ awọn lati pada da iṣẹ silẹ ko ṣẹyin bi ijọba Aarẹ Bola Tinubu ṣe kuna lati wa ọna abayọ si iṣoro ti awọn araalu n koju lẹyin to yọ owo iranwọ ori epo bẹntiro.
Ẹgbẹ naa fi ẹsun kan ijọba apapọ pe o mẹnu kuro lori ijiroro awọn to n lọ lọwọ, bẹẹ lo tun kọ lati mu awọn ileri to ti ṣe ṣaaju ṣẹ ninu awọn ijiroro to ti waye sẹyin.
O mẹnuba koko nnkan mẹfa to fẹ ki ijọba Tinubu ṣe amọ to ti kuna rẹ.
Gẹgẹ bii ohun ti atẹjade naa sọ, NLC ti ṣetan lati da iṣẹ silẹ laarin ọjọ mẹrinla si ọjọ mọkanlelogun bẹrẹ lati ọjọ Ẹti to kọja ayafi ti ijọba ba yanju iṣoro to wa nilẹ.
NLC fẹsun kan ileeṣẹ ọlọpaa pe o kogi dina ẹnu ọna ọọfisi ẹgbẹ awọn awakọ, NURTW.
NLC tun fẹsun kan ijọba pe o n tẹ ẹtọ awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ loju mọle nipinlẹ Imo, o n da si ọrọ awọn ọmọ ẹgbẹ nipinlẹ Abia, o tun dunkoko lati wo ile minnisita fun FCT, Nyesom Wike, atawọn ẹsun mii.
“Ko si ohun ti yoo yẹ iyanṣẹlodi wa”
Ti ẹ ko ba gbagbe, ọjọ keji, oṣu Kẹjọ, ọdun 2023 yii ni NLC ṣe iwoọde lawọn ipinlẹ kan lati fi ehonu han lori bi nnkan ṣe ri fun awọn araalu lẹyin ti ijọba yo owo iranwọ ori epo bẹntiro, ti awọn ilu ti iwọde naa ti waye si mi titi.
Ẹwẹ, lẹyin ikede NLC, minisita fun eto iroyin, Mohammed Idris, sọ fun ileeṣẹ iroyin Punch ninu ifọrọwerọ kan pe ijọba yoo ṣe ipade pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ naa ki iyanṣẹlodi ọhun ma baa waye.
Amọ NLC ti sọ pe ko si ohun ti yoo yẹ iyanṣẹlodi oun.