Àwọn kókó ẹ̀sùn tí El-Rufai fi kan Tinubu, èyí tó mú kó màá sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí lórí ayélujára

Oríṣun àwòrán, Others
Gomina tẹlẹ nipinlẹ Kaduna, Nasir El-Rufai, ti ṣalaye pe, bi oun se fidi janlẹ lasiko ayẹwo fun ipo minisita niwaju ile igbimọ aṣofin, ko sẹyin pe Aarẹ Bola Tinubu ko fẹ oun ninu igbimọ ijọba rẹ.
El-Rufai ni bo tilẹ jẹ pe aarẹ gan an lo fi orukọ oun ransẹ si ile igbimọ aṣofin, to si tun fi ọwọ ara rẹ yọ ọ kuro.
O sọ eyi lasiko to n se ifọrọwerọ pẹlu Arise TV, to jẹ pe igba akọkọ ree ti El-Rufai yoo sọrọ sita lati igba to ti kuro ni ipo gomina ipinlẹ Kaduna.
Lẹyin ti wọn se iburawọle fun Aarẹ Bola Tinubu ni ọdun 2023, o kede eeyan mejidinlaadọta fun ipo minisita, to fi mọ El-Rufai. Ṣugbọn ile igbimọ aṣofin agba wọgile ko buwọlu gomina ana naa ati eeyan meji mii.
Aarẹ ile igbimọ aṣofin, Godswill Akpabio, ṣalaye pe awọn eeyan ti wọn wọgile ni wọn yoo fakalẹ fun iwadii, to si tun rọ wọn pe ki wọn gbe ọrọ naa lọ si ọdọ Aarẹ Tinubu.
Ninu ifọrọwerọ naa, El-Rufai ni oun gbagbọ pe aarẹ gan an ni ko fẹ oun ninu igbimọ ijọba rẹ, to si fi ile igbimọ aṣofin boju.
"Aarẹ ko fẹ mi ninu igbimọ rẹ," El-Rufai sọrọ sita fun igba akọkọ lẹyin ti o kuna lati di minisita.
"Ko ni nkankan se pẹlu ile igbimọ aṣofin ilẹ wa."
El-Rufai ni oun ko ni iṣoro kan kan pẹlu aabo ti wọn ni lati yẹ wo.
"Ki ni wọn n sọ nipa aabo? Mo jẹ gomina ni ọkan ninu awọn ipinlẹ to buru ju. Mo jẹ minisita ni ogun ọdun sẹyin," o fikun pe ko si ohunohun to jade sita nipa aabo ni wọn tẹnumọ ni ile igbimọ aṣofin.
Gomina ana, ẹni to se atilẹyin fun ibo si ipo Aarẹ Tinubu lasiko eto idibo ni ọdun 2023, ṣalaye pe oun sọ fun aarẹ pe oun ko nifẹ si ipo kankan.
Tinubu ki se ọrẹ mi, a ko fi nkankan sun mọ ara wa

Oríṣun àwòrán, El Rufa'i/X
Gomina tẹlẹ nipinlẹ Kaduna tun tẹnubọ ọrọ pe oun ko figba kankan jẹ ọmọ lẹyin Aarẹ Bola Tinubu tabi ki oun jẹ alabase to sunmọ ọ.
O ni lasiko eto idibo abẹle ẹgbẹ oṣelu APC, oun pe fun pe lati guusu orilẹede Naijiria ni ki wọn ti yan oludije ẹgbẹ oṣelu naa , ti oun si ṣetan lati tẹle ẹnikẹni ti wọn ba fa kalẹ.
"Ọrọ nipa eeyan ti a gbe asia APC fun jẹ ohun to kọmilominu.
"Ohun t mo fẹ ko wa si imusẹ ni pe ki eeyan lati ariwa Naijiria jẹ oludije APC .
"Nigba ti a da ẹgbẹ naa silẹ ni ọdun 2013, a pinnu pe lẹyin ọdun mẹjọ Buhari, agbara yoo wa si guusu.
"Tinubu ko fi igba kan ri jẹ ọrẹ mi, a ko sunmọ ara wa rara."
'Mi o le darapọ mọ PDP'
Mi o le darapọ mọ PDP
Nasir El Rufai tun jẹ ko di mimọ pe iroyin ẹlẹjẹ lasan ni iroyin to ni oun gbero lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu PDP lẹyin to se ipade pẹlu awọn eekan ninu ẹgbẹ oṣelu naa nipinlẹ Kaduna.
El Rufai ni otitọ ni pe o ṣeeṣe ki oun fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ ṣugbọn oun ko ni darapọ mọ PDP
"Mo si w ani APC, ma si wa nibẹ titi wọn yoo fi kuna lati se ohun to yẹ ki wọn se."















