Tinubu yóò lulẹ̀ lọ́dún 2027 - àwọn onílù Aregbesola ló fìlù sọ bẹ́ẹ̀

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Awọn onilu fi ilu dara lasiko ti Gomina ipinlẹ Osun tẹlẹri, Ọgbẹni Rauf Aregbesola, gbalejo Igbakeji Aarẹ orilẹede Naijiria tẹlẹri, Atiku Abubakar, nile rẹ niluu Ilesa lọjọ Ẹti ọsẹ to kọja.

Lara nnkan tawọn onilu to wa nibi ipade Atiku ati Aregbesola naa n fi ilu sọ ni pe ''Tinubu yoo lulẹ ninu idibo ọdun 2027.''

Nile Aregbesola ni Atiku ti jẹun aarọ pẹlu gomina ipinlẹ Osun tẹlẹri lọjọ naa pẹlu awọn alẹnulọrọ lagbo oṣelu.

Alhaji Namadi Sambo, toun naa ti figba kan ri jẹ igbakeji aarẹ orilẹede Naijiria lasiko ijọba Goodluck Jonathan naa kọwọọ rin pẹlu Atiku lọ sile Aregbesola.

Aregbesola atawọn alejo rẹ wa lori ijokoo ninu ile igbalejo rẹ nigba tawọn onilu bẹrẹ sii fi ilu sọ pe ''Tinubu maa lulẹ lọdun 2027'' eyi to tumọ si pe Aarẹ Bola Tinubu yoo fidirẹmi ninu ibo aarẹ ọdun 2027.

Atiku tun lo anfaani naa lati lọ sibi iwuye Ọwa Obokun ilẹ Ijesa tuntun, Ọba Clement Adesuyi Haastrup Ajimoko Kẹta, niluu Ilesa lọjọ Ẹti kan naa.

Atiku gan an lo fi fidio bi Aregbesola ṣe ki i kaabọ sile rẹ atawọn abẹnugan lagbo oṣelu sori oju opo X rẹ.

Lara awọn eeyan to ki Atiku kaabọ pẹlu Aregbesola ni adari ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Osun tẹlẹ, Họnọrebu Najeem Salaam ati akọwe ijọba ipinlẹ Osun tẹlẹ, Alhaji Moshood Adeoti.

Awọn oloṣelu mii to wa nibẹ ni Sẹnẹtọ Adelowo Oriolowo to ṣoju ẹkun guusu Osun tẹlẹ nile aṣofin agba l'Abuja, alaga ẹgbẹ oṣelu Aregbesola ti n ko jọ, Alhaji Isaa Adesiji atawọn oloṣelu mii ti wọn ṣiṣẹ pọ pẹlu Aregbe lasiko to jẹ gomina ipinlẹ Osun.