You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kí ló mú koríko hù ní ọ́fíìsì àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ l'Osun?
Pẹlu bi ọfiisi awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ ṣe wa ni titipa lati ọjọ keje, oṣu Keji ọdun yii, koriko ti n digbo sinu awọn ọgba ofiisi naa.
Bi ẹ ko ba gbagbe, idajọ ile-ẹjọ Ko-tẹmi-lọrun to fi ikalẹ si ilu Akure, nipinlẹ Ondo, lo fa titipa naa.
Ṣugbọn iroyin sọ pe owo oṣu awọn osisẹ ijọba ibilẹ ati awọn alaga ti ko ni anfaani lati wọ ofiisi naa ko duro lati igba naa.
BBC Yoruba kan si ẹgbẹ oselu APC lati mọ bo se n lọ labala ọdọ wọn.
Jamiu Olawumi, ọkan gboogi ninu ẹgbẹ oselu APC Osun, ṣalaye pe ijọba Gomina Ademola Adeleke n tan ara wọn jẹ ni.
O ni ile ẹjọ Ko-tẹmi-lọrun ti da awọn Alaga ati Kansilọ pada si ofiisi lati ọjọ kẹwaa, osu Keji ọdun yii.
Olawumi ni awọn ko mọ ọna ti Gomina Adeleke n gba sanwo osisẹ ati awọn Alaga ijọba Ibilẹ to bura wọle fun.
O ni gbogbo owo awọn Alaga ijọba Ibilẹ wa ni banki apapọ ti ko si si ẹnikẹni to gba a.
O fi kun un pe awọn Alaga ati Kansilọ ti ile ẹjọ Ko-tẹmi-lọrun da pada ni wọn n lọ si ọfiisi wọn.
Wọn yoo si bẹrẹ si i gba owo oṣu ka too ri ọjọ diẹ, nitori banki apapọ ti beere awọn ẹri kan lọwọ wọn ti wọn si yege.
Olawumi lo ṣalaye bẹẹ.
Àlàyé ìjọba ìpínlẹ̀ Osun
Komiṣanna eto Iroyin nipinlẹ Ọsun, Kolapo Alimi, ṣalaye pe awọn ẹgbẹ oselu APC lo n da omi alaafia ìjọba ibilẹ Osun ru.
O ni eyi ri bẹẹ latari bi wọn ko se ni òye ohun ti ile ẹjọ Ko-tẹmi-lọrun sọ lọjọ kẹwaa, osu Keji ọdun yii.
Alimi fi kun ọrọ rẹ pe, ohun ti awọn ẹgbẹ oselu APC ko fẹ ṣe ni wọn pada ṣe latari bi wọn ṣe tun gba ile ẹjọ lọ lori ọrọ naa.
O ni loootọ ni ijọba Gomina Ademola Adeleke n sanwo awọn osisẹ ijọba ibilẹ, ṣugbọn ọna ti awọn n gba sanwo naa ko kan ẹnikẹni rara.
Kọmiṣanna eto iroyin Osun naa sọ pe aala ni yoo fi oko ọlẹ han laipẹ yii.