Ẹ̀yin abiyamọ̀ ẹ gbàmí, mí ò mọ̀ bí ẹ̀dọ̀ fóórò ọ̀mọ̀ mi ṣe pòórá ní ìléèwòsàn Eko – Ìyá ọ̀mọ̀ ọdún 12 ké síta

Iya ọmọ ọdun mejila kan ti ke gbajare sita pe ki gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu gbe ija oun ja.

Iya yii ke sita lasiko ti ọmọ rẹ n jerora lori idubulẹ aisan nitori wọn ko mọ ibi ti ẹdọ fooro rẹ ra pamọ si.

Eleyii ti ọmọ naa nilo lati gbe igbe aye alaafia abi ki wọn ṣe iṣẹ abẹ ti wọn yoo fi fun ni omiran.

Kini ohun ti iya ọmọ naa sọ?

Iya ọmọ naa ti ọrukọ rẹ n jẹ Abiodun Deborah lo fi fidio lede lati ṣalaye bi iṣẹlẹ naa ṣe waye, ti ọmọ rẹ fi dubulẹ aisan.

Ọmọ ọdun mejila naa to jẹ ọkunrin lo n gba itọju ni ileewosan Lasuth ni ipinlẹ Eko lọwọ lẹyin ti wọn ṣe orisirisi iṣẹ abẹ fun, to si di eyi ti wọn bẹrẹ si ni wa ẹdọfooro rẹ ti awọn oloyinbo n pe ni’’ small intestine’’

Iya rẹ ni ọmọ naa di ero ileewosan lẹyin ti o bẹrẹ sini ya igbẹ ti o si n bi lai dawọ duro.

Lẹyin naa ni iya rẹ gbe lọ fun ayẹwo ni ileewosan, ti wọn si ni o ni aisan iba apọnju, iyẹn typhold amọ ti irora naa ko rọlẹ lẹyin ọjọ marun un.

Lẹyin naa ni iya rẹ tun gbe lọ si ileewosan aladani miran ni agbegbe ileepo Alimosho, ti awọn dokita si ni ẹya ara rẹ, ‘’appendix’’ lo ti bẹ si inu rẹ, ati pe iṣẹ abẹ ni ọna abayọ.

Iya rẹ ni ko tun pẹ si igba naa ni ọmọ naa tun bẹrẹ si ni pariwo inu rirun ni Osu kẹfa, ti wọn si gbe pada lọ si ileewosan ti wọn ti kọkọ se iṣẹ abẹ fun.

Lẹyin naa ni wọn ni awọn ri pe idiwọ wa ni ẹdọfooro rẹ, ti wọn si tun ṣe iṣẹ abẹ fun amọ lẹyin ọjọ meje ni wọn ri pe ọmọ naa ṣi n jẹrora nitori pe nkan si n jade ni inu rẹ.

Iya naa ba ke sita, ti dokita ọhun si ni wọn yoo pe dokita onimọ miran wa lati ileewosan ẹkọni Lasuth, ti wọn si gbe lọ sibẹ.

Ohun ti LASUTH sọ ree

Dokita to ba BBC Pidgin sọrọ ni aisan to n ṣe ọmọ naa ni pe ẹdofooro rẹ ti bẹ, to si n ṣe omi sinu ọmọ naa “intestinal obstruction with perforated viscus”.

Lasiko ti ileewosan Lasuth n ba BBC sọrọ ni wọn ni iṣẹ abẹ ti awọn ṣe fun ọmọ naa ni lati doola ẹmi rẹ.

Wọn awọn ayẹwọ ti wọn se fihan pe inu ọmọ naa n wu pẹlu ohun to dabi ẹni pe kokoro wa nibẹ.

Lẹyin naa ni wọn n bẹrẹ iwosan fun un, amọ wọn ni nigba ti nọọsi n ‘’clean’’ rẹ lo tun dabi ẹni pe o ja si.

Amọ dokita to kọkọ se iṣẹ meji naa ni gbogbo igba ti oun ba n ṣe iṣẹ abẹ fun ọmọ naa ni iya rẹ n wa ninu ibẹ pẹlu ohun.

Amọ o ni nigba ti wọn gbe de Lasuth,wọn ko tete ṣe iṣẹ abẹ fun un ni oju ẹṣẹ, to si di ọjọ keji ki wọn to ṣe fun.

Bakan naa ni wọn fikun un pe iya rẹ ko si nibẹ lasiko iṣẹ abẹ naa.

Iya ọmọ naa wa rọ gomina Sanwo Olu lati dide iranwọ fun oun nitori ọmọ naa wa ninu irora, ti awọn si nilo lati ṣe iṣẹ abẹ lati da ẹdofooro pada sibẹ.

Iya ọmọ naa fikun un pe oke okun ni wọn ti n ṣe iru iṣẹ abẹ naa, to si rọ ijọba lati dide iranwọ si oun.