Wike fọnmú, ó pe Seyi Makinde ní Ọ̀dàlẹ̀ àti Agbẹ̀yìnbẹbọjẹ́, pé ó wá lára àwọn tí kò jẹ́ kí omi àlàáfíà ẹgbẹ́ PDP tòrò

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Rogbodiayan to n lọ ninu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party PDP tun gba ọna miiran yọ nigba ti Nyesom Wike, tii se minisita fun olu ilu ilẹ wa, Abuja, ni oun ti yọwọ kuro ninu adehun wiwa ojutu si iṣoro ẹgbẹ naa.

Bakan naa ni Wike tun fẹsun kan Gomina Seyi Makinde ti ipinlẹ Oyo pe oun lo n fa ọpọ wahala to n ja ẹgbẹ oṣelu PDP nitori bo ṣe kuna lati ko ipa tirẹ lori adehun ti wọn jọ fẹnuko le lori.

Wike wa ṣapejuwe Makinde, Mba ati awọn mii ninu ẹgbẹ oṣelu PDP gẹgẹ bii ọdalẹ.

Ninu atẹjade kan ti Wike gbe soju opo ayelujara X ni gomina ipinlẹ Rivers tẹlẹ naa ti fẹsun kan awọn agbagba ẹgbẹ oṣelu PDP bi Gomina ipinlẹ Enugu, Peter Mbah, to ṣapejuwe wọn gẹgẹ bii ọdalẹ, alailootọ ati awọn ẹsun mii to ni ṣe pẹlu yiyẹ adehun.

Orisun rogbodiyan to n lọ ninu ẹgbẹ oṣelu lo bẹrẹ lẹyin eto idibo ọdun 2023, ti minister ọhun si ṣe ileri pe oun ko ni jawọ ninu ija titi oun yoo fi ri idajọ ododo gba.

Wike, ẹni to fi igba kan jẹ Gomina ipinlẹ Rivers labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP jẹ ọkan gboogi ninu ẹgbẹ awọn Gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP ni gbogbo igbiyanju lati w ani ojutu si iṣoro PDP ni Makinde n daru.

"Mo sọ fun Gomina ipinlẹ O yo, Seyi Makinde pe oun oludasilẹ iṣoro wa, ti mo si ṣalaye fun pe ai mojuto adehun to wa lati ọwọ rẹ lo fa rogbodiyan yii, to si jẹ pe oun ni olori mọdaru," Wike ṣalaye.

"Lẹyin ipade yii, a ṣe ipade miiran niluu Abuja, nibẹ ni emi, Gomina Seyi Makinde, Umaru Fintri, Bala Mohammed, ati Bukola Saraki, ni ile itura Saraki.

Ninu ipade naa, mo jẹ ko di mimọ pe n ko ni iṣoro kankan pẹlu gomina Bala Muhammed yatọ si pe o ṣa pamọ si abẹ orule pe o jẹ alaga awọn gomina PDP to tọwọ adehun.

"Ipade yii ni o kun fun ọpọ ariwo, ti a si se gbogbo ohun to yẹ lati jẹ ki alaafia jọba.

Ni ipari ipade naa, a fẹnuko lori awọn wọn yii;

  • Pe ki Sẹnetọ Samuel Anyanwu tun bọ wa ni ipo akọwe ẹgbẹ PDP titi idajọ ile ẹjọ.
  • Pe ki agbẹjọro yọdile gbogbo ẹsun ti wọn fi kan ipinlẹ Rivers
  • Pe ki wọn wọgile ẹjọ ti wọn pe tako ikede ilu o fararọ ni Rivers
  • Pe ẹnikẹni ko gbọdọ yabara kuro ni adehun

Lẹyin gbogbo eyi, Wike ni wọn bẹ oun pe ki oun lọ fun ipade ni ile ijọba nipinlẹ Bauchi, ti a si yan igbimọ ti HE, Bukola Saraki jẹ olori fun lati yanju awọ ẹgbẹ oṣelu PDP.

Wike oun to ju oun pupọ ni pe saaju ki igbimọ Gomina Bukola Saraki to waye ni awọn adehun ti wọn fẹnuko le lori ni ile Itura Saraki ti ni ọwọ ninu.

Ki ni Gomina Seyi Makinde sọ nipa ọrọ yii?

Lẹyin ti Minisita fun olu ilu Abuja, Nyesom Wike, sọ oko ọrọ sita, nibi to ti fẹsun kan Seyi Makinde pe o jẹ ọdalẹ, to si tun jẹ ọkan gboogi ninu awn eeyan to n da wahala silẹ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP.

BBC Yoruba kan si igun Seyi Makinde, Gomina Ipinlẹ Oyo, lati mọ esi to fẹ fọ sawọn ẹsun ti Wike fi kan an ati orukọ buruku to sọ.

Amọ ikọ iroyin MAkinde sọ fun BBC Yoruba pe oun ko ni nkankan lati sọ nipa awọn ẹsun ti Wike gbe sori ayelujara.

Agbẹnusọ Makinde to ba wa sọrọ ni Makinde ko ni ohunkohun lati sọ sita lori ọrọ Wike.